< Leviticus 16 >

1 Olúwa sọ fún Mose lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Aaroni méjèèjì tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ Olúwa.
Und der HERR redete mit Mose, nachdem die zwei Söhne Aarons gestorben waren, da sie vor dem HERRN opferten,
2 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí Ibi Mímọ́ Jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.
und sprach: Sage deinem Bruder Aaron, daß er nicht zu aller Zeit in das inwendige Heiligtum gehe hinter den Vorhang vor den Gnadenstuhl, der auf der Lade ist, daß er nicht sterbe; denn ich will in einer Wolke erscheinen auf dem Gnadenstuhl;
3 “Báyìí ni Aaroni yóò ṣe máa wá sí Ibi Mímọ́ Jùlọ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun.
sondern damit soll er hineingehen: mit einem jungen Farren zum Sündopfer und mit einem Widder zum Brandopfer,
4 Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í, yóò sì dé fìlà funfun, àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí. Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n.
und soll den heiligen leinenen Rock anlegen und leinene Beinkleider an seinem Fleisch haben und sich mit einem leinenen Gürtel gürten und den leinenen Hut aufhaben, denn das sind die heiligen Kleider, und soll sein Fleisch mit Wasser baden und sie anlegen.
5 Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n, àti àgbò kan fún ẹbọ sísun.
Und soll von der Gemeinde der Kinder Israel zwei Ziegenböcke nehmen zum Sündopfer und einen Widder zum Brandopfer.
6 “Aaroni yóò sì fi akọ màlúù rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ṣe ti ara rẹ̀ òun yóò sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀.
Und Aaron soll den Farren, sein Sündopfer, herzubringen, daß er sich und sein Haus versöhne,
7 Lẹ́yìn náà yóò sì mú ewúrẹ́ méjì náà wá sí iwájú Olúwa ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ ìpàdé.
und darnach die zwei Böcke nehmen und vor den HERRN stellen vor der Tür der Hütte des Stifts,
8 Aaroni yóò sì dìbò ní ti àwọn ewúrẹ́ méjèèjì náà, ìbò àkọ́kọ́ fún ti Olúwa, àti èkejì fún ewúrẹ́ ìpààrọ̀.
und soll das Los werfen über die zwei Böcke: ein Los dem HERRN, das andere dem Asasel.
9 Aaroni yóò sì mú ewúrẹ́ tí ìbò Olúwa mú, yóò sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
Und soll den Bock, auf welchen das Los des HERRN fällt, opfern zum Sündopfer.
10 Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láààyè síwájú Olúwa láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí aginjù.
Aber den Bock, auf welchen das Los für Asasel fällt, soll er lebendig vor den HERRN stellen, daß er über ihm versöhne, und lasse den Bock für Asasel in die Wüste.
11 “Aaroni yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.
Und also soll er denn den Farren seines Sündopfers herzubringen und sich und sein Haus versöhnen und soll ihn schlachten
12 Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá síwájú Olúwa: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa.
und soll einen Napf voll Glut vom Altar nehmen, der vor dem HERRN steht, und die Hand voll zerstoßenen Räuchwerks und es hinein hinter den Vorhang bringen
13 Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa: kí èéfín tùràrí náà ba à le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má ba à kú.
und das Räuchwerk aufs Feuer tun vor dem HERRN, daß der Nebel vom Räuchwerk den Gnadenstuhl bedecke, der auf dem Zeugnis ist, daß er nicht sterbe.
14 Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù náà yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn, ní iwájú ìtẹ́ àánú, yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn nígbà méje níwájú ìtẹ́ àánú.
Und soll von dem Blut des Farren nehmen und es mit seinem Finger auf den Gnadenstuhl sprengen vornean; vor den Gnadenstuhl aber soll er siebenmal mit seinem Finger vom Blut sprengen.
15 “Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti síwájú ìtẹ́ ètùtù.
Darnach soll er den Bock, des Volkes Sündopfer, schlachten und sein Blut hineinbringen hinter den Vorhang und soll mit seinem Blut tun, wie er mit des Farren Blut getan hat, und damit auch sprengen auf den Gnadenstuhl und vor den Gnadenstuhl;
16 Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún Ibi Mímọ́ Jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Israẹli àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà láàrín wọn nínú àìmọ́ wọn.
und soll also versöhnen das Heiligtum von der Unreinigkeit der Kinder Israel und von ihrer Übertretung in allen ihren Sünden. Also soll er auch tun der Hütte des Stifts; denn sie sind unrein, die umher lagern.
17 Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ láti ṣe ètùtù, títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnra rẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli.
Kein Mensch soll in der Hütte des Stifts sein, wenn er hineingeht, zu versöhnen im Heiligtum, bis er herausgehe; und soll also versöhnen sich und sein Haus und die ganze Gemeinde Israel.
18 “Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa, yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká.
Und wenn er herausgeht zum Altar, der vor dem HERRN steht, soll er ihn versöhnen und soll vom Blut des Farren und vom Blut des Bocks nehmen und es auf des Altars Hörner umher tun;
19 Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli.
und soll mit seinem Finger vom Blut darauf sprengen siebenmal und ihn reinigen und heiligen von der Unreinigkeit der Kinder Israel.
20 “Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti Ibi Mímọ́ Jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ, òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá.
Und wenn er vollbracht hat das Versöhnen des Heiligtums und der Hütte des Stifts und des Altars, so soll er den lebendigen Bock herzubringen.
21 Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí. Gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà.
Da soll Aaron seine beiden Hände auf sein Haupt legen und bekennen auf ihn alle Missetat der Kinder Israel und alle ihre Übertretung in allen ihren Sünden, und soll sie dem Bock auf das Haupt legen und ihn durch einen Mann, der bereit ist, in die Wüste laufen lassen,
22 Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.
daß also der Bock alle ihre Missetat auf sich in eine Wildnis trage; und er lasse ihn in die Wüste.
23 “Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.
Und Aaron soll in die Hütte des Stifts gehen und ausziehen die leinenen Kleider, die er anzog, da er in das Heiligtum ging, und soll sie daselbst lassen.
24 Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn.
Und soll sein Fleisch mit Wasser baden an heiliger Stätte und seine eigenen Kleider antun und herausgehen und sein Brandopfer und des Volkes Brandopfer machen und beide, sich und das Volk, versöhnen,
25 Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ.
und das Fett vom Sündopfer auf dem Altar anzünden.
26 “Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó.
Der aber den Bock für Asasel hat ausgeführt, soll seine Kleider waschen und sein Fleisch mit Wasser baden und darnach ins Lager kommen.
27 Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí Ibi Mímọ́ Jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà.
Den Farren des Sündopfers und den Bock des Sündopfers, deren Blut in das Heiligtum zu versöhnen gebracht ward, soll man hinausschaffen vor das Lager und mit Feuer verbrennen, Haut, Fleisch und Mist.
28 Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀, lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.
Und der sie verbrennt, soll seine Kleider waschen und sein Fleisch mit Wasser baden und darnach ins Lager kommen.
29 “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín, pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín.
Auch soll euch das ein ewiges Recht sein: am zehnten Tage des siebenten Monats sollt ihr euren Leib kasteien und kein Werk tun, weder ein Einheimischer noch ein Fremder unter euch.
30 Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́, kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo.
Denn an diesem Tage geschieht eure Versöhnung, daß ihr gereinigt werdet; von allen euren Sünden werdet ihr gereinigt vor dem HERRN.
31 Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín, ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé.
Darum soll's euch ein großer Sabbat sein, und ihr sollt euren Leib kasteien. Ein ewiges Recht sei das.
32 Àlùfáà náà tí a ti fi òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn ní ipò baba rẹ̀, òun ni kí ó ṣe ètùtù, yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà, òun yóò sì ṣe ètùtù.
Es soll aber solche Versöhnung tun ein Priester, den man geweiht und des Hand man gefüllt hat zum Priester an seines Vaters Statt; und er soll die leinenen Kleider antun, die heiligen Kleider,
33 Yóò sì ṣe ètùtù fún Ibi Mímọ́ Jùlọ, fún ìpàdé àti fún pẹpẹ, yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà.
und soll also versöhnen das heiligste Heiligtum und die Hütte des Stifts und den Altar und die Priester und alles Volk der Gemeinde.
34 “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Israẹli fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.” Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Das soll euch ein ewiges Recht sein, daß ihr die Kinder Israel versöhnt von allen ihren Sünden, im Jahr einmal. Und Aaron tat, wie der HERR dem Mose geboten hatte.

< Leviticus 16 >