< Judges 2 >

1 Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa dìde kúrò láti Gilgali lọ sí Bokimu ó sì wí pé, “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, èmi sì síwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín. Èmi sì wí pé, ‘Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín,
主の使がギルガルからボキムに上って言った、「わたしはあなたがたをエジプトから上らせて、あなたがたの先祖に誓った地に連れてきて、言った、『わたしはあなたと結んだ契約を決して破ることはない。
2 ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò wó pẹpẹ ibi ìsin òrìṣà wọn lulẹ̀.’ Síbẹ̀ ẹ̀yin ṣe àìgbọ́ràn sí mi. Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí?
あなたがたはこの国の住民と契約を結んではならない。彼らの祭壇をこぼたなければならない』と。しかし、あなたがたはわたしの命令に従わなかった。あなたがたは、なんということをしたのか。
3 Ní báyìí, èmi wí fún un yín pé, èmi kì yóò lé àwọn ènìyàn jáde kúrò níwájú yín; ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ ẹ̀gún ní ìhà yín, àwọn òrìṣà wọn yóò sì jẹ́ ìdánwò fún un yín.”
それでわたしは言う、『わたしはあなたがたの前から彼らを追い払わないであろう。彼らはかえってあなたがたの敵となり、彼らの神々はあなたがたのわなとなるであろう』と」。
4 Bí angẹli Olúwa sì ti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli tan, àwọn ènìyàn náà sì gbé ohùn wọn sókè wọ́n sì sọkún kíkorò,
主の使がこれらの言葉をイスラエルのすべての人々に告げたので、民は声をあげて泣いた。
5 wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu (ibi tí àwọn ènìyàn ti sọkún). Wọ́n sì rú ẹbọ sí Olúwa níbẹ̀.
それでその所の名をボキムと呼んだ。そして彼らはその所で主に犠牲をささげた。
6 Lẹ́yìn tí Joṣua ti tú àwọn ènìyàn Israẹli ká, àwọn ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn.
ヨシュアが民を去らせたので、イスラエルの人々はおのおのその領地へ行って土地を獲た。
7 Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli.
民はヨシュアの在世中も、またヨシュアのあとに生き残った長老たち、すなわち主がかつてイスラエルのために行われたすべての大いなるわざを見た人々の在世中も主に仕えた。
8 Joṣua ọmọ Nuni, ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún.
こうして主のしもべヌンの子ヨシュアは百十歳で死んだ。
9 Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Timnati-Hereki ní ilẹ̀ òkè Efraimu ní àríwá òkè Gaaṣi.
人々は彼をエフライムの山地のガアシ山の北のテムナテ・ヘレスにある彼の領地内に葬った。
10 Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Israẹli.
そしてその時代の者もまたことごとくその先祖たちのもとにあつめられた。その後ほかの時代が起ったが、これは主を知らず、また主がイスラエルのために行われたわざをも知らなかった。
11 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali.
イスラエルの人々は主の前に悪を行い、もろもろのバアルに仕え、
12 Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú,
かつてエジプトの地から彼らを導き出された先祖たちの神、主を捨てて、ほかの神々すなわち周囲にある国民の神々に従い、それにひざまずいて、主の怒りをひき起した。
13 nítorí tí wọ́n kọ̀ Olúwa sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti.
すなわち彼らは主を捨てて、バアルとアシタロテに仕えたので、
14 Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.
主の怒りがイスラエルに対して燃え、かすめ奪う者の手にわたして、かすめ奪わせ、かつ周囲のもろもろの敵の手に売られたので、彼らは再びその敵に立ち向かうことができなかった。
15 Nígbàkígbà tí àwọn Israẹli bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀tá a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn. Wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.
彼らがどこへ行っても、主の手は彼らに災をした。これは主がかつて言われ、また主が彼らに誓われたとおりで、彼らはひどく悩んだ。
16 Olúwa sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń kó wọn lẹ́rú.
その時、主はさばきづかさを起して、彼らをかすめ奪う者の手から救い出された。
17 Síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídàájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọ́ràn sí àwọn òfin Olúwa.
しかし彼らはそのさばきづかさにも従わず、かえってほかの神々を慕ってそれと姦淫を行い、それにひざまずき、先祖たちが主の命令に従って歩んだ道を、いちはやく離れ去って、そのようには行わなかった。
18 Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láààyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n.
主が彼らのためにさばきづかさを起されたとき、そのさばきづかさの在世中、主はさばきづかさと共におられて、彼らを敵の手から救い出された。これは彼らが自分をしえたげ悩ました者のゆえに、うめき悲しんだので、主が彼らをあわれまれたからである。
19 Ṣùgbọ́n ní kété tí onídàájọ́ bá ti kú, àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.
しかしさばきづかさが死ぬと、彼らはそむいて、先祖たちにまさって悪を行い、ほかの神々に従ってそれに仕え、それにひざまずいてそのおこないをやめず、かたくなな道を離れなかった。
20 Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Israẹli a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mú tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi,
それで主はイスラエルに対し激しく怒って言われた、「この民はわたしがかつて先祖たちに命じた契約を犯し、わたしの命令に従わないゆえ、
21 Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Joṣua fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde.
わたしもまたヨシュアが死んだときに残しておいた国民を、この後、彼らの前から追い払わないであろう。
22 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Israẹli wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn.”
これはイスラエルが、先祖たちの守ったように主の道を守ってそれに歩むかどうかをわたしが試みるためである」。
23 Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Israẹli pa wọ́n run, bẹ́ẹ̀ kò sì fi wọ́n lé Joṣua lọ́wọ́.
それゆえ主はこれらの国民を急いで追い払わずに残しておいて、ヨシュアの手にわたされなかったのである。

< Judges 2 >