< Leviticus 14 >

1 Olúwa sọ fún Mose pé,
Et l'Éternel parla à Moïse en ces termes:
2 “Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú un tọ àlùfáà wá.
Voici le rite qu'observera le lépreux le jour de sa purification. Il sera conduit au Prêtre, et le Prêtre sortira hors du camp;
3 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà.
et, si l'examen du Prêtre constate que le lépreux est guéri de l'affection de la lèpre,
4 Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.
le Prêtre ordonnera d'apporter pour celui qui doit se purifier, deux oiseaux vivants purs et du bois de cèdre et du vermillon et de l'hysope.
5 Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀.
Et le Prêtre ordonnera d'égorger l'un des oiseaux dans un vase de terre sur de l'eau vive.
6 Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà.
Puis il prendra l'oiseau vivant et le bois de cèdre et le vermillon et l'hysope, qu'il trempera ainsi que l'oiseau vivant dans le sang de l'oiseau égorgé sur l'eau vive,
7 Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ìta gbangba.
et il fera sept aspersions sur celui qui se purifie de la lèpre et le purifiera, puis il lâchera l'oiseau vivant en pleine campagne.
8 “Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.
Et celui qui se purifie lavera ses vêtements et rasera tout son poil et se baignera dans de l'eau, et il sera en état de pureté; après quoi il pourra entrer au camp, mais il devra pendant sept jours loger hors de sa tente.
9 Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.
Et le septième jour il rasera tout son poil, il se rasera et barbe et chevelure et sourcils, tout son poil; et il lavera ses vêtements et baignera son corps dans l'eau, et ainsi il sera pur.
10 “Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àgbò aláìlábùkù méjì àti abo ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pòpọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n lógù òróró kan.
Et le huitième jour il apportera deux agneaux sans défaut et une brebis d'un an sans défaut avec trois dixièmes de fleur de farine, comme offrande, trempée dans l'huile, et un log d'huile.
11 Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́, yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
Et le Prêtre purificateur présentera l'homme qui se purifie, et ces objets devant l'Éternel à l'entrée de la Tente du Rendez-vous.
12 “Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti lógù òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Kí ó sì fì wọ́n níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì.
Et le Prêtre prendra l'un des agneaux qu'il offrira avec le log d'huile comme victime pour le délit, et il les agitera en oblation agitée devant l'Éternel;
13 Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
et il égorgera l'agneau dans le lieu où l'on égorge les victimes expiatoires et les holocaustes, en lieu saint; car de même que la victime expiatoire, la victime pour le délit appartient au Prêtre: elle est très sainte.
14 Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.
Et le Prêtre prendra du sang de la victime pour le délit, et il en mettra au bout de l'oreille droite de celui qui se purifie, et au pouce de sa main droite et au grand orteil de son pied droit.
15 Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú lógù òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.
Et le Prêtre prendra du log d'huile, et en versera dans sa main gauche, de lui Prêtre;
16 Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje.
et le Prêtre trempera son doigt de droite dans l'huile qu'il aura dans la main gauche, et avec son doigt il fera sept aspersions d'huile devant l'Éternel.
17 Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀mọ́, lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi.
Et le Prêtre mettra de l'huile qui lui reste dans la main, au bout de l'oreille droite de l'homme qui se purifie, et au pouce de sa main droite et au grand orteil de son pied droit, par-dessus le sang de la victime pour le délit.
18 Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa.
Et le reste de l'huile qu'il aura dans la main, le Prêtre le mettra sur la tête de l'homme qui se purifie, et le Prêtre fera la propitiation pour lui devant l'Éternel.
19 “Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun.
Et le Prêtre fera le sacrifice expiatoire, et la propitiation pour celui qui se purifie en suite de sa souillure; après quoi il égorgera l'holocauste.
20 Kí àlùfáà kí ó sì rú ẹbọ sísun, àti ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà kí ó sì ṣe ètùtù fún un, òun yóò sì di mímọ́.
Et le Prêtre apportera sur l'Autel l'holocauste et l'offrande, et fera la propitiation afin qu'il soit pur.
21 “Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òsùwọ̀n lógù òróró
Mais s'il est pauvre et que ses ressources ne suffisent pas, il prendra un agneau comme victime de délit, et l'offrira par agitation en propitiation pour lui, et un dixième de fleur de farine trempée d'huile, comme offrande, et un log d'huile,
22 àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.
et deux tourterelles, ou deux jeunes pigeons que comportent ses ressources, l'un comme victime expiatoire, l'autre comme holocauste.
23 “Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa.
Et il apportera ces choses le huitième jour au Prêtre pour sa purification à l'entrée de la Tente du Rendez-vous devant l'Éternel.
24 Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì.
Et le Prêtre prendra l'agneau, victime de délit, et le log d'huile qu'il présentera en oblation agitée devant l'Éternel.
25 Kí ó pa ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún.
Et le Prêtre égorgera l'agneau, victime de délit, et il prendra du sang de la victime de délit et en mettra au bout de l'oreille droite de celui qui se purifie, et au pouce de sa main droite et au grand orteil de son pied droit.
26 Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.
Et le Prêtre versera de l'huile dans sa main gauche, de lui Prêtre;
27 Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa.
et avec son doigt de droite, le Prêtre fera de l'huile qu'il a dans la main gauche, sept aspersions devant l'Éternel.
28 Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí.
Et le Prêtre mettra de l'huile qu'il a dans la main, au bout de l'oreille droite de celui qui se purifie et au pouce de sa main droite et au grand orteil de son pied droit à la place où il y a du sang de la victime de délit.
29 Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún, láti ṣe ètùtù fún un ní iwájú Olúwa.
Et le reste de l'huile qu'il a dans la main, le Prêtre le mettra sur la tête de l'homme qui se purifie, afin de faire la propitiation pour lui devant l'Éternel.
30 Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ.
Et il sacrifiera l'une des tourterelles ou l'un des jeunes pigeons que comportent ressources,
31 Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.”
ce que comportent ses ressources, l'un comme victime expiatoire, l'autre en holocauste, en même temps que l'offrande, et ainsi le Prêtre fera la propitiation pour celui, qui se purifie devant l'Éternel.
32 Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.
Tel est le rite que doit observer lors de sa purification celui qui est atteint de la lèpre et dont les ressources sont insuffisantes.
33 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé.
Et l'Éternel parla à Moïse et Aaron et dit:
34 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fi fún yín ní ìní, tí mo sì fi ààrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín.
Lorsque vous serez entrés au pays de Canaan que je vous donne en propriété, et que j'enverrai une atteinte de lèpre à une maison du pays dont vous prendrez possession,
35 Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’
le propriétaire de la maison viendra faire au Prêtre sa déclaration en ces termes: Je remarque comme une lèpre dans ma maison.
36 Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.
Et le Prêtre ordonnera de vider la maison avant qu'il arrive pour examiner le mal, afin que ce qui est dans la maison ne contracte pas la souillure,
37 Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.
et ensuite le Prêtre entrera pour examiner la maison. Et si l'examen qu'il fera du mal constate que l'altération des parois de la maison consiste dans des cavités d'une teinte verdâtre ou rougeâtre et déprimées au-dessous du niveau de la paroi,
38 Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje.
le Prêtre sortira de la maison dont il passera, la porte, et qu'il fermera pour sept jours.
39 Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri.
Et revenant le septième jour, s'il voit que le mal s'est étendu sur les parois de la maison,
40 Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí ààrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú.
le Prêtre ordonnera d'extraire les pierres attaquées et de les jeter hors de la ville dans un lieu impur.
41 Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà.
Puis l'on raclera la maison intérieurement partout, et l'on versera le crépi qu'on aura raclé, hors de la ville dans un lieu impur.
42 Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.
Et l'on prendra d'autres pierres que l'on mettra à la place des pierres [extraites], et l'on prendra d'autre crépi pour en enduire la maison.
43 “Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.
Et si le mal reparaît et fait éruption dans la maison après que les pierres auront été extraites, et la maison raclée, puis recrépie,
44 Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.
et si le Prêtre qui reviendra voit que le mal s'est étendu dans la maison, c'est une lèpre maligne dont la maison est atteinte, elle est souillée.
45 Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.
Alors on détruira la maison avec ses pierres, son bois et tout son crépi, et l'on portera le tout hors de la ville dans un lieu impur.
46 “Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
Et quiconque sera entré dans la maison pendant le temps de sa fermeture., sera jusqu'au soir en état d'impureté.
47 Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.
Et quiconque aura couché dans la maison, lavera ses habits; et quiconque aura mangé dans la maison lavera ses habits.
48 “Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí ààrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé ààrùn náà ti lọ.
Mais si le Prêtre qui reviendra voit que le mal ne s'est pas étendu dans la maison, une fois recrépie, le Prêtre la déclarera pure, car le mal est guéri.
49 Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi kedari òdòdó àti hísópù.
Et pour faire l'expiation de la maison il prendra deux oiseaux et du bois de cèdre et du vermillon et de l'hysope.
50 Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀.
Et il égorgera l'un des oiseaux dans un vase de terre sur de l'eau vive,
51 Kí ó ri igi kedari, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje.
et il prendra le bois de cèdre et l'hysope et le vermillon et l'oiseau vivant, qu'il trempera dans le sang de l'oiseau égorgé et dans l'eau vive et en fera sept aspersions contre la maison,
52 Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi kedari, hísópù àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́.
et fera ainsi l'expiation de la maison avec le sang de l'oiseau et avec l'eau vive et l'oiseau vivant et le bois de cèdre et l'hysope et le vermillon,
53 Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.”
puis il lâchera l'oiseau vivant hors de la ville en pleine campagne et fera ainsi la propitiation pour la maison, afin qu'elle soit pure.
54 Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyìí ààrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká, fún làpálàpá,
Telle est la loi touchant toute espèce de lèpre, et la teigne
55 àti fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, àti ti ilé,
et la lèpre des habits et des maisons,
56 fún ara wíwú, fún èélá àti ibi ara tí ó ń dán yàtọ̀.
et les élevures et les dartres et les taches,
57 Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́. Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ààrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀.
pour déterminer les cas d'impureté et les cas de pureté. Telle est la loi touchant la lèpre.

< Leviticus 14 >