< Leviticus 7 >

1 “‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún rírú ẹbọ ẹ̀bi, tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
וְזֹ֥את תּוֹרַ֖ת הָאָשָׁ֑ם קֹ֥דֶשׁ קָֽדָשִׁ֖ים הֽוּא׃
2 Níbi tí wọn ti ń pa ẹran ẹbọ sísun ni kí ẹ ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀bi, kí ẹ sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.
בִּמְק֗וֹם אֲשֶׁ֤ר יִשְׁחֲטוּ֙ אֶת־הָ֣עֹלָ֔ה יִשְׁחֲט֖וּ אֶת־הָאָשָׁ֑ם וְאֶת־דָּמ֛וֹ יִזְרֹ֥ק עַל־הַמִּזְבֵּ֖חַ סָבִֽיב׃
3 Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ ni kí ẹ sun, ọ̀rá ìrù rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀.
וְאֵ֥ת כָּל־חֶלְבּ֖וֹ יַקְרִ֣יב מִמֶּ֑נּוּ אֵ֚ת הָֽאַלְיָ֔ה וְאֶת־הַחֵ֖לֶב הַֽמְכַסֶּ֥ה אֶת־הַקֶּֽרֶב׃
4 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín.
וְאֵת֙ שְׁתֵּ֣י הַכְּלָיֹ֔ת וְאֶת־הַחֵ֙לֶב֙ אֲשֶׁ֣ר עֲלֵיהֶ֔ן אֲשֶׁ֖ר עַל־הַכְּסָלִ֑ים וְאֶת־הַיֹּתֶ֙רֶת֙ עַל־הַכָּבֵ֔ד עַל־הַכְּלָיֹ֖ת יְסִירֶֽנָּה׃
5 Àlùfáà yóò sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀bi ni.
וְהִקְטִ֨יר אֹתָ֤ם הַכֹּהֵן֙ הַמִּזְבֵּ֔חָה אִשֶּׁ֖ה לַיהוָ֑ה אָשָׁ֖ם הֽוּא׃
6 Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
כָּל־זָכָ֥ר בַּכֹּהֲנִ֖ים יֹאכְלֶ֑נּוּ בְּמָק֤וֹם קָדוֹשׁ֙ יֵאָכֵ֔ל קֹ֥דֶשׁ קָֽדָשִׁ֖ים הֽוּא׃
7 “‘Òfin yìí kan náà ló wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi: méjèèjì jẹ́ tí àlùfáà, tó fi wọ́n ṣe ètùtù.
כַּֽחַטָּאת֙ כָּֽאָשָׁ֔ם תּוֹרָ֥ה אַחַ֖ת לָהֶ֑ם הַכֹּהֵ֛ן אֲשֶׁ֥ר יְכַפֶּר־בּ֖וֹ ל֥וֹ יִהְיֶֽה׃
8 Àlùfáà tó rú ẹbọ sísun fún ẹnikẹ́ni le è mú awọ ẹran ìrúbọ náà.
וְהַ֨כֹּהֵ֔ן הַמַּקְרִ֖יב אֶת־עֹ֣לַת אִ֑ישׁ ע֤וֹר הָֽעֹלָה֙ אֲשֶׁ֣ר הִקְרִ֔יב לַכֹּהֵ֖ן ל֥וֹ יִהְיֶֽה׃
9 Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a bá yan lórí ààrò, àti gbogbo èyí tí a yan nínú apẹ, àti nínú àwopẹ̀tẹ́, ni kí ó jẹ́ ti àlùfáà tí ó rú ẹbọ náà.
וְכָל־מִנְחָ֗ה אֲשֶׁ֤ר תֵּֽאָפֶה֙ בַּתַּנּ֔וּר וְכָל־נַעֲשָׂ֥ה בַמַּרְחֶ֖שֶׁת וְעַֽל־מַחֲבַ֑ת לַכֹּהֵ֛ן הַמַּקְרִ֥יב אֹתָ֖הּ ל֥וֹ תִֽהְיֶֽה׃
10 Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹbọ ohun jíjẹ yálà a fi òróró pò ó tàbí èyí tó jẹ́ gbígbẹ, wọ́n jẹ́ ti gbogbo ọmọ Aaroni.
וְכָל־מִנְחָ֥ה בְלוּלָֽה־בַשֶּׁ֖מֶן וַחֲרֵבָ֑ה לְכָל־בְּנֵ֧י אַהֲרֹ֛ן תִּהְיֶ֖ה אִ֥ישׁ כְּאָחִֽיו׃ פ
11 “‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún ọrẹ àlàáfíà tí ẹnikẹ́ni bá gbé wá síwájú Olúwa.
וְזֹ֥את תּוֹרַ֖ת זֶ֣בַח הַשְּׁלָמִ֑ים אֲשֶׁ֥ר יַקְרִ֖יב לַיהוָֽה׃
12 “‘Bí ẹni náà bá gbé e wá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ọkàn ọpẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọpẹ́ yìí, ó gbọdọ̀ mú àkàrà aláìwú tí a fi òróró pò wá àti àkàrà aláìwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a dà òróró sí àti àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò ṣe.
אִ֣ם עַל־תּוֹדָה֮ יַקְרִיבֶנּוּ֒ וְהִקְרִ֣יב ׀ עַל־זֶ֣בַח הַתּוֹדָ֗ה חַלּ֤וֹת מַצּוֹת֙ בְּלוּלֹ֣ת בַּשֶּׁ֔מֶן וּרְקִיקֵ֥י מַצּ֖וֹת מְשֻׁחִ֣ים בַּשָּׁ֑מֶן וְסֹ֣לֶת מֻרְבֶּ֔כֶת חַלֹּ֖ת בְּלוּלֹ֥ת בַּשָּֽׁמֶן׃
13 Pẹ̀lú ọrẹ àlàáfíà rẹ̀, kí ó tún mú àkàrà wíwú wá fún ọpẹ́,
עַל־חַלֹּת֙ לֶ֣חֶם חָמֵ֔ץ יַקְרִ֖יב קָרְבָּנ֑וֹ עַל־זֶ֖בַח תּוֹדַ֥ת שְׁלָמָֽיו׃
14 kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú oríṣìíríṣìí ọrẹ àlàáfíà rẹ wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Olúwa, ó jẹ́ tí àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà.
וְהִקְרִ֨יב מִמֶּ֤נּוּ אֶחָד֙ מִכָּל־קָרְבָּ֔ן תְּרוּמָ֖ה לַיהוָ֑ה לַכֹּהֵ֗ן הַזֹּרֵ֛ק אֶת־דַּ֥ם הַשְּׁלָמִ֖ים ל֥וֹ יִהְיֶֽה׃
15 Ẹran ọrẹ àlàáfíà ti ọpẹ́ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ ní ọjọ́ gan an tí wọ́n rú ẹbọ, kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ẹran kankan kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.
וּבְשַׂ֗ר זֶ֚בַח תּוֹדַ֣ת שְׁלָמָ֔יו בְּי֥וֹם קָרְבָּנ֖וֹ יֵאָכֵ֑ל לֹֽא־יַנִּ֥יחַ מִמֶּ֖נּוּ עַד־בֹּֽקֶר׃
16 “‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ó mú ọrẹ wá, nítorí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ tàbí kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, wọn yóò jẹ ẹbọ náà ní ọjọ́ tí wọ́n rú ẹbọ yìí, ṣùgbọ́n wọ́n lè jẹ èyí tó ṣẹ́kù ní ọjọ́ kejì.
וְאִם־נֶ֣דֶר ׀ א֣וֹ נְדָבָ֗ה זֶ֚בַח קָרְבָּנ֔וֹ בְּי֛וֹם הַקְרִיב֥וֹ אֶת־זִבְח֖וֹ יֵאָכֵ֑ל וּמִֽמָּחֳרָ֔ת וְהַנּוֹתָ֥ר מִמֶּ֖נּוּ יֵאָכֵֽל׃
17 Gbogbo ẹran tó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ní ẹ gbọdọ̀ sun.
וְהַנּוֹתָ֖ר מִבְּשַׂ֣ר הַזָּ֑בַח בַּיּוֹם֙ הַשְּׁלִישִׁ֔י בָּאֵ֖שׁ יִשָּׂרֵֽף׃
18 Bí ẹ bá jẹ ọ̀kankan nínú ẹran ọrẹ àlàáfíà ní ọjọ́ kẹta, kò ni jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. A kò ní í kà á sí fún ẹni tó rú ẹbọ náà, nítorí pé ó jẹ́ àìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹ ẹ́, ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù.
וְאִ֣ם הֵאָכֹ֣ל יֵ֠אָכֵל מִבְּשַׂר־זֶ֨בַח שְׁלָמָ֜יו בַּיּ֣וֹם הַשְּׁלִישִׁי֮ לֹ֣א יֵרָצֶה֒ הַמַּקְרִ֣יב אֹת֗וֹ לֹ֧א יֵחָשֵׁ֛ב ל֖וֹ פִּגּ֣וּל יִהְיֶ֑ה וְהַנֶּ֛פֶשׁ הָאֹכֶ֥לֶת מִמֶּ֖נּוּ עֲוֺנָ֥הּ תִּשָּֽׂא׃
19 “‘Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá ti kan ohun tí a kà sí àìmọ́, sísun ni kí ẹ sun ún. Ẹnikẹ́ni tí a ti kà sí mímọ́ le è jẹ nínú ẹran tí ó kù.
וְהַבָּשָׂ֞ר אֲשֶׁר־יִגַּ֤ע בְּכָל־טָמֵא֙ לֹ֣א יֵֽאָכֵ֔ל בָּאֵ֖שׁ יִשָּׂרֵ֑ף וְהַ֨בָּשָׂ֔ר כָּל־טָה֖וֹר יֹאכַ֥ל בָּשָֽׂר׃
20 Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò mọ́ bá jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tí ó jẹ́ tí Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.
וְהַנֶּ֜פֶשׁ אֲשֶׁר־תֹּאכַ֣ל בָּשָׂ֗ר מִזֶּ֤בַח הַשְּׁלָמִים֙ אֲשֶׁ֣ר לַיהוָ֔ה וְטֻמְאָת֖וֹ עָלָ֑יו וְנִכְרְתָ֛ה הַנֶּ֥פֶשׁ הַהִ֖וא מֵעַמֶּֽיהָ׃
21 Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ.’”
וְנֶ֜פֶשׁ כִּֽי־תִגַּ֣ע בְּכָל־טָמֵ֗א בְּטֻמְאַ֤ת אָדָם֙ א֣וֹ ׀ בִּבְהֵמָ֣ה טְמֵאָ֗ה א֚וֹ בְּכָל־שֶׁ֣קֶץ טָמֵ֔א וְאָכַ֛ל מִבְּשַׂר־זֶ֥בַח הַשְּׁלָמִ֖ים אֲשֶׁ֣ר לַיהוָ֑ה וְנִכְרְתָ֛ה הַנֶּ֥פֶשׁ הַהִ֖וא מֵעַמֶּֽיהָ׃ פ
22 Olúwa sọ fún Mose pé,
וַיְדַבֵּ֥ר יְהוָ֖ה אֶל־מֹשֶׁ֥ה לֵּאמֹֽר׃
23 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ má ṣe jẹ ọ̀rá màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́.
דַּבֵּ֛ר אֶל־בְּנֵ֥י יִשְׂרָאֵ֖ל לֵאמֹ֑ר כָּל־חֵ֜לֶב שׁ֥וֹר וְכֶ֛שֶׂב וָעֵ֖ז לֹ֥א תֹאכֵֽלוּ׃
24 Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko igbó pa, fún nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.
וְחֵ֤לֶב נְבֵלָה֙ וְחֵ֣לֶב טְרֵפָ֔ה יֵעָשֶׂ֖ה לְכָל־מְלָאכָ֑ה וְאָכֹ֖ל לֹ֥א תֹאכְלֻֽהוּ׃
25 Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa ni ẹ gbọdọ̀ gé kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.
כִּ֚י כָּל־אֹכֵ֣ל חֵ֔לֶב מִן־הַ֨בְּהֵמָ֔ה אֲשֶׁ֨ר יַקְרִ֥יב מִמֶּ֛נָּה אִשֶּׁ֖ה לַיהוָ֑ה וְנִכְרְתָ֛ה הַנֶּ֥פֶשׁ הָאֹכֶ֖לֶת מֵֽעַמֶּֽיהָ׃
26 Ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tàbí ẹran ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé.
וְכָל־דָּם֙ לֹ֣א תֹאכְל֔וּ בְּכֹ֖ל מוֹשְׁבֹתֵיכֶ֑ם לָע֖וֹף וְלַבְּהֵמָֽה׃
27 Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀, a ó gé ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.’”
כָּל־נֶ֖פֶשׁ אֲשֶׁר־תֹּאכַ֣ל כָּל־דָּ֑ם וְנִכְרְתָ֛ה הַנֶּ֥פֶשׁ הַהִ֖וא מֵֽעַמֶּֽיהָ׃ פ
28 Olúwa sọ fún Mose pé,
וַיְדַבֵּ֥ר יְהוָ֖ה אֶל־מֹשֶׁ֥ה לֵּאמֹֽר׃
29 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa.
דַּבֵּ֛ר אֶל־בְּנֵ֥י יִשְׂרָאֵ֖ל לֵאמֹ֑ר הַמַּקְרִ֞יב אֶת־זֶ֤בַח שְׁלָמָיו֙ לַיהוָ֔ה יָבִ֧יא אֶת־קָרְבָּנ֛וֹ לַיהוָ֖ה מִזֶּ֥בַח שְׁלָמָֽיו׃
30 Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífì.
יָדָ֣יו תְּבִיאֶ֔ינָה אֵ֖ת אִשֵּׁ֣י יְהוָ֑ה אֶת־הַחֵ֤לֶב עַל־הֶֽחָזֶה֙ יְבִיאֶ֔נּוּ אֵ֣ת הֶחָזֶ֗ה לְהָנִ֥יף אֹת֛וֹ תְּנוּפָ֖ה לִפְנֵ֥י יְהוָֽה׃
31 Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀,
וְהִקְטִ֧יר הַכֹּהֵ֛ן אֶת־הַחֵ֖לֶב הַמִּזְבֵּ֑חָה וְהָיָה֙ הֶֽחָזֶ֔ה לְאַהֲרֹ֖ן וּלְבָנָֽיו׃
32 kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà.
וְאֵת֙ שׁ֣וֹק הַיָּמִ֔ין תִּתְּנ֥וּ תְרוּמָ֖ה לַכֹּהֵ֑ן מִזִּבְחֵ֖י שַׁלְמֵיכֶֽם׃
33 Ọmọ Aaroni ẹni tí ó rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.
הַמַּקְרִ֞יב אֶת־דַּ֧ם הַשְּׁלָמִ֛ים וְאֶת־הַחֵ֖לֶב מִבְּנֵ֣י אַהֲרֹ֑ן ל֧וֹ תִהְיֶ֛ה שׁ֥וֹק הַיָּמִ֖ין לְמָנָֽה׃
34 Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Israẹli, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Aaroni àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Israẹli.’”
כִּי֩ אֶת־חֲזֵ֨ה הַתְּנוּפָ֜ה וְאֵ֣ת ׀ שׁ֣וֹק הַתְּרוּמָ֗ה לָקַ֙חְתִּי֙ מֵאֵ֣ת בְּנֵֽי־יִשְׂרָאֵ֔ל מִזִּבְחֵ֖י שַׁלְמֵיהֶ֑ם וָאֶתֵּ֣ן אֹ֠תָם לְאַהֲרֹ֨ן הַכֹּהֵ֤ן וּלְבָנָיו֙ לְחָק־עוֹלָ֔ם מֵאֵ֖ת בְּנֵ֥י יִשְׂרָאֵֽל׃
35 Èyí ni ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa lọ́jọ́ tí wọ́n mú wọn wá láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
זֹ֣את מִשְׁחַ֤ת אַהֲרֹן֙ וּמִשְׁחַ֣ת בָּנָ֔יו מֵאִשֵּׁ֖י יְהוָ֑ה בְּיוֹם֙ הִקְרִ֣יב אֹתָ֔ם לְכַהֵ֖ן לַיהוָֽה׃
36 Lọ́jọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni Olúwa ti pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa fún wọn ní àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ìgbà gbogbo fún àwọn ìran tó ń bọ̀.
אֲשֶׁר֩ צִוָּ֨ה יְהוָ֜ה לָתֵ֣ת לָהֶ֗ם בְּיוֹם֙ מָשְׁח֣וֹ אֹתָ֔ם מֵאֵ֖ת בְּנֵ֣י יִשְׂרָאֵ֑ל חֻקַּ֥ת עוֹלָ֖ם לְדֹרֹתָֽם׃
37 Nítorí náà, àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi, ìfinijoyè àlùfáà àti ẹbọ àlàáfíà
זֹ֣את הַתּוֹרָ֗ה לָֽעֹלָה֙ לַמִּנְחָ֔ה וְלַֽחַטָּ֖את וְלָאָשָׁ֑ם וְלַ֨מִּלּוּאִ֔ים וּלְזֶ֖בַח הַשְּׁלָמִֽים׃
38 èyí tí Olúwa fún Mose lórí òkè Sinai lọ́jọ́ tí Olúwa pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa mú ọrẹ wọn wá fún Olúwa ni ijù Sinai.
אֲשֶׁ֨ר צִוָּ֧ה יְהוָ֛ה אֶת־מֹשֶׁ֖ה בְּהַ֣ר סִינָ֑י בְּי֨וֹם צַוֺּת֜וֹ אֶת־בְּנֵ֣י יִשְׂרָאֵ֗ל לְהַקְרִ֧יב אֶת־קָרְבְּנֵיהֶ֛ם לַיהוָ֖ה בְּמִדְבַּ֥ר סִינָֽי׃ פ

< Leviticus 7 >