< Leviticus 18 >
1 Olúwa sọ fún Mose pé:
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
3 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Ejibiti níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìṣe wọn.
4 Kí ẹ̀yin kí ó sì máa ṣe òfin mi, kí ẹ̀yin sì máa pa ìlànà mi mọ́, láti máa rìn nínú wọn, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
5 Ẹ̀yin ó sì máa pa ìlànà mi mọ́ àti òfin mi; Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn. Èmi ni Olúwa.
6 “‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀. Èmí ni Olúwa.
7 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.
8 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyàwó baba rẹ lòpọ̀, nítorí ìhòhò baba rẹ ni.
9 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.
10 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòhò wọn, ìhòhò ìwọ fúnra rẹ̀ ni.
11 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya baba rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún baba rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni.
12 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni.
13 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin màmá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.
14 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni.
15 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀.
16 “‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.
17 “‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.
18 “‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbí bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láààyè.
19 “‘Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni.
20 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.
21 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rú ẹbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Moleki, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.
22 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́.
23 “‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.
24 “‘Má ṣe fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ba ara rẹ jẹ́, torí pé nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé kúrò níwájú yín ti ba ara wọn jẹ́.
25 Nítorí pé ilẹ̀ náà di àìmọ́ nítorí náà mo fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ilẹ̀ náà sì pọ àwọn olùgbé ibẹ̀ jáde.
26 Ṣùgbọ́n kí ẹ máa pa àṣẹ àti òfin mi mọ́. Onílé tàbí àjèjì tó ń gbé láàrín yín kò gbọdọ̀ ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun ìríra wọ̀nyí.
27 Nítorí pé gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe tí ó sì mú kí ilẹ̀ náà di aláìmọ́.
28 Bí ẹ bá sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́ yóò pọ̀ yín jáde bí ó ti pọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti wá ṣáájú yín jáde.
29 “‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun ìríra wọ̀nyí, kí ẹ gé irú ẹni náà kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
30 Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ ṣe ohun tí mo fẹ́, kí ẹ má sì lọ́wọ́ nínú àṣà ìríra wọ̀nyí, tí wọn ń ṣe kí ẹ tó dé. Ẹ má ṣe fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’”