< Luke 18 >
1 Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀.
Then Jesus told them a parable about their need to pray at all times and not lose heart:
2 Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn.
“In a certain town there was a judge who neither feared God nor respected men.
3 Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi!’
And there was a widow in that town who kept appealing to him, ‘Give me justice against my adversary.’
4 “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn, ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn,
For a while he refused, but later he said to himself, ‘Though I neither fear God nor respect men,
5 Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má ba à fi wíwá rẹ̀ nígbàkígbà dá mi lágara.’”
yet because this widow keeps pestering me, I will give her justice. Then she will stop wearing me out with her perpetual requests.’”
6 Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí!
And the Lord said, “Listen to the words of the unjust judge.
7 Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn?
Will not God bring about justice for His elect who cry out to Him day and night? Will He continue to defer their help?
8 Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”
I tell you, He will promptly carry out justice on their behalf. Nevertheless, when the Son of Man comes, will He find faith on earth?”
9 Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn,
To some who trusted in their own righteousness and viewed others with contempt, He also told this parable:
10 pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde.
“Two men went up to the temple to pray. One was a Pharisee and the other a tax collector.
11 Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.
The Pharisee stood by himself and prayed, ‘God, I thank You that I am not like the other men—swindlers, evildoers, adulterers—or even like this tax collector.
12 Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’
I fast twice a week and pay tithes of all that I acquire.’
13 “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’
But the tax collector stood at a distance, unwilling even to lift up his eyes to heaven. Instead, he beat his breast and said, ‘God, have mercy on me, a sinner!’
14 “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”
I tell you, this man, rather than the Pharisee, went home justified. For everyone who exalts himself will be humbled, but the one who humbles himself will be exalted.”
15 Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí.
Now people were even bringing their babies to Jesus for Him to place His hands on them. And when the disciples saw this, they rebuked those who brought them.
16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.
But Jesus called the children to Him and said, “Let the little children come to Me, and do not hinder them! For the kingdom of God belongs to such as these.
17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
Truly I tell you, anyone who does not receive the kingdom of God like a little child will never enter it.”
18 Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” (aiōnios )
Then a certain ruler asked Him, “Good Teacher, what must I do to inherit eternal life?” (aiōnios )
19 Jesu wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run.
“Why do you call Me good?” Jesus replied. “No one is good except God alone.
20 Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’”
You know the commandments: ‘Do not commit adultery, do not murder, do not steal, do not bear false witness, honor your father and mother.’”
21 Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”
“All these I have kept from my youth,” he said.
22 Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
On hearing this, Jesus told him, “You still lack one thing: Sell everything you own and give to the poor, and you will have treasure in heaven. Then come, follow Me.”
23 Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
But when the ruler heard this, he became very sad, because he was extremely wealthy.
24 Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!
Seeing the man’s sadness, Jesus said, “How hard it is for the rich to enter the kingdom of God!
25 Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”
Indeed, it is easier for a camel to pass through the eye of a needle than for a rich man to enter the kingdom of God.”
26 Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?”
Those who heard this asked, “Who then can be saved?”
27 Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
But Jesus said, “What is impossible with man is possible with God.”
28 Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”
“Look,” said Peter, “we have left all we had to follow You.”
29 Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run,
“Truly I tell you,” Jesus replied, “no one who has left home or wife or brothers or parents or children for the sake of the kingdom of God
30 tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (aiōn , aiōnios )
will fail to receive many times more in this age—and in the age to come, eternal life.” (aiōn , aiōnios )
31 Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn.
Then Jesus took the Twelve aside and said to them, “Look, we are going up to Jerusalem, and everything the prophets have written about the Son of Man will be fulfilled.
32 Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára.
He will be delivered over to the Gentiles and will be mocked and insulted and spit upon.
33 Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”
They will flog Him and kill Him, and on the third day He will rise again.”
34 Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn, ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.
But the disciples did not understand any of these things. The meaning was hidden from them, and they did not comprehend what He was saying.
35 Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe.
As Jesus drew near to Jericho, a blind man was sitting beside the road, begging.
36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí.
When he heard the crowd going by, he asked what was happening.
37 Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”
“Jesus of Nazareth is passing by,” they told him.
38 Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
So he called out, “Jesus, Son of David, have mercy on me!”
39 Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
Those who led the way admonished him to be silent, but he cried out all the louder, “Son of David, have mercy on me!”
40 Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í
Jesus stopped and directed that the man be brought to Him. When he had been brought near, Jesus asked him,
41 wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?” Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”
“What do you want Me to do for you?” “Lord,” he said, “let me see again.”
42 Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”
“Receive your sight!” Jesus replied. “Your faith has healed you.”
43 Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.
Immediately he received his sight and followed Jesus, glorifying God. And all the people who saw this gave praise to God.