< Leviticus 24 >

1 Olúwa sọ fún Mose pé,
וידבר יהוה אל משה לאמר
2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara olifi wá láti fi tan iná, kí fìtílà lè máa jò láì kú.
צו את בני ישראל ויקחו אליך שמן זית זך כתית--למאור להעלת נר תמיד
3 Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.
מחוץ לפרכת העדת באהל מועד יערך אתו אהרן מערב עד בקר לפני יהוה--תמיד חקת עולם לדרתיכם
4 Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójoojúmọ́.
על המנרה הטהרה יערך את הנרות לפני יהוה תמיד
5 “Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan.
ולקחת סלת--ואפית אתה שתים עשרה חלות שני עשרנים יהיה החלה האחת
6 Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa.
ושמת אותם שתים מערכות שש המערכת על השלחן הטהר לפני יהוה
7 Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ sísun sí Olúwa.
ונתת על המערכת לבנה זכה והיתה ללחם לאזכרה אשה ליהוה
8 Àkàrà yìí ni kí ẹ gbé wá síwájú Olúwa nígbàkígbà, lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.
ביום השבת ביום השבת יערכנו לפני יהוה--תמיד מאת בני ישראל ברית עולם
9 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni í. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojoojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.”
והיתה לאהרן ולבניו ואכלהו במקום קדש כי קדש קדשים הוא לו מאשי יהוה--חק עולם
10 Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Ejibiti. Ó jáde lọ láàrín àwọn ọmọ Israẹli, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrín òun àti ọmọ Israẹli kan.
ויצא בן אשה ישראלית והוא בן איש מצרי בתוך בני ישראל וינצו במחנה בן הישראלית ואיש הישראלי
11 Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè, wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani.)
ויקב בן האשה הישראלית את השם ויקלל ויביאו אתו אל משה ושם אמו שלמית בת דברי למטה דן
12 Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.
ויניחהו במשמר לפרש להם על פי יהוה
13 Olúwa sì sọ fún Mose pé,
וידבר יהוה אל משה לאמר
14 “Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.
הוצא את המקלל אל מחוץ למחנה וסמכו כל השמעים את ידיהם על ראשו ורגמו אתו כל העדה
15 Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
ואל בני ישראל תדבר לאמר איש איש כי יקלל אלהיו ונשא חטאו
16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.
ונקב שם יהוה מות יומת רגום ירגמו בו כל העדה כגר כאזרח--בנקבו שם יומת
17 “‘Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á.
ואיש כי יכה כל נפש אדם--מות יומת
18 Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.
ומכה נפש בהמה ישלמנה--נפש תחת נפש
19 Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára, ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i.
ואיש כי יתן מום בעמיתו--כאשר עשה כן יעשה לו
20 Ẹ̀yà fún ẹ̀yà, ojú fún ojú, eyín fún eyín; bí òun ti ṣe àbùkù sí ara ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni kí a ṣe sí i.
שבר תחת שבר עין תחת עין שן תחת שן--כאשר יתן מום באדם כן ינתן בו
21 Ẹni tí ó bá sì lu ẹran pa, kí ó sán an padà; ẹni tí ó bá sì lu ènìyàn pa, a ó pa á.
ומכה בהמה ישלמנה ומכה אדם יומת
22 Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’”
משפט אחד יהיה לכם כגר כאזרח יהיה כי אני יהוה אלהיכם
23 Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀-òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose.
וידבר משה אל בני ישראל ויוציאו את המקלל אל מחוץ למחנה וירגמו אתו אבן ובני ישראל עשו כאשר צוה יהוה את משה

< Leviticus 24 >