< Leviticus 3 >
1 “‘Bí ọrẹ ẹnìkan bá jẹ́ ọrẹ àlàáfíà, tí ó sì mú ẹran wá láti inú agbo màlúù yálà akọ tàbí abo, kí ó mú èyí tí kò ní àbùkù wá síwájú Olúwa.
But if his oblation will be a sacrifice of peace offerings, and he wishes to offer it from the oxen, whether male or female, he shall offer what is immaculate, in the sight of the Lord.
2 Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.
And he shall place his hand upon the head of his victim, which shall be immolated at the entrance of the tabernacle of the testimony. And the sons of Aaron, the priests, shall pour the blood all around the altar.
3 Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa, gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn.
And they shall offer from the sacrifice of peace offerings, as an oblation to the Lord: the fat which covers the vital organs, and whatever fat is interior,
4 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
the two kidneys with the fat that covers the sides, and the mesh of the liver with the two little kidneys.
5 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
And they shall burn them upon the altar as a holocaust, placing fire under the wood, as an oblation of a most sweet odor to the Lord.
6 “‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù.
Yet truly, if his oblation and the sacrifice of peace offerings will be from the sheep, whether he will offer a male or a female, they shall be immaculate.
7 Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́-àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
If he will offer a lamb in the sight of the Lord,
8 Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Aaroni wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.
he shall place his hand upon the head of the victim. And it shall be immolated at the vestibule of the tabernacle of the testimony. And the sons of Aaron shall pour its blood all around the altar.
9 Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun.
And they shall offer from the victim of peace offerings, as a sacrifice to the Lord: the fat, and the entire rump
10 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
with the kidneys, and the fat that covers the abdomen, and all the vital organs, and both the little kidneys with the fat that is near the sides, and the mesh of the liver with the little kidneys.
11 Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
And the priest shall burn them upon the altar, as fuel for the fire and as an oblation of the Lord.
12 “‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
If his oblation will be a goat, and he will offer it to the Lord,
13 Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.
he shall place his hand upon its head, and he shall immolate it at the entrance of the tabernacle of the testimony. And the sons of Aaron shall pour its blood all around the altar.
14 Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ẹbọ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn.
And they shall take from it, to feed the Lord’s fire: the fat which covers the abdomen, and that which covers all the vital organs,
15 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
the two little kidneys with the mesh that is over them near the sides, and the fat of the liver with the little kidneys.
16 Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa.
And the priest shall burn them upon the altar, as nourishment for the fire and as a most sweet odor. All the fat shall be for the Lord;
17 “‘Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀.’”
by a perpetual law, in your generations and in all of your habitations, neither blood nor fat shall you eat at all.