< Judges 11 >

1 Jefta ará Gileadi jẹ́ akọni jagunjagun. Gileadi ni baba rẹ̀; ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ panṣágà.
さてギレアデびとエフタは強い勇士であったが遊女の子で、エフタの父はギレアデであった。
2 Ìyàwó Gileadi sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jefta jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ ọmọ obìnrin mìíràn.”
ギレアデの妻も子供を産んだが、その妻の子供たちが成長したとき、彼らはエフタを追い出して彼に言った、「あなたはほかの女の産んだ子だから、わたしたちの父の家を継ぐことはできません」。
3 Jefta sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tobu, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ òfin lójú parapọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri.
それでエフタはその兄弟たちのもとから逃げ去って、トブの地に住んでいると、やくざ者がエフタのもとに集まってきて、彼と一緒に出かけて略奪を事としていた。
4 Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ammoni dìde ogun sí àwọn Israẹli,
日がたって後、アンモンの人々はイスラエルと戦うことになり、
5 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn Ammoni bá Israẹli jagun, àwọn àgbàgbà Gileadi tọ Jefta lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tobu.
アンモンの人々がイスラエルと戦ったとき、ギレアデの長老たちは行ってエフタをトブの地から連れてこようとして、
6 Wọ́n wí fún Jefta wí pé, “Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ammoni.”
エフタに言った、「きて、わたしたちの大将になってください。そうすればわたしたちはアンモンの人々と戦うことができます」。
7 Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Ṣé kì í ṣe pé ẹ kórìíra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?”
エフタはギレアデの長老たちに言った、「あなたがたはわたしを憎んで、わたしの父の家から追い出したではありませんか。しかるに今あなたがたが困っている時とはいえ、わたしのところに来るとはどういうわけですか」。
8 Àwọn àgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ammoni, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gileadi.”
ギレアデの長老たちはエフタに言った、「それでわたしたちは今、あなたに帰ったのです。どうぞ、わたしたちと一緒に行って、アンモンの人々と戦ってください。そしてわたしたちとギレアデに住んでいるすべてのものとのかしらになってください」。
9 Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ammoni jà àti tí Olúwa bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́?”
エフタはギレアデの長老たちに言った、「もしあなたがたが、わたしをつれて帰って、アンモンの人々と戦わせるとき、主が彼らをわたしにわたされるならば、わたしはあなたがたのかしらとなりましょう」。
10 Àwọn àgbàgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Àwa fi Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí: àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí.”
ギレアデの長老たちはエフタに言った、「主はあなたとわたしたちの間の証人です。わたしたちは必ずあなたの言われるとおりにしましょう」。
11 Jefta sì tẹ̀lé àwọn àgbàgbà Gileadi lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn. Jefta sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ níwájú Olúwa ní Mispa.
そこでエフタはギレアデの長老たちと一緒に行った。民は彼を立てて自分たちのかしらとし、大将とした。それでエフタはミヅパで、自分の言葉をことごとく主の前に述べた。
12 Jefta sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ammoni pé, “Kí ni ẹ̀sùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?”
かくてエフタはアンモンの人々の王に使者をつかわして言った、「あなたはわたしとなんのかかわりがあって、わたしのところへ攻めてきて、わたしの国と戦おうとするのですか」。
13 Ọba àwọn Ammoni dá àwọn oníṣẹ́ Jefta lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli jáde ti Ejibiti wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Arnoni dé Jabbok, àní dé Jordani, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”
アンモンの人々の王はエフタの使者に答えた、「昔、イスラエルがエジプトから上ってきたとき、アルノンからヤボクに及び、またヨルダンに及ぶわたしの国を奪い取ったからです。それゆえ今、穏やかにそれを返しなさい」。
14 Jefta sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ammoni
エフタはまた使者をアンモンの人々の王につかわして、
15 ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Jefta wí: àwọn ọmọ Israẹli kò gba ilẹ̀ Moabu tàbí ilẹ̀ àwọn ará Ammoni.
言わせた、「エフタはこう申します、『イスラエルはモアブの地も、またアンモンの人々の地も取りませんでした。
16 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ejibiti àwọn ọmọ Israẹli la aginjù kọjá lọ sí ọ̀nà Òkun Pupa wọ́n sì lọ sí Kadeṣi.
イスラエルはエジプトから上ってきたとき、荒野をとおって紅海にいたり、カデシにきました。
17 Nígbà náà Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Edomu pé, ‘Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá,’ ṣùgbọ́n ọba Edomu kò fetí sí wọn. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Moabu bákan náà òun náà kọ̀. Nítorí náà Israẹli dúró sí Kadeṣi.
そしてイスラエルは使者をエドムの王につかわして「どうぞ、われわれにあなたの国を通らせてください」と言わせましたが、エドムの王は聞きいれませんでした。また同じように人をモアブの王につかわしたが、彼も承諾しなかったので、イスラエルはカデシにとどまりました。
18 “Wọ́n rin aginjù kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Edomu àti ti Moabu sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà-oòrùn Moabu, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Arnoni. Wọn kò wọ ilẹ̀ Moabu, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Arnoni wà.
それから荒野をとおって、エドムの地とモアブの地を回り、モアブの地の東部に達し、アルノンの向こうに宿営しましたがモアブの領域には、はいりませんでした。アルノンはモアブの境だからです。
19 “Nígbà náà ni Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Heṣboni, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí ibùgbé wa.’
次にイスラエルはヘシボンの王すなわちアモリびとの王シホンに使者をつかわし、シホンに向かって「どうぞ、われわれにあなたの国をとおって、われわれの目的地へ行かせてください」と言わせました。
20 Ṣùgbọ́n Sihoni kò gba Israẹli gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jahisa láti bá Israẹli jagun.
ところがシホンはイスラエルを信ぜず、その領域を通らせないばかりか、かえってすべての民を集めてヤハヅに陣を取り、イスラエルと戦いましたが、
21 “Olúwa Ọlọ́run Israẹli sì fi Sihoni àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Israẹli sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé ní agbègbè náà,
イスラエルの神、主はシホンとそのすべての民をイスラエルの手にわたされたので、イスラエルは彼らを撃ち破って、その土地に住んでいたアモリびとの地をことごとく占領し、
22 wọ́n gbà gbogbo agbègbè àwọn ará Amori, láti Arnoni tí ó fi dé Jabbok, àti láti aginjù dé Jordani.
アルノンからヤボクまでと、荒野からヨルダンまで、アモリびとの領域をことごとく占領しました。
23 “Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti lé àwọn ará Amori kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Israẹli, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà?
このようにイスラエルの神、主はその民イスラエルの前からアモリびとを追い払われたのに、あなたはそれを取ろうとするのですか。
24 Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kemoṣi òrìṣà rẹ fi fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa.
あなたは、あなたの神ケモシがあなたに取らせるものを取らないのですか。われわれはわれわれの神、主がわれわれの前から追い払われたものの土地を取るのです。
25 Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú Israẹli bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí?
あなたはモアブの王チッポルの子バラクにまさる者ですか。バラクはかつてイスラエルと争ったことがありますか。かつて彼らと戦ったことがありますか。
26 Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?
イスラエルはヘシボンとその村里に住み、またアロエルとその村里およびアルノンの岸に沿うすべての町々に住むこと三百年になりますが、あなたがたはどうしてその間にそれを取りもどさなかったのですか。
27 Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàrín àwọn ọmọ Israẹli àti àwọn ará Ammoni.”
わたしはあなたに何も悪い事をしたこともないのに、あなたはわたしと戦って、わたしに害を加えようとします。審判者であられる主よ、どうぞ、きょう、イスラエルの人々とアンモンの人々との間をおさばきください』」。
28 Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ammoni kò fetí sí iṣẹ́ tí Jefta rán sí i.
しかしアンモンの人々の王はエフタが言いつかわした言葉をききいれなかった。
29 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jefta òun sì la Gileadi àti Manase kọjá. Ó la Mispa àti Gileadi kọjá láti ibẹ̀, ó tẹ̀síwájú láti bá àwọn ará Ammoni jà.
時に主の霊がエフタに臨み、エフタはギレアデおよびマナセをとおって、ギレアデのミヅパに行き、ギレアデのミヅパから進んでアンモンの人々のところに行った。
30 Jefta sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ammoni lé mi lọ́wọ́,
エフタは主に誓願を立てて言った、「もしあなたがアンモンの人々をわたしの手にわたされるならば、
31 yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ó bá jáde láti ẹnu-ọ̀nà ilé mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ammoni ní àlàáfíà, yóò jẹ́ ti Olúwa, èmi yóò sì fi rú ẹbọ bí ọrẹ ẹbọ sísun.”
わたしがアンモンの人々に勝って帰るときに、わたしの家の戸口から出てきて、わたしを迎えるものはだれでも主のものとし、その者を燔祭としてささげましょう」。
32 Jefta sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ammoni jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́.
エフタはアンモンの人々のところに進んで行って、彼らと戦ったが、主は彼らをエフタの手にわたされたので、
33 Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní à pa tán láti Aroeri títí dé agbègbè Minniti, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Keramimu. Báyìí ni Israẹli ti ṣẹ́gun àwọn ará Ammoni.
アロエルからミンニテの附近まで、二十の町を撃ち敗り、アベル・ケラミムに至るまで、非常に多くの人を殺した。こうしてアンモンの人々はイスラエルの人々の前に攻め伏せられた。
34 Nígbà tí Jefta padà sí ilé rẹ̀ ní Mispa, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú timbrili àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan.
やがてエフタはミヅパに帰り、自分の家に来ると、彼の娘が鼓をもち、舞い踊って彼を出迎えた。彼女はエフタのひとり子で、ほかに男子も女子もなかった。
35 Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí Olúwa ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le sẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.”
エフタは彼女を見ると、衣を裂いて言った、「ああ、娘よ、あなたは全くわたしを打ちのめした。わたしを悩ますものとなった。わたしが主に誓ったのだから改めることはできないのだ」。
36 Ọmọ náà sì dáhùn pé, “Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí Olúwa ti gba ẹ̀san fún ọ lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ará Ammoni.
娘は言った、「父よ、あなたは主に誓われたのですから、主があなたのために、あなたの敵アンモンの人々に報復された今、あなたが言われたとおりにわたしにしてください」。
37 Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láààyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n sọkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúńdíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.”
娘はまた父に言った、「どうぞ、この事をわたしにさせてください。すなわち二か月の間わたしをゆるし、友だちと一緒に行って、山々をゆきめぐり、わたしの処女であることを嘆かせてください」。
38 Jefta dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láààyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yòókù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n sọkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó.
エフタは「行きなさい」と言って、彼女を二か月の間、出してやった。彼女は友だちと一緒に行って、山の上で自分の処女であることを嘆いたが、
39 Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúńdíá tí kò mọ ọkùnrin rí. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Israẹli
二か月の後、父のもとに帰ってきたので、父は誓った誓願のとおりに彼女におこなった。彼女はついに男を知らなかった。
40 wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrín ọdún àwọn obìnrin Israẹli a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jefta ti Gileadi.
これによって年々イスラエルの娘たちは行って、年に四日ほどギレアデびとエフタの娘のために嘆くことがイスラエルのならわしとなった。

< Judges 11 >