< Judges 3 >
1 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani.
2 (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun).
3 Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati.
4 A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose.
5 Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi.
6 Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.
7 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah.
8 Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.
9 Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.
10 Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu.
11 Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú.
12 Àwọn ọmọ Israẹli sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí, Olúwa fún Egloni, ọba àwọn Moabu ní agbára ní orí Israẹli.
13 Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ammoni àti àwọn ọmọ-ogun Amaleki ní Egloni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ tí i se Jeriko.
14 Àwọn ọmọ Israẹli sì sin Egloni ọba Moabu fún ọdún méjìdínlógún.
15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli tún ké pe Olúwa, Olúwa rán olùgbàlà kan sí wọn, Ehudu ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gera ti ẹ̀yà Benjamini. Àwọn ọmọ Israẹli fi ẹ̀bùn rán sí Egloni ọba Moabu.
16 Ehudu sì rọ idà kan olójú méjì, ìgbọ̀nwọ́ kan ní gígùn; òun sì sán an ní abẹ́ aṣọ rẹ̀ ní itan rẹ̀ ọ̀tún.
17 Ó sì mú ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, Egloni ẹni tí ó sanra púpọ̀.
18 Lẹ́yìn tí Ehudu ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn.
19 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnra rẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń ṣọ sì jáde síta kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
20 Ehudu lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Ehudu sì wí fún un pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀,
21 Ehudu fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀.
22 Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ehudu kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà.
23 Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
24 Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.”
25 Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.
26 Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Ehudu ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Seira.
27 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn.
28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.
29 Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.
30 Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.
31 Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ẹgbẹ̀ta Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú.