< Leviticus 15 >

1 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,
וידבר יהוה אל משה ואל אהרן לאמר
2 “Ẹ bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí ẹ wí fún wọn pé, ‘Bí ìsunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara, ìsunjáde náà jẹ́ àìmọ́.
דברו אל בני ישראל ואמרתם אלהם איש איש כי יהיה זב מבשרו--זובו טמא הוא
3 Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìsunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́:
וזאת תהיה טמאתו בזובו רר בשרו את זובו או החתים בשרו מזובו--טמאתו הוא
4 “‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìsunjáde náà bá sùn di àìmọ́.
כל המשכב אשר ישכב עליו הזב--יטמא וכל הכלי אשר ישב עליו יטמא
5 Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
ואיש אשר יגע במשכבו--יכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
והישב על הכלי אשר ישב עליו הזב--יכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
7 “‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìsunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
והנגע בבשר הזב--יכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
8 “‘Bí ẹni tí ó ní ìsunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
וכי ירק הזב בטהור--וכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
9 “‘Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́.
וכל המרכב אשר ירכב עליו הזב--יטמא
10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
וכל הנגע בכל אשר יהיה תחתיו--יטמא עד הערב והנושא אותם--יכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
11 “‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde ní ara rẹ̀ bá fi ara kàn láìfi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
וכל אשר יגע בו הזב וידיו לא שטף במים--וכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
12 “‘Ìkòkò amọ̀ tí ọkùnrin náà bá fọwọ́ kàn ni kí ẹ fọ́, gbogbo ohun èlò igi tí ó fọwọ́ kàn ni kí ẹ fi omi sàn.
וכלי חרש אשר יגע בו הזב ישבר וכל כלי עץ--ישטף במים
13 “‘Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀nù kúrò nínú ìsunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́: kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì di mímọ́.
וכי יטהר הזב מזובו--וספר לו שבעת ימים לטהרתו וכבס בגדיו ורחץ בשרו במים חיים וטהר
14 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kí ó sì wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa, kí ó sì kó wọn fún àlùfáà.
וביום השמיני יקח לו שתי תרים או שני בני יונה ובא לפני יהוה אל פתח אהל מועד ונתנם אל הכהן
15 Kí àlùfáà fi wọ́n rú ẹbọ: ọ̀kan fún ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ọrẹ ẹbọ sísun níwájú Olúwa ní ipò ọkùnrin náà nítorí ìsunjáde rẹ̀.
ועשה אתם הכהן--אחד חטאת והאחד עלה וכפר עליו הכהן לפני יהוה מזובו
16 “‘Bí nǹkan ọkùnrin kan bá tú jáde, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
ואיש כי תצא ממנו שכבת זרע--ורחץ במים את כל בשרו וטמא עד הערב
17 Yálà àwọ̀ tàbí aṣọ tí nǹkan ọkùnrin bá dà sí lórí ni kí ẹ fọ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ di ìrọ̀lẹ́.
וכל בגד וכל עור אשר יהיה עליו שכבת זרע--וכבס במים וטמא עד הערב
18 Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin lòpọ̀ tí nǹkan ọkùnrin sì tú jáde lára rẹ̀. Àwọn méjèèjì gbọdọ̀ fi omi wẹ̀, kí wọ́n sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
ואשה אשר ישכב איש אתה שכבת זרע--ורחצו במים וטמאו עד הערב
19 “‘Bí obìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, obìnrin yìí wà ní àìmọ́ títí di ọjọ́ méje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
ואשה כי תהיה זבה דם יהיה זבה בבשרה--שבעת ימים תהיה בנדתה וכל הנגע בה יטמא עד הערב
20 “‘Gbogbo ohun tí ó bá sùn lé ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ di àìmọ́.
וכל אשר תשכב עליו בנדתה יטמא וכל אשר תשב עליו יטמא
21 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ibùsùn rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
וכל הנגע במשכבה--יכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
22 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó bá jókòó lé gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
וכל הנגע--בכל כלי אשר תשב עליו יכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
23 Ìbá à ṣe ibùsùn tàbí ohunkóhun tí ó jókòó lé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
ואם על המשכב הוא או על הכלי אשר הוא ישבת עליו--בנגעו בו יטמא עד הערב
24 “‘Bí ọkùnrin kan bá bá a lòpọ̀, tí nǹkan oṣù rẹ̀ sì kàn án lára, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, gbogbo ibùsùn tí ọkùnrin náà bá sùn yóò jẹ́ aláìmọ́.
ואם שכב ישכב איש אתה ותהי נדתה עליו--וטמא שבעת ימים וכל המשכב אשר ישכב עליו יטמא
25 “‘Bí obìnrin bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ yálà sí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá kọjá ìgbà tí ó yẹ. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ni yóò fi wà ní àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀.
ואשה כי יזוב זוב דמה ימים רבים בלא עת נדתה או כי תזוב על נדתה כל ימי זוב טמאתה כימי נדתה תהיה--טמאה הוא
26 Ibùsùn tí ó wù kí ó sùn sí ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ náà ń wá yóò jẹ́ àìmọ́ bí ibùsùn rẹ̀ ṣe jẹ́ ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá jókòó lé yóò wà ní àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀.
כל המשכב אשר תשכב עליו כל ימי זובה--כמשכב נדתה יהיה לה וכל הכלי אשר תשב עליו--טמא יהיה כטמאת נדתה
27 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn wọ́n yóò wà ní àìmọ́. Ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ kí ó sì wà ní àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
וכל הנוגע בם יטמא וכבס בגדיו ורחץ במים וטמא עד הערב
28 “‘Nígbà tí ó bá di mímọ́ kúrò nínú ìsun rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, a ó kà á sí mímọ́.
ואם טהרה מזובה--וספרה לה שבעת ימים ואחר תטהר
29 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé wá síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
וביום השמיני תקח לה שתי תרים או שני בני יונה והביאה אותם אל הכהן אל פתח אהל מועד
30 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
ועשה הכהן את האחד חטאת ואת האחד עלה וכפר עליה הכהן לפני יהוה מזוב טמאתה
31 “‘Ẹ ya ará Israẹli sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́, kí wọ́n má bá a kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́, èyí tí ó wà láàrín wọn.’”
והזרתם את בני ישראל מטמאתם ולא ימתו בטמאתם בטמאם את משכני אשר בתוכם
32 Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ọkùnrin tí ó ni ìsunjáde fún ẹnikẹ́ni tí a sọ di àìmọ́ nípa ìsunjáde nǹkan ọkùnrin rẹ̀.
זאת תורת הזב ואשר תצא ממנו שכבת זרע לטמאה בה
33 Fún obìnrin ní nǹkan oṣù rẹ̀, fún ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ní ìsunjáde, àti fún ọkùnrin tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́.
והדוה בנדתה והזב את זובו לזכר ולנקבה ולאיש אשר ישכב עם טמאה

< Leviticus 15 >