< Joshua 6 >

1 Wàyí o, a ti há Jeriko mọ́lé gágá nítorí àwọn ọmọ Israẹli, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé.
καὶ Ιεριχω συγκεκλεισμένη καὶ ὠχυρωμένη καὶ οὐθεὶς ἐξεπορεύετο ἐξ αὐτῆς οὐδὲ εἰσεπορεύετο
2 Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo ti fi Jeriko lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀.
καὶ εἶπεν κύριος πρὸς Ἰησοῦν ἰδοὺ ἐγὼ παραδίδωμι ὑποχείριόν σου τὴν Ιεριχω καὶ τὸν βασιλέα αὐτῆς τὸν ἐν αὐτῇ δυνατοὺς ὄντας ἐν ἰσχύι
3 Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.
σὺ δὲ περίστησον αὐτῇ τοὺς μαχίμους κύκλῳ
4 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè.
5 Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.”
καὶ ἔσται ὡς ἂν σαλπίσητε τῇ σάλπιγγι ἀνακραγέτω πᾶς ὁ λαὸς ἅμα καὶ ἀνακραγόντων αὐτῶν πεσεῖται αὐτόματα τὰ τείχη τῆς πόλεως καὶ εἰσελεύσεται πᾶς ὁ λαὸς ὁρμήσας ἕκαστος κατὰ πρόσωπον εἰς τὴν πόλιν
6 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.”
καὶ εἰσῆλθεν Ἰησοῦς ὁ τοῦ Ναυη πρὸς τοὺς ἱερεῖς
7 Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa.”
καὶ εἶπεν αὐτοῖς λέγων παραγγείλατε τῷ λαῷ περιελθεῖν καὶ κυκλῶσαι τὴν πόλιν καὶ οἱ μάχιμοι παραπορευέσθωσαν ἐνωπλισμένοι ἐναντίον κυρίου
8 Nígbà tí Joṣua ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú Olúwa kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí Olúwa sì tẹ̀lé wọn.
καὶ ἑπτὰ ἱερεῖς ἔχοντες ἑπτὰ σάλπιγγας ἱερὰς παρελθέτωσαν ὡσαύτως ἐναντίον τοῦ κυρίου καὶ σημαινέτωσαν εὐτόνως καὶ ἡ κιβωτὸς τῆς διαθήκης κυρίου ἐπακολουθείτω
9 Àwọn olùṣọ tí ó hámọ́ra sì lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè, olùṣọ́ ẹ̀yìn sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Ní gbogbo àsìkò yìí fèrè sì ń dún.
οἱ δὲ μάχιμοι ἔμπροσθεν παραπορευέσθωσαν καὶ οἱ ἱερεῖς οἱ οὐραγοῦντες ὀπίσω τῆς κιβωτοῦ τῆς διαθήκης κυρίου πορευόμενοι καὶ σαλπίζοντες
10 Ṣùgbọ́n Joṣua tí pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ kígbe ogun, ẹ kò gbọdọ̀ gbé ohùn yín sókè, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ kan títí ọjọ́ tí èmi yóò sọ fún un yín pé kí ẹ hó. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì hó!”
τῷ δὲ λαῷ ἐνετείλατο Ἰησοῦς λέγων μὴ βοᾶτε μηδὲ ἀκουσάτω μηθεὶς ὑμῶν τὴν φωνήν ἕως ἂν ἡμέραν αὐτὸς διαγγείλῃ ἀναβοῆσαι καὶ τότε ἀναβοήσετε
11 Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí Olúwa yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà.
καὶ περιελθοῦσα ἡ κιβωτὸς τῆς διαθήκης τοῦ θεοῦ τὴν πόλιν εὐθέως ἀπῆλθεν εἰς τὴν παρεμβολὴν καὶ ἐκοιμήθη ἐκεῖ
12 Joṣua sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.
καὶ τῇ ἡμέρᾳ τῇ δευτέρᾳ ἀνέστη Ἰησοῦς τὸ πρωί καὶ ἦραν οἱ ἱερεῖς τὴν κιβωτὸν τῆς διαθήκης κυρίου
13 Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ.
καὶ οἱ ἑπτὰ ἱερεῖς οἱ φέροντες τὰς σάλπιγγας τὰς ἑπτὰ προεπορεύοντο ἐναντίον κυρίου καὶ μετὰ ταῦτα εἰσεπορεύοντο οἱ μάχιμοι καὶ ὁ λοιπὸς ὄχλος ὄπισθε τῆς κιβωτοῦ τῆς διαθήκης κυρίου καὶ οἱ ἱερεῖς ἐσάλπισαν ταῖς σάλπιγξι καὶ ὁ λοιπὸς ὄχλος ἅπας περιεκύκλωσε τὴν πόλιν ἐγγύθεν
14 Ní ọjọ́ kejì, wọ́n yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan wọ́n sì padà sí ibùdó. Wọ́n sì ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.
καὶ ἀπῆλθεν πάλιν εἰς τὴν παρεμβολήν οὕτως ἐποίει ἐπὶ ἓξ ἡμέρας
15 Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní àfẹ̀mọ́júmọ́, wọ́n sì wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí i ti ìṣáájú, ní ọjọ́ keje nìkan ṣoṣo ni wọ́n wọ́de ogun yí ìlú náà ká nígbà méje.
καὶ τῇ ἡμέρᾳ τῇ ἑβδόμῃ ἀνέστησαν ὄρθρου καὶ περιήλθοσαν τὴν πόλιν ἑξάκις
16 Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé Olúwa ti fún un yín ní ìlú náà.
καὶ τῇ περιόδῳ τῇ ἑβδόμῃ ἐσάλπισαν οἱ ἱερεῖς καὶ εἶπεν Ἰησοῦς τοῖς υἱοῖς Ισραηλ κεκράξατε παρέδωκεν γὰρ κύριος ὑμῖν τὴν πόλιν
17 Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún Olúwa. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́.
καὶ ἔσται ἡ πόλις ἀνάθεμα αὐτὴ καὶ πάντα ὅσα ἐστὶν ἐν αὐτῇ κυρίῳ σαβαωθ πλὴν Ρααβ τὴν πόρνην περιποιήσασθε αὐτὴν καὶ ὅσα ἐστὶν ἐν τῷ οἴκῳ αὐτῆς
18 Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ̀yin kí ó má ba à ṣojú kòkòrò nípa mímú nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ ó sọ ibùdó Israẹli di ìparun. Kí ẹ sì mú wàhálà wá sórí i rẹ̀.
ἀλλὰ ὑμεῖς φυλάξασθε σφόδρα ἀπὸ τοῦ ἀναθέματος μήποτε ἐνθυμηθέντες ὑμεῖς αὐτοὶ λάβητε ἀπὸ τοῦ ἀναθέματος καὶ ποιήσητε τὴν παρεμβολὴν τῶν υἱῶν Ισραηλ ἀνάθεμα καὶ ἐκτρίψητε ἡμᾶς
19 Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún Olúwa, wọ́n yóò wá sínú ìṣúra Olúwa.”
καὶ πᾶν ἀργύριον ἢ χρυσίον ἢ χαλκὸς ἢ σίδηρος ἅγιον ἔσται τῷ κυρίῳ εἰς θησαυρὸν κυρίου εἰσενεχθήσεται
20 Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó. Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ; bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà.
καὶ ἐσάλπισαν ταῖς σάλπιγξιν οἱ ἱερεῖς ὡς δὲ ἤκουσεν ὁ λαὸς τὴν φωνὴν τῶν σαλπίγγων ἠλάλαξεν πᾶς ὁ λαὸς ἅμα ἀλαλαγμῷ μεγάλῳ καὶ ἰσχυρῷ καὶ ἔπεσεν ἅπαν τὸ τεῖχος κύκλῳ καὶ ἀνέβη πᾶς ὁ λαὸς εἰς τὴν πόλιν
21 Wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀ fún Olúwa àti fún ìparun, wọ́n sì fi idà run gbogbo ohun alààyè ní ìlú náà—ọkùnrin àti obìnrin, ọ́mọdé, àti àgbà, màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
καὶ ἀνεθεμάτισεν αὐτὴν Ἰησοῦς καὶ ὅσα ἦν ἐν τῇ πόλει ἀπὸ ἀνδρὸς καὶ ἕως γυναικός ἀπὸ νεανίσκου καὶ ἕως πρεσβύτου καὶ ἕως μόσχου καὶ ὑποζυγίου ἐν στόματι ῥομφαίας
22 Joṣua sì sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ti wá ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà pé, “Ẹ lọ sí ilé panṣágà nì, kí ẹ sì mu jáde àti gbogbo ohun tí í ṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ tí búra fún un.”
καὶ τοῖς δυσὶν νεανίσκοις τοῖς κατασκοπεύσασιν εἶπεν Ἰησοῦς εἰσέλθατε εἰς τὴν οἰκίαν τῆς γυναικὸς καὶ ἐξαγάγετε αὐτὴν ἐκεῖθεν καὶ ὅσα ἐστὶν αὐτῇ
23 Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Rahabu jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Israẹli.
καὶ εἰσῆλθον οἱ δύο νεανίσκοι οἱ κατασκοπεύσαντες τὴν πόλιν εἰς τὴν οἰκίαν τῆς γυναικὸς καὶ ἐξηγάγοσαν Ρααβ τὴν πόρνην καὶ τὸν πατέρα αὐτῆς καὶ τὴν μητέρα αὐτῆς καὶ τοὺς ἀδελφοὺς αὐτῆς καὶ πάντα ὅσα ἦν αὐτῇ καὶ πᾶσαν τὴν συγγένειαν αὐτῆς καὶ κατέστησαν αὐτὴν ἔξω τῆς παρεμβολῆς Ισραηλ
24 Nígbà náà ni wọ́n sun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò idẹ àti irin sínú ìṣúra ilé Olúwa.
καὶ ἡ πόλις ἐνεπρήσθη ἐμπυρισμῷ σὺν πᾶσιν τοῖς ἐν αὐτῇ πλὴν ἀργυρίου καὶ χρυσίου καὶ χαλκοῦ καὶ σιδήρου ἔδωκαν εἰς θησαυρὸν κυρίου εἰσενεχθῆναι
25 Ṣùgbọ́n Joṣua dá Rahabu panṣágà pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Joṣua rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jeriko mọ́. Ó sì ń gbé láàrín ará Israẹli títí di òní yìí.
καὶ Ρααβ τὴν πόρνην καὶ πάντα τὸν οἶκον τὸν πατρικὸν αὐτῆς ἐζώγρησεν Ἰησοῦς καὶ κατῴκησεν ἐν τῷ Ισραηλ ἕως τῆς σήμερον ἡμέρας διότι ἔκρυψεν τοὺς κατασκοπεύσαντας οὓς ἀπέστειλεν Ἰησοῦς κατασκοπεῦσαι τὴν Ιεριχω
26 Ní àkókò náà Joṣua sì búra pé, “Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jeriko kọ́: “Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni yóò fi pilẹ̀ rẹ̀; ikú àbíkẹ́yìn rẹ̀ ní yóò fi gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.”
καὶ ὥρκισεν Ἰησοῦς ἐν τῇ ἡμέρᾳ ἐκείνῃ ἐναντίον κυρίου λέγων ἐπικατάρατος ὁ ἄνθρωπος ὃς οἰκοδομήσει τὴν πόλιν ἐκείνην ἐν τῷ πρωτοτόκῳ αὐτοῦ θεμελιώσει αὐτὴν καὶ ἐν τῷ ἐλαχίστῳ αὐτοῦ ἐπιστήσει τὰς πύλας αὐτῆς καὶ οὕτως ἐποίησεν Οζαν ὁ ἐκ Βαιθηλ ἐν τῷ Αβιρων τῷ πρωτοτόκῳ ἐθεμελίωσεν αὐτὴν καὶ ἐν τῷ ἐλαχίστῳ διασωθέντι ἐπέστησεν τὰς πύλας αὐτῆς
27 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Joṣua; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.
καὶ ἦν κύριος μετὰ Ἰησοῦ καὶ ἦν τὸ ὄνομα αὐτοῦ κατὰ πᾶσαν τὴν γῆν

< Joshua 6 >