< Leviticus 6 >

1 Olúwa sọ fún Mose pé,
Yahweh parla à Moïse, en disant:
2 “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí Olúwa nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ,
« Si quelqu’un pèche et commet une infidélité envers Yahweh, en mentant à son prochain au sujet d’un dépôt, d’un gage mis entre ses mains, d’une chose volée, ou en faisant violence à son prochain;
3 tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀.
en mentant à propos d’un objet perdu qu’il a trouvé, en faisant un faux serment au sujet de l’une des choses dans lesquelles l’homme peut pécher:
4 Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he,
quand il aura péché ainsi et se sera rendu coupable, il restituera la chose volée ou ravie par violence, le dépôt qui lui avait été confié, l’objet perdu qu’il a trouvé,
5 tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀.
ou tout objet au sujet duquel il a fait un faux serment. Il le restituera en son entier, avec un cinquième de la valeur en sus, et le remettra à son propriétaire, le jour même où il offrira son sacrifice de réparation.
6 Fún ìtánràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní síwájú Olúwa, ẹbọ ẹ̀bi, àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́.
Il amènera au prêtre pour être offert à Yahweh en sacrifice de réparation un bélier sans défaut, pris du troupeau d’après ton estimation,
7 Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú Olúwa, a ó sì dáríjì í nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú un jẹ̀bi.”
Et le prêtre fera pour lui l’expiation devant Yahweh, et il lui sera pardonné, de quelque faute qu’il se soit rendu coupable. »
8 Olúwa sọ fún Mose pé,
Yahweh parla à Moïse, en disant:
9 “Pàṣẹ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ
« Donne cet ordre à Aaron et à ses fils, et dis-leur: Voici la loi de l’holocauste. L’holocauste brûlera sur le foyer de l’autel toute la nuit jusqu’au matin, et le feu de l’autel y sera tenu allumé.
10 kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.
Chaque matin, le prêtre, ayant revêtu sa tunique de lin et mis des caleçons de lin sur sa chair, enlèvera la cendre laissée par le feu qui aura consumé l’holocauste sur l’autel, et la déposera à côté de l’autel;
11 Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́.
puis il quittera ses vêtements et en mettra d’autres pour porter la cendre hors du camp, en un lieu pur.
12 Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀.
Le feu sur l’autel y sera entretenu sans qu’il s’éteigne; le prêtre y allumera du bois chaque matin, arrangera dessus l’holocauste, et y fera fumer la graisse des sacrifices pacifiques.
13 Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú.
Un feu perpétuel doit brûler sur l’autel sans s’éteindre.
14 “‘Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Aaroni gbé ẹbọ sísun náà wá síwájú Olúwa níwájú pẹpẹ.
Voici la loi de l’oblation: les fils d’Aaron la présenteront devant Yahweh, devant l’autel.
15 Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.
Le prêtre en prélèvera une poignée de fleur de farine avec son huile, et tout l’encens qui est sur l’oblation, et il fera fumer cela sur l’autel, en agréable odeur, comme souvenir à Yahweh.
16 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ láìsí máa wú máa wú ohun tí ń mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́.
Ce qui restera de l’oblation, Aaron et ses fils le mangeront; ils le mangeront sans levain, en lieu saint, dans le parvis de la tente de réunion.
17 Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú ìwúkàrà. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́.
On ne le cuira pas avec du levain. C’est la part que je leur ai assignée de mes offrandes consumées par le feu. C’est une chose très sainte, comme le sacrifice pour le péché et comme le sacrifice de réparation.
18 Èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Aaroni ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.’”
Tout mâle des enfants d’Aaron en mangera. C’est une loi perpétuelle pour vos descendants sur les offrandes faites par le feu à Yahweh. Quiconque y touchera sera saint. »
19 Olúwa sọ fún Mose pé,
Yahweh parla à Moïse, en disant:
20 “Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́.
« Voici l’offrande qu’Aaron et ses fils feront à Yahweh le jour où il recevra l’onction: un dixième d’épha de fleur de farine, comme oblation perpétuelle, moitié le matin et moitié le soir.
21 Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéékèèké bí òórùn dídùn sí Olúwa.
Elle sera préparée dans la poêle avec de l’huile; tu l’apporteras quand elle sera frite, et tu l’offriras en morceaux, comme offrande divisée, d’agréable odeur à Yahweh.
22 Ọmọkùnrin Aaroni tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti Olúwa títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátápátá.
Le prêtre ayant reçu l’onction, qui lui succédera d’entre ses fils, fera aussi cette oblation: c’est une loi perpétuelle devant Yahweh; elle montera tout entière en fumée.
23 Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátápátá, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.”
Toute offrande de prêtre sera consumée tout entière; on ne la mangera pas. »
24 Olúwa sọ fún Mose pé,
Yahweh parla à Moïse, en disant:
25 “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Olúwa, níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
« Parle à Aaron et à ses fils, et dis-leur: Voici la loi du sacrifice pour le péché: c’est dans le lieu où l’on égorge l’holocauste que sera égorgée la victime pour le péché devant Yahweh: c’est une chose très sainte.
26 Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.
Le prêtre qui offrira la victime pour le péché la mangera; elle sera mangée en lieu saint, dans le parvis de la tente de réunion.
27 Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́, bí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá sì ta sí ara aṣọ kan, ẹ gbọdọ̀ fọ̀ ọ́ ní ibi mímọ́.
Quiconque en touchera la chair sera saint. S’il en rejaillit du sang sur un vêtement, la place où le sang aura rejailli, tu la laveras en lieu saint.
28 Ẹ gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí ẹ fi se ẹran náà, ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìkòkò idẹ ni ẹ fi sè é, ẹ gbọdọ̀ bó o, kí ẹ sì fi omi sìn ín dáradára.
Le vase de terre dans lequel elle aura cuit sera brisé; si elle a cuit dans un vase d’airain, il sera nettoyé et rincé dans l’eau.
29 Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
Tout mâle parmi les prêtres en mangera: c’est une chose très sainte.
30 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tí wọ́n bá mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ètùtù ní Ibi Mímọ́, sísun ni kí ẹ sun ún.
Mais on ne mangera aucune victime pour le péché dont on doit porter le sang dans la tente de réunion pour faire l’expiation dans le sanctuaire: elle sera brûlée au feu.

< Leviticus 6 >