< Luke 14 >
1 Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ.
One Sabbath, Jesus went to eat in the home of a leading Pharisee, and those in attendance were watching Him closely.
2 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀.
Right there before Him was a man with dropsy.
3 Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?”
So Jesus asked the experts in the law and the Pharisees, “Is it lawful to heal on the Sabbath or not?”
4 Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
But they remained silent. Then Jesus took hold of the man, healed him, and sent him on his way.
5 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?”
And He asked them, “Which of you whose son or ox falls into a pit on the Sabbath day will not immediately pull him out?”
6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí.
And they were unable to answer these questions.
7 Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé,
When Jesus noticed how the guests chose the places of honor, He told them a parable:
8 “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.
“When you are invited to a wedding banquet, do not sit in the place of honor, in case someone more distinguished than you has been invited.
9 Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní ààyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn.
Then the host who invited both of you will come and tell you, ‘Give this man your seat.’ And in humiliation, you will have to take the last place.
10 Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ.
But when you are invited, go and sit in the last place, so that your host will come and tell you, ‘Friend, move up to a better place.’ Then you will be honored in front of everyone at the table with you.
11 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.”
For everyone who exalts himself will be humbled, and the one who humbles himself will be exalted.”
12 Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà.
Then Jesus said to the man who had invited Him, “When you host a dinner or a banquet, do not invite your friends or brothers or relatives or rich neighbors. Otherwise, they may invite you in return, and you will be repaid.
13 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú:
But when you host a banquet, invite the poor, the crippled, the lame, and the blind,
14 Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ, ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”
and you will be blessed. Since they cannot repay you, you will be repaid at the resurrection of the righteous.”
15 Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”
When one of those reclining with Him heard this, he said to Jesus, “Blessed is everyone who will eat at the feast in the kingdom of God.”
16 Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀.
But Jesus replied, “A certain man prepared a great banquet and invited many guests.
17 Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’
When it was time for the banquet, he sent his servant to tell those who had been invited, ‘Come, for everything is now ready.’
18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
But one after another they all began to make excuses. The first one said, ‘I have bought a field, and I need to go see it. Please excuse me.’
19 “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
Another said, ‘I have bought five yoke of oxen, and I am going to try them out. Please excuse me.’
20 “Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’
Still another said, ‘I have married a wife, so I cannot come.’
21 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’
The servant returned and reported all this to his master. Then the owner of the house became angry and said to his servant, ‘Go out quickly into the streets and alleys of the city, and bring in the poor, the crippled, the blind, and the lame.’
22 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’
‘Sir,’ the servant replied, ‘what you ordered has been done, and there is still room.’
23 “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún.
So the master told his servant, ‘Go out to the highways and hedges and compel them to come in, so that my house will be full.
24 Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’”
For I tell you, not one of those men who were invited will taste my banquet.’”
25 Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé,
Large crowds were now traveling with Jesus, and He turned and said to them,
26 “Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
“If anyone comes to Me and does not hate his father and mother and wife and children and brothers and sisters—yes, even his own life—he cannot be My disciple.
27 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
And whoever does not carry his cross and follow Me cannot be My disciple.
28 “Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀.
Which of you, wishing to build a tower, does not first sit down and count the cost to see if he has the resources to complete it?
29 Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà.
Otherwise, if he lays the foundation and is unable to finish the work, everyone who sees it will ridicule him,
30 Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’
saying, ‘This man could not finish what he started to build.’
31 “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá pàdé ẹni tí ń mú ogún ẹgbẹ̀rún bọ̀ wá ko òun lójú?
Or what king on his way to war with another king will not first sit down and consider whether he can engage with ten thousand men the one coming against him with twenty thousand?
32 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà.
And if he is unable, he will send a delegation while the other king is still far off, to ask for terms of peace.
33 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
In the same way, any one of you who does not give up everything he has cannot be My disciple.
34 “Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn?
Salt is good, but if the salt loses its savor, with what will it be seasoned?
35 Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù. “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”
It is fit neither for the soil nor for the manure pile, and it is thrown out. He who has ears to hear, let him hear.”