< Judges 12 >
1 Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”
And the men of Ephraim are called together, and pass over northward, and say to Jephthah, “Why have you passed over to fight against the sons of Ammon, and have not called on us to go with you? We burn your house with fire over you.”
2 Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn.
And Jephthah says to them, “I have been a man of great strife (I and my people) with the sons of Ammon, and I call you, and you have not saved me out of their hand,
3 Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”
and I see that you are not a savior, and I put my life in my hand, and pass over to the sons of Ammon, and YHWH gives them into my hand—and why have you come up to me this day to fight against me?”
4 Nígbà náà ni Jefta kó gbogbo ọkùnrin Gileadi jọ, ó sì bá Efraimu jà. Àwọn ọkùnrin Gileadi sì kọlù Efraimu, nítorí wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gileadi jẹ́ àsáwọ̀ àwọn ará Efraimu àti ti Manase.”
And Jephthah gathered all the men of Gilead, and fights with Ephraim, and the men of Gilead strike Ephraim, because they said, “You Gileadites [are] fugitives of Ephraim, in the midst of Ephraim—in the midst of Manasseh.”
5 Àwọn ará Gileadi gba à bá wọ odò Jordani tí wọ́n máa gbà lọ sí Efraimu, nígbàkígbà tí àwọn ará Efraimu bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sálọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gileadi yóò bi í pé, “Ṣé ará Efraimu ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,”
And Gilead captures the passages of the Jordan to Ephraim, and it has been, when [any of] the fugitives of Ephraim say, “Let me pass over,” and the men of Gilead say to him, “[Are] you an Ephraimite?” And he says, “No”;
6 wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣibolẹti.’” Tí ó bá ní, “Sibolẹti,” torí pé kò ní mọ̀ ọ́n pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì ọkùnrin.
that they say to him, “Now say, Shibboleth”; and he says, “Sibboleth,” and is not prepared to speak right—and they seize him, and slaughter him at the passages of the Jordan, and there fall at that time, of Ephraim, forty-two chiefs.
7 Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi.
And Jephthah judged Israel [for] six years, and Jephthah the Gileadite dies, and is buried in [one of] the cities of Gilead.
8 Lẹ́yìn Jefta, Ibsani ará Bẹtilẹhẹmu ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli.
And after him Ibzan of Beth-Lehem judges Israel,
9 Ó ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ibsani ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méje.
and he has thirty sons, and thirty daughters he gave away [in marriage], and thirty daughters he brought in from outside for his sons; and he judges Israel [for] seven years.
10 Lẹ́yìn náà ni Ibsani kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹtilẹhẹmu.
And Ibzan dies, and is buried in Beth-Lehem.
11 Lẹ́yìn rẹ̀, Eloni ti ẹ̀yà Sebuluni ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́wàá.
And after him Elon the Zebulunite judges Israel, and he judges Israel [for] ten years,
12 Eloni sì kú, wọ́n sì sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni.
and Elon the Zebulunite dies, and is buried in Aijalon, in the land of Zebulun.
13 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hileli tí Piratoni n ṣe àkóso Israẹli.
And after him, Abdon son of Hillel, the Pirathonite, judges Israel,
14 Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́jọ.
and he has forty sons, and thirty grandsons, riding on seventy donkey-colts, and he judges Israel [for] eight years.
15 Abdoni ọmọ Hileli sì kú, wọ́n sin ín sí Piratoni ní ilé Efraimu ní ìlú òkè àwọn ará Amaleki.
And Abdon son of Hillel, the Pirathonite, dies, and is buried in Pirathon, in the land of Ephraim, in the hill-country of the Amalekite.