< Leviticus 23 >

1 Olúwa sọ fún Mose wí pé,
וידבר יהוה אל משה לאמר
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, àwọn àjọ̀dún ti Olúwa èyí tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún tí a yàn.
דבר אל בני ישראל ואמרת אלהם מועדי יהוה אשר תקראו אתם מקראי קדש--אלה הם מועדי
3 “‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni.
ששת ימים תעשה מלאכה וביום השביעי שבת שבתון מקרא קדש כל מלאכה לא תעשו שבת הוא ליהוה בכל מושבתיכם
4 “‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, àjọ̀dún tí a yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákokò wọn.
אלה מועדי יהוה מקראי קדש אשר תקראו אתם במועדם
5 Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní.
בחדש הראשון בארבעה עשר לחדש--בין הערבים פסח ליהוה
6 Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ni àjọ̀dún àkàrà àìwú tí Olúwa yó bẹ̀rẹ̀, fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.
ובחמשה עשר יום לחדש הזה חג המצות ליהוה שבעת ימים מצות תאכלו
7 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan nínú rẹ̀.
ביום הראשון מקרא קדש יהיה לכם כל מלאכת עבדה לא תעשו
8 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.’”
והקרבתם אשה ליהוה שבעת ימים ביום השביעי מקרא קדש כל מלאכת עבדה לא תעשו
9 Olúwa sọ fún Mose pe,
וידבר יהוה אל משה לאמר
10 “Sọ fún àwọn ará Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírí ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.
דבר אל בני ישראל ואמרת אלהם כי תבאו אל הארץ אשר אני נתן לכם וקצרתם את קצירה--והבאתם את עמר ראשית קצירכם אל הכהן
11 Kí ó fi síírí ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.
והניף את העמר לפני יהוה לרצנכם ממחרת השבת יניפנו הכהן
12 Ní ọjọ́ tí ẹ bá fi síírí ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa.
ועשיתם ביום הניפכם את העמר כבש תמים בן שנתו לעלה ליהוה
13 Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì (èyí jẹ́ lita kan).
ומנחתו שני עשרנים סלת בלולה בשמן אשה ליהוה--ריח ניחח ונסכה יין רביעת ההין
14 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
ולחם וקלי וכרמל לא תאכלו עד עצם היום הזה--עד הביאכם את קרבן אלהיכם חקת עולם לדרתיכם בכל משבתיכם
15 “‘Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú ìdì ọkà fífì wá.
וספרתם לכם ממחרת השבת מיום הביאכם את עמר התנופה שבע שבתות תמימת תהיינה
16 Ẹ ka àádọ́ta ọjọ́ títí dé ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀ méjèèje, kí ẹ sì mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Olúwa.
עד ממחרת השבת השביעת תספרו חמשים יום והקרבתם מנחה חדשה ליהוה
17 Láti ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, ẹ mú ìṣù àkàrà méjì tí a fi òsùwọ̀n ìdá méjì nínú mẹ́wàá tí efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi ìwúkàrà ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì àkọ́so sí Olúwa.
ממושבתיכם תביאו לחם תנופה שתים שני עשרנים--סלת תהיינה חמץ תאפינה בכורים ליהוה
18 Ẹ fi akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù, ọmọ màlúù kan àti àgbò méjì kún àkàrà yìí, wọn yóò jẹ́ ẹbọ sísun sí Olúwa, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu wọn, àní ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn ni sí Olúwa.
והקרבתם על הלחם שבעת כבשים תמימם בני שנה ופר בן בקר אחד ואילם שנים יהיו עלה ליהוה ומנחתם ונסכיהם אשה ריח ניחח ליהוה
19 Lẹ́yìn náà kí ẹ fi akọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan fún ọrẹ àlàáfíà.
ועשיתם שעיר עזים אחד לחטאת ושני כבשים בני שנה לזבח שלמים
20 Kí àlùfáà fi ọ̀dọ́-àgùntàn méjèèjì náà níwájú Olúwa bí i ọrẹ fífì pẹ̀lú oúnjẹ àkọ́so wọn jẹ́ ọrẹ mímọ́ sí Olúwa fún àlùfáà.
והניף הכהן אתם על לחם הבכרים תנופה לפני יהוה על שני כבשים קדש יהיו ליהוה לכהן
21 Ní ọjọ́ yìí náà ni kí ẹ kéde ìpàdé àjọ mímọ́: ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ níbi yówù tí ẹ ń gbé.
וקראתם בעצם היום הזה מקרא קדש יהיה לכם--כל מלאכת עבדה לא תעשו חקת עולם בכל מושבתיכם לדרתיכם
22 “‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’”
ובקצרכם את קציר ארצכם לא תכלה פאת שדך בקצרך ולקט קצירך לא תלקט לעני ולגר תעזב אתם אני יהוה אלהיכם
23 Olúwa sọ fún Mose pé,
וידבר יהוה אל משה לאמר
24 “Sọ fún àwọn ará Israẹli, ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, kí ẹ ní ọjọ́ ìsinmi, ìpàdé àjọ mímọ́ tí a fi fèrè fífọn ṣe ìrántí.
דבר אל בני ישראל לאמר בחדש השביעי באחד לחדש יהיה לכם שבתון--זכרון תרועה מקרא קדש
25 Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojúmọ́, ṣùgbọ́n ẹ mú ọrẹ tí a fi iná sun wá síwájú Olúwa.’”
כל מלאכת עבדה לא תעשו והקרבתם אשה ליהוה
26 Olúwa sọ fún Mose pé,
וידבר יהוה אל משה לאמר
27 “Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa.
אך בעשור לחדש השביעי הזה יום הכפרים הוא מקרא קדש יהיה לכם ועניתם את נפשתיכם והקרבתם אשה ליהוה
28 Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.
וכל מלאכה לא תעשו בעצם היום הזה כי יום כפרים הוא לכפר עליכם לפני יהוה אלהיכם
29 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
כי כל הנפש אשר לא תענה בעצם היום הזה--ונכרתה מעמיה
30 Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
וכל הנפש אשר תעשה כל מלאכה בעצם היום הזה--והאבדתי את הנפש ההוא מקרב עמה
31 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
כל מלאכה לא תעשו חקת עולם לדרתיכם בכל משבתיכם
32 Ọjọ́ ìsinmi ni fún un yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsànán oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”
שבת שבתון הוא לכם ועניתם את נפשתיכם בתשעה לחדש בערב--מערב עד ערב תשבתו שבתכם
33 Olúwa sọ fún Mose pé,
וידבר יהוה אל משה לאמר
34 “Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.
דבר אל בני ישראל לאמר בחמשה עשר יום לחדש השביעי הזה חג הסכות שבעת ימים ליהוה
35 Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.
ביום הראשון מקרא קדש כל מלאכת עבדה לא תעשו
36 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojoojúmọ́.
שבעת ימים תקריבו אשה ליהוה ביום השמיני מקרא קדש יהיה לכם והקרבתם אשה ליהוה עצרת הוא--כל מלאכת עבדה לא תעשו
37 (“‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí Olúwa ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i àjọ̀dún tí a yàn fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa wá—ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
אלה מועדי יהוה אשר תקראו אתם מקראי קדש להקריב אשה ליהוה עלה ומנחה זבח ונסכים--דבר יום ביומו
38 Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi Olúwa, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún Olúwa.)
מלבד שבתת יהוה ומלבד מתנותיכם ומלבד כל נדריכם ומלבד כל נדבתיכם אשר תתנו ליהוה
39 “‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ ṣe àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.
אך בחמשה עשר יום לחדש השביעי באספכם את תבואת הארץ תחגו את חג יהוה שבעת ימים ביום הראשון שבתון וביום השמיני שבתון
40 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi dáradára, imọ̀ ọ̀pẹ, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, àti igi wílò odò, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.
ולקחתם לכם ביום הראשון פרי עץ הדר כפת תמרים וענף עץ עבת וערבי נחל ושמחתם לפני יהוה אלהיכם--שבעת ימים
41 Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, ẹ ṣe é ní oṣù keje.
וחגתם אתו חג ליהוה שבעת ימים בשנה חקת עולם לדרתיכם בחדש השביעי תחגו אתו
42 Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọ bíbí Israẹli gbé nínú àgọ́.
בסכת תשבו שבעת ימים כל האזרח בישראל ישבו בסכת
43 Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Israẹli gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’”
למען ידעו דרתיכם כי בסכות הושבתי את בני ישראל בהוציאי אותם מארץ מצרים אני יהוה אלהיכם
44 Báyìí ni Mose kéde àwọn àjọ̀dún tí a yàn Olúwa fún àwọn ọmọ Israẹli.
וידבר משה את מעדי יהוה אל בני ישראל

< Leviticus 23 >