< Luke 2 >
1 Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé.
E aconteceu naqueles dias que saiu um decreto da parte de Cesar Augusto, para que todo o mundo se alistasse
2 (Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí Kirene fi jẹ baálẹ̀ Siria.)
(Este primeiro alistamento foi feito sendo Cyrenio presidente da Syria),
3 Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.
E todos iam alistar-se, cada um à sua própria cidade.
4 Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe,
E subiu também José da Galiléia, da cidade de Nazareth, à Judeia, à cidade de David, chamada Belém (porque era da casa e família de David),
5 láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí.
Para alistar-se com Maria, sua mulher, que estava grávida.
6 Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí.
E aconteceu que, estando eles ali se cumpriram os dias em que havia de dar à luz.
7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.
E deu à luz a seu filho primogênito, e envolveu-o em panos, e deitou-o numa mangedoura, porque não havia lugar para eles na estalagem.
8 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.
Ora havia naquela mesma comarca pastores que estavam no campo, e guardavam durante as vigílias da noite o seu rebanho.
9 Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
E eis que o anjo do Senhor veio sobre eles, e a glória do Senhor os cercou de resplendor, e tiveram grande temor.
10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, “Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.
E o anjo lhes disse: Não temais, porque eis aqui vos dou novas de grande alegria, que será para todo o povo:
11 Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa.
Que hoje, na cidade de David, vos nasceu o Salvador, que é Cristo, o Senhor.
12 Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.”
E isto vos será por sinal: Achareis o menino envolto em panos, e deitado numa mangedoura.
13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,
E, no mesmo instante, apareceu com o anjo uma multidão dos exércitos celestiais, louvando a Deus, e dizendo:
14 “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, àti ní ayé àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”
Glória a Deus nas alturas, paz na terra, boa vontade para os homens.
15 Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.”
E aconteceu que, ausentando-se deles os anjos para o céu, disseram os pastores uns aos outros: Vamos pois até Belém, e vejamos isso que aconteceu, e que o Senhor nos notificou.
16 Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.
E foram apressadamente, e acharam Maria, e José, e o menino deitado na mangedoura.
17 Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí.
E, vendo-o, divulgaram a palavra que acerca do menino lhes fôra dita;
18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá.
E todos os que os ouviram se maravilharam do que os pastores lhes diziam.
19 Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.
Mas Maria guardava todas estas coisas, conferindo-as em seu coração.
20 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.
E voltaram os pastores, glorificando e louvando a Deus por tudo o que tinham ouvido e visto, como lhes havia sido dito.
21 Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀.
E, quando os oito dias foram cumpridos, para circuncidar o menino, foi-lhe dado o nome de Jesus, que pelo anjo lhe fôra posto antes de ser concebido.
22 Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa
E, cumprindo-se os dias da purificação, segundo a lei de Moisés, o levaram a Jerusalém, para o apresentarem ao Senhor,
23 (bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”),
Segundo o que está escrito na lei do Senhor: Todo o macho primogênito será consagrado ao Senhor;
24 àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”
E para darem a oferta segundo o disposto na lei do Senhor: um par de rolas ou dois pombinhos.
25 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli, Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.
E eis que havia em Jerusalém um homem cujo nome era Simeão; e este homem era justo e temente a Deus, e esperava a consolação de Israel; e o Espírito Santo estava sobre ele.
26 A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa.
E fôra-lhe divinamente revelado pelo Espírito Santo que ele não morreria antes de ter visto o Cristo do Senhor.
27 Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin.
E pelo espírito foi ao templo, e, quando os pais introduziram o menino Jesus, para com ele procederem segundo o uso da lei,
28 Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:
Ele então o tomou em seus braços, e louvou a Deus, e disse:
29 “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ, ní àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Agora, Senhor, despedes em paz o teu servo, segundo a tua palavra.
30 Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,
Pois já os meus olhos viram a tua salvação,
31 tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;
A qual tu preparaste perante a face de todos os povos;
32 ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà, àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”
Luz para alumiar as nações, e para glória de teu povo Israel.
33 Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.
E José, e sua mãe, se maravilharam das coisas que dele se diziam.
34 Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé, “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí;
E Simeão os abençoou, e disse a Maria, sua mãe: Eis que este é posto para queda e elevação de muitos em Israel, e para sinal que será contradito;
35 (idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
E uma espada traspassará também a tua própria alma; para que se manifestem os pensamentos de muitos corações.
36 Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá;
E estava ali a profetiza Ana, filha de Fanuel, da tribo de Aser. Esta era já avançada em idade, e tinha vivido com o marido sete anos, desde a sua virgindade,
37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru.
E era viúva, de quase oitenta e quatro anos, e não se afastava do templo, servindo a Deus em jejuns e orações, de noite e de dia.
38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.
E esta, sobrevindo na mesma hora, dava graças a Deus, e falava dele a todos os que esperavam a redenção em Jerusalém.
39 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn.
E, quando acabaram de cumprir tudo segundo a lei do Senhor, voltaram à Galiléia, para a sua cidade de Nazareth.
40 Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.
E o menino crescia, e se fortalecia em espírito, cheio de sabedoria; e a graça de Deus estava sobre ele.
41 Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá.
Ora, todos os anos iam seus pais a Jerusalém, à festa da pascoa;
42 Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà.
E, tendo ele já doze anos, subiram a Jerusalém, segundo o costume do dia da festa.
43 Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀.
E, regressando eles, terminados aqueles dias, ficou o menino Jesus em Jerusalém, e não o souberam seus pais.
44 Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn.
Pensando, porém, eles que viria de companhia pelo caminho, andaram caminho de um dia, e buscavam-no entre os parentes e conhecidos;
45 Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri.
E, como o não encontrassem, voltaram a Jerusalém em busca dele.
46 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè.
E aconteceu que, passados três dias, o acharam no templo, assentado no meio dos doutores, ouvindo-os, e interrogando-os.
47 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀.
E todos os que o ouviam admiravam a sua inteligência e respostas.
48 Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”
E eles, vendo-o, maravilharam-se, e disse-lhe sua mãe: Filho, porque fizeste assim para conosco? Eis que teu pai e eu anciosos te buscávamos.
49 Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”
E ele lhes disse: Porque é que me buscaveis? Não sabeis que me convém tratar dos negócios de meu pai?
50 Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.
E eles não compreenderam as palavras que lhes dizia.
51 Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.
E desceu com eles, e foi para Nazareth, e era-lhes sujeito. E sua mãe guardava no seu coração todas estas coisas.
52 Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.
E crescia Jesus em sabedoria, e em estatura, e em graça para com Deus e os homens.