< Judges 4 >
1 Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa.
Da Ehud var død, gjorde Israels barn atter det som var ondt i Herrens øine.
2 Nítorí náà Olúwa jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu.
Og Herren solgte dem i Jabins, Kana'ans konges hånd; han regjerte i Hasor; hans hærfører var Sisera, som bodde i Haroset-Haggojim.
3 Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.
Og Israels barn ropte til Herren; for han hadde ni hundre jernvogner, og han trengte Israels barn hårdt i tyve år.
4 Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà.
Og Debora, en profetinne, Lappidots hustru, dømte Israel på denne tid;
5 Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀.
hun satt under Deboras palmetre mellem Rama og Betel på Efra'im-fjellet, og Israels barn gikk op til henne forat hun skulde skifte rett mellem dem.
6 Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “Olúwa, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé, ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori.
Hun sendte bud og kalte til sig Barak, Abinoams sønn, fra Kedes i Naftali og sa til ham: Hør hvad Herren, Israels Gud, har befalt: Gå av sted og dra op på Tabor-fjellet og ta med dig ti tusen mann av Naftalis barn og av Sebulons barn!
7 Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’”
Og jeg vil dra Sisera, Jabins hærfører, og hans vogner og hans hær bort til dig, til Kison-bekken, og gi ham i din hånd.
8 Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”
Da sa Barak til henne: Hvis du går med mig, vil jeg gå; men hvis du ikke går med mig, så går heller ikke jeg.
9 Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́,” báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi.
Og hun sa: Gå med dig skal jeg; men æren skal dog ikke bli din på den vei du går, for i en kvinnes hånd skal Herren selge Sisera. Så gjorde Debora sig rede og gikk med Barak til Kedes.
10 Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ.
Og Barak stevnet Sebulon og Naftali sammen til Kedes, og ti tusen mann drog op efter ham; og Debora gikk med ham.
11 Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi.
Men kenitten Heber hadde skilt sig fra kenittene, fra Hobabs, Moses' svogers barn; og han flyttet med sine telt like til Sa'ana'im-eken ved Kedes.
12 Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori,
Da Sisera fikk spurt at Barak, Abinoams sønn, hadde draget op på Tabor-fjellet,
13 Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni.
stevnet han sammen alle sine vogner, ni hundre jernvogner, og alt det folk som var med ham, at de skulde komme fra Haroset-Haggojim til Kison-bekken.
14 Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori.
Da sa Debora til Barak: Op! Dette er den dag da Herren har gitt Sisera i din hånd; drar ikke Herren ut foran dig? Så drog Barak ned fra Tabor-fjellet, og ti tusen mann fulgte ham.
15 Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ.
Da slo Herren Sisera og alle vognene og hele hæren med redsel, så de ikke kunde stå sig for Baraks sverd; og Sisera steg ned av vognen og flyktet til fots.
16 Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè.
Men Barak forfulgte vognene og hæren til Haroset-Haggojim, og hele Siseras hær falt for sverdets egg; det blev ikke en eneste tilbake.
17 Ṣùgbọ́n Sisera ti fi ẹsẹ̀ sálọ sí àgọ́ Jaeli aya Heberi ẹ̀yà Keni: nítorí ìbá dá ọ̀rẹ́ àlàáfíà wà láàrín Jabini ọba Hasori àti ìdílé Heberi ti ẹ̀yà Keni.
Sisera flyktet til fots til Jaels telt; hun var kenitten Hebers hustru, og der var fred mellem Jabin, kongen i Hasor, og kenitten Hebers hus.
18 Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.
Da gikk Jael ut mot Sisera og sa til ham: Kom inn, herre, kom inn til mig, frykt ikke! Og han gikk inn i teltet til henne, og hun gjemte ham under teppet.
19 Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.
Og han sa til henne: Kjære, gi mig litt vann å drikke! Jeg er tørst. Da åpnet hun melkeflasken og lot ham drikke og dekket ham til.
20 Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’”
Og han sa til henne: Stå i teltdøren, og dersom det kommer nogen og spør dig: Er det nogen her? da si nei!
21 Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú.
Men Jael, Hebers hustru, tok en teltplugg og gikk sakte inn til ham med en hammer i hånden og slo pluggen gjennem tinningen på ham, så den gikk ned i jorden; for trett som han var, var han falt i tung søvn. Således døde han.
22 Nígbà tí Baraki dé bí ó ti ń lépa Sisera, Jaeli láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsi Sisera dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú.
Da nu Barak forfulgte Sisera, gikk Jael ut imot ham og sa til ham: Kom, så skal jeg vise dig den mann du søker efter. Og han gikk inn til henne, og se, der lå Sisera død med pluggen gjennem tinningen.
23 Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
Så ydmyket Gud på denne dag Jabin, Kana'ans konge, for Israels barns øine.
24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
Og Israels barns hånd lå tyngre og tyngre på Jabin, Kana'ans konge, til de helt hadde gjort ende på Jabin, Kana'ans konge.