< Lamentations 1 >

1 Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan, nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn! Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó wà ní ipò opó, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú ni ó padà di ẹrú.
איכה ישבה בדד העיר רבתי עם היתה כאלמנה רבתי בגוים שרתי במדינות היתה למס׃
2 Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀ wọ́n ti di alátakò rẹ̀.
בכו תבכה בלילה ודמעתה על לחיה אין לה מנחם מכל אהביה כל רעיה בגדו בה היו לה לאיבים׃
3 Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú, Juda lọ sí àjò Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi. Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́ ibi tí kò ti le sá àsálà.
גלתה יהודה מעני ומרב עבדה היא ישבה בגוים לא מצאה מנוח כל רדפיה השיגוה בין המצרים׃
4 Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀, nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn. Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro, àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn, àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú, òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.
דרכי ציון אבלות מבלי באי מועד כל שעריה שוממין כהניה נאנחים בתולתיה נוגות והיא מר לה׃
5 Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀, nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú, ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.
היו צריה לראש איביה שלו כי יהוה הוגה על רב פשעיה עולליה הלכו שבי לפני צר׃
6 Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín tí kò rí ewé tútù jẹ; nínú àárẹ̀ wọ́n sáré níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.
ויצא מן בת ציון כל הדרה היו שריה כאילים לא מצאו מרעה וילכו בלא כח לפני רודף׃
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.
זכרה ירושלם ימי עניה ומרודיה כל מחמדיה אשר היו מימי קדם בנפל עמה ביד צר ואין עוזר לה ראוה צרים שחקו על משבתה׃
8 Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀; ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò.
חטא חטאה ירושלם על כן לנידה היתה כל מכבדיה הזילוה כי ראו ערותה גם היא נאנחה ותשב אחור׃
9 Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu; olùtùnú kò sì ṣí fún un. “Wo ìpọ́njú mi, Olúwa, nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”
טמאתה בשוליה לא זכרה אחריתה ותרד פלאים אין מנחם לה ראה יהוה את עניי כי הגדיל אויב׃
10 Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.
ידו פרש צר על כל מחמדיה כי ראתה גוים באו מקדשה אשר צויתה לא יבאו בקהל לך׃
11 Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ láti mú wọn wà láààyè. “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
כל עמה נאנחים מבקשים לחם נתנו מחמודיהם באכל להשיב נפש ראה יהוה והביטה כי הייתי זוללה׃
12 “Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín? Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá. Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.
לוא אליכם כל עברי דרך הביטו וראו אם יש מכאוב כמכאבי אשר עולל לי אשר הוגה יהוה ביום חרון אפו׃
13 “Ó rán iná láti òkè sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi. Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi, ó sì yí mi padà. Ó ti pa mí lára mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.
ממרום שלח אש בעצמתי וירדנה פרש רשת לרגלי השיבני אחור נתנני שממה כל היום דוה׃
14 “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà; ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀. Wọ́n ti yí ọrùn mi ká Olúwa sì ti dín agbára mi kù. Ó sì ti fi mí lé àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.
נשקד על פשעי בידו ישתרגו עלו על צוארי הכשיל כחי נתנני אדני בידי לא אוכל קום׃
15 “Olúwa kọ àwọn akọni mi sílẹ̀, ó rán àwọn ológun lòdì sí mi kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run. Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda.
סלה כל אבירי אדני בקרבי קרא עלי מועד לשבר בחורי גת דרך אדני לבתולת בת יהודה׃
16 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún tí omijé sì ń dà lójú mi. Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi, kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà. Àwọn ọmọ mi di aláìní nítorí ọ̀tá ti borí.”
על אלה אני בוכיה עיני עיני ירדה מים כי רחק ממני מנחם משיב נפשי היו בני שוממים כי גבר אויב׃
17 Sioni na ọwọ́ jáde, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un Jerusalẹmu ti di ohun aláìmọ́ láàrín wọn.
פרשה ציון בידיה אין מנחם לה צוה יהוה ליעקב סביביו צריו היתה ירושלם לנדה ביניהם׃
18 “Olóòtítọ́ ni Olúwa, ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀. Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn; ẹ wò mí wò ìyà mi. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.
צדיק הוא יהוה כי פיהו מריתי שמעו נא כל עמים וראו מכאבי בתולתי ובחורי הלכו בשבי׃
19 “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣùgbọ́n wọ́n dà mí. Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi ṣègbé sínú ìlú nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóò mú wọn wà láààyè.
קראתי למאהבי המה רמוני כהני וזקני בעיר גועו כי בקשו אכל למו וישיבו את נפשם׃
20 “Olúwa, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira! Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi, ìdààmú dé bá ọkàn mi nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi. Ní gbangba ni idà ń parun; ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.
ראה יהוה כי צר לי מעי חמרמרו נהפך לבי בקרבי כי מרו מריתי מחוץ שכלה חרב בבית כמות׃
21 “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi. Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi; wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe. Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde, kí wọ́n le dàbí tèmi.
שמעו כי נאנחה אני אין מנחם לי כל איבי שמעו רעתי ששו כי אתה עשית הבאת יום קראת ויהיו כמוני׃
22 “Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ; jẹ wọ́n ní yà bí o ṣe jẹ mí ní yà nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”
תבא כל רעתם לפניך ועולל למו כאשר עוללת לי על כל פשעי כי רבות אנחתי ולבי דוי׃

< Lamentations 1 >