< Luke 20 >

1 Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìyìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i.
It happened on one of those days, as he was teaching the people in the temple and preaching the gospel, that the chief priests and scribes came to him with the elders.
2 Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”
They asked him, "Tell us: by what authority do you do these things? Or who is giving you this authority?"
3 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi.
He answered them, "I also will ask you one question. Tell me:
4 Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”
the baptism of John, was it from heaven, or from man?"
5 Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun yóò wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’
They reasoned with themselves, saying, "If we say, 'From heaven,' he will say, 'Why did you not believe him?'
6 Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.”
But if we say, 'From man,' all the people will stone us, for they are persuaded that John was a prophet."
7 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”
They answered that they did not know where it was from.
8 Jesu sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”
Jesus said to them, "Neither will I tell you by what authority I do these things."
9 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.
He began to tell the people this parable. "A man planted a vineyard, and rented it out to some farmers, and went on a journey for a long time.
10 Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà, ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
At the proper season, he sent a servant to the farmers to collect his share of the fruit of the vineyard. But the farmers beat him, and sent him away empty.
11 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn, wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
He sent yet another servant, and they also beat him, and treated him shamefully, and sent him away empty.
12 Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.
He sent yet a third, and they also wounded him, and threw him out.
13 “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’
The lord of the vineyard said, 'What am I to do? I will send my beloved son. It may be that they will respect him.'
14 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’
"But when the farmers saw him, they reasoned among themselves, saying, 'This is the heir. Let us kill him, that the inheritance may be ours.'
15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á. “Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?
They threw him out of the vineyard, and killed him. What therefore will the lord of the vineyard do to them?
16 Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!”
He will come and destroy these farmers, and will give the vineyard to others." When they heard it, they said, "May it never be."
17 Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?
But he looked at them, and said, "Then what is this that is written, 'The stone which the builders rejected, the same was made the chief cornerstone?'
18 Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”
Everyone who falls on that stone will be broken to pieces; but on whomever it falls, it will crush him."
19 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.
The chief priests and the scribes sought to lay hands on him that very hour, but they feared the people—for they knew he had spoken this parable against them.
20 Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.
They watched him, and sent out spies, who pretended to be righteous, that they might trap him in something he said, so as to deliver him up to the power and authority of the governor.
21 Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́.
They asked him, "Teacher, we know that you say and teach what is right, and are not partial to anyone, but truly teach the way of God.
22 Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”
Is it lawful for us to pay taxes to Caesar, or not?"
23 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,
But he perceived their craftiness, and said to them,
24 “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”
"Show me a denarius. Whose image and inscription are on it?" They answered, "Caesar's."
25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
He said to them, "Then give to Caesar the things that are Caesar's, and to God the things that are God's."
26 Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.
They weren't able to trap him in his words before the people. And amazed at his answer, they fell silent.
27 Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí wọ́n sì bi í,
Some of the Sadducees came to him, those who deny that there is a resurrection.
28 wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé, Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.
They asked him, "Teacher, Moses wrote to us that if a man's brother dies having a wife, and he is childless, his brother should take the wife, and raise up children for his brother.
29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.
There were therefore seven brothers. The first took a wife, and died childless.
30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.
The second and
31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú.
the third took her, and likewise the seven all left no children, and died.
32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú.
Afterward the woman also died.
33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”
Therefore in the resurrection whose wife of them will she be? For the seven had her as a wife."
34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. (aiōn g165)
Jesus said to them, "The people of this age marry and are given to someone to marry. (aiōn g165)
35 Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. (aiōn g165)
But those who are regarded as worthy of a place in that age and the resurrection from the dead neither marry nor are given to someone to marry. (aiōn g165)
36 Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.
For they cannot die any more, for they are like the angels, and are children of God, being children of the resurrection.
37 Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’
But that the dead are raised, even Moses showed at the bush, when he called the Lord 'The God of Abraham, and the God of Isaac, and the God of Jacob.'
38 Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.”
Now he is not the God of the dead, but of the living, for all are alive to him."
39 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!”
Some of the scribes answered, "Teacher, you speak well."
40 Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.
They did not dare to ask him any more questions.
41 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, ọmọ Dafidi ni Kristi?
He said to them, "Why do they say that the Messiah is David's son?
42 Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé: “‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
David himself says in the scroll of Psalms, 'The Lord said to my Lord, "Sit at my right hand,
43 títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”’
until I make your enemies the footstool of your feet."'
44 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
"David therefore calls him Lord, so how is he his son?"
45 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé,
In the hearing of all the people, he said to his disciples,
46 “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè;
"Beware of the scribes, who like to walk in long robes, and love greetings in the marketplaces, the best seats in the synagogues, and the best places at feasts;
47 Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”
who devour widows' houses, and for a pretense make long prayers: these will receive greater condemnation."

< Luke 20 >