< Lamentations 3 >

1 Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
I am the man who has seen affliction under the rod of God’s wrath.
2 Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.
He has driven me away and made me walk in darkness instead of light.
3 Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
Indeed, He keeps turning His hand against me all day long.
4 Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
He has worn away my flesh and skin; He has shattered my bones.
5 Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
He has besieged me and surrounded me with bitterness and hardship.
6 Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
He has made me dwell in darkness like those dead for ages.
7 Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
He has walled me in so I cannot escape; He has weighed me down with chains.
8 Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.
Even when I cry out and plead for help, He shuts out my prayer.
9 Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.
He has barred my ways with cut stones; He has made my paths crooked.
10 Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.
He is a bear lying in wait, a lion hiding in ambush.
11 Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.
He forced me off my path and tore me to pieces; He left me without help.
12 Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
He bent His bow and set me as the target for His arrow.
13 Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
He pierced my kidneys with His arrows.
14 Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
I am a laughingstock to all my people; they mock me in song all day long.
15 Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.
He has filled me with bitterness; He has intoxicated me with wormwood.
16 Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
He has ground my teeth with gravel and trampled me in the dust.
17 Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
My soul has been deprived of peace; I have forgotten what prosperity is.
18 Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”
So I say, “My strength has perished, along with my hope from the LORD.”
19 Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.
Remember my affliction and wandering, the wormwood and the gall.
20 Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
Surely my soul remembers and is humbled within me.
21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.
Yet I call this to mind, and therefore I have hope:
22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
Because of the loving devotion of the LORD we are not consumed, for His mercies never fail.
23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀.
They are new every morning; great is Your faithfulness!
24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
“The LORD is my portion,” says my soul, “therefore I will hope in Him.”
25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.
The LORD is good to those who wait for Him, to the soul who seeks Him.
26 Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.
It is good to wait quietly for the salvation of the LORD.
27 Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.
It is good for a man to bear the yoke while he is still young.
28 Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.
Let him sit alone in silence, for God has disciplined him.
29 Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.
Let him bury his face in the dust— perhaps there is still hope.
30 Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
Let him offer his cheek to the one who would strike him; let him be filled with reproach.
31 Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
For the Lord will not cast us off forever.
32 Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
Even if He causes grief, He will show compassion according to His abundant loving devotion.
33 Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
For He does not willingly afflict or grieve the sons of men.
34 Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
To crush underfoot all the prisoners of the land,
35 Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,
to deny a man justice before the Most High,
36 láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.
to subvert a man in his lawsuit— of these the Lord does not approve.
37 Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
Who has spoken and it came to pass, unless the Lord has ordained it?
38 Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá?
Do not both adversity and good come from the mouth of the Most High?
39 Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?
Why should any mortal man complain, in view of his sins?
40 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ.
Let us examine and test our ways, and turn back to the LORD.
41 Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,
Let us lift up our hearts and hands to God in heaven:
42 “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.
“We have sinned and rebelled; You have not forgiven.”
43 “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú.
You have covered Yourself in anger and pursued us; You have killed without pity.
44 Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
You have covered Yourself with a cloud that no prayer can pass through.
45 Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
You have made us scum and refuse among the nations.
46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa.
All our enemies open their mouths against us.
47 Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
Panic and pitfall have come upon us— devastation and destruction.
48 Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.
Streams of tears flow from my eyes over the destruction of the daughter of my people.
49 Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi,
My eyes overflow unceasingly, without relief,
50 títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
until the LORD looks down from heaven and sees.
51 Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.
My eyes bring grief to my soul because of all the daughters of my city.
52 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.
Without cause my enemies hunted me like a bird.
53 Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí.
They dropped me alive into a pit and cast stones upon me.
54 Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.
The waters flowed over my head, and I thought I was going to die.
55 Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
I called on Your name, O LORD, out of the depths of the Pit.
56 Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
You heard my plea: “Do not ignore my cry for relief.”
57 O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”
You drew near when I called on You; You said, “Do not be afraid.”
58 Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
You defend my cause, O Lord; You redeem my life.
59 O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. Gba ẹjọ́ mi ró!
You have seen, O LORD, the wrong done to me; vindicate my cause!
60 Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.
You have seen all their malice, all their plots against me.
61 Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,
O LORD, You have heard their insults, all their plots against me—
62 ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́.
the slander and murmuring of my assailants against me all day long.
63 Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.
When they sit and when they rise, see how they mock me in song.
64 Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
You will pay them back what they deserve, O LORD, according to the work of their hands.
65 Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré.
Put a veil of anguish over their hearts; may Your curse be upon them!
66 Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run Olúwa.
You will pursue them in anger and exterminate them from under Your heavens, O LORD.

< Lamentations 3 >