< Joshua 4 >

1 Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jordani tan, Olúwa sọ fún Joṣua pé,
When the whole nation had finished crossing the Jordan, the LORD said to Joshua,
2 “Yan ọkùnrin méjìlá nínú àwọn ènìyàn, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,
“Choose twelve men from among the people, one from each tribe,
3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé, ‘Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.’”
and command them: ‘Take up for yourselves twelve stones from the middle of the Jordan where the priests were standing, carry them with you, and set them down in the place where you spend the night.’”
4 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pe àwọn ọkùnrin méjìlá tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,
So Joshua summoned the twelve men he had appointed from the Israelites, one from each tribe,
5 ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli,
and said to them, “Cross over before the ark of the LORD your God into the middle of the Jordan. Each of you is to take a stone upon his shoulder, according to the number of the tribes of Israel,
6 kí ó sì jẹ́ àmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’
to serve as a sign among you. In the future, when your children ask, ‘What do these stones mean to you?’
7 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.”
you are to tell them, ‘The waters of the Jordan were cut off before the ark of the covenant of the LORD. When it crossed the Jordan, the waters were cut off.’ Therefore these stones will be a memorial to the Israelites forever.”
8 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí Joṣua ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, bí Olúwa ti sọ fún Joṣua; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀.
Thus the Israelites did as Joshua had commanded them. They took up twelve stones from the middle of the Jordan, one for each tribe of Israel, just as the LORD had told Joshua; and they carried them to the camp, where they set them down.
9 Joṣua sì to òkúta méjìlá náà sí àárín odò Jordani fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí.
Joshua also set up twelve stones in the middle of the Jordan, in the place where the priests who carried the ark of the covenant stood. And the stones are there to this day.
10 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárín Jordani títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pàṣẹ fún Joṣua fi di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún Joṣua. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,
Now the priests who carried the ark remained standing in the middle of the Jordan until the people had completed everything the LORD had commanded Joshua to tell them, just as Moses had directed Joshua. The people hurried across,
11 bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdìkejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n.
and after everyone had finished crossing, the priests with the ark of the LORD crossed in the sight of the people.
12 Àwọn ọkùnrin Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn.
The Reubenites, the Gadites, and the half-tribe of Manasseh crossed over before the Israelites, armed for battle as Moses had instructed them.
13 Àwọn bí ọ̀kẹ́ méjì tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko láti jagun.
About 40,000 troops armed for battle crossed over before the LORD into the plains of Jericho.
14 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose.
On that day the LORD exalted Joshua in the sight of all Israel, and they revered him all the days of his life, just as they had revered Moses.
15 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé,
Then the LORD said to Joshua,
16 “Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tí o ń ru àpótí ẹ̀rí, kí wọn kí ó jáde kúrò nínú odò Jordani.”
“Command the priests who carry the ark of the Testimony to come up from the Jordan.”
17 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ jáde kúrò nínú odò Jordani.”
So Joshua commanded the priests, “Come up from the Jordan.”
18 Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jordani náà padà sí ààyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìnwá.
When the priests carrying the ark of the covenant of the LORD came up out of the Jordan and their feet touched the dry land, the waters of the Jordan returned to their course and overflowed all the banks as before.
19 Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko.
On the tenth day of the first month the people went up from the Jordan and camped at Gilgal on the eastern border of Jericho.
20 Joṣua sì to àwọn òkúta méjìlá tí wọ́n mú jáde ní Jordani jọ ní Gilgali.
And there at Gilgal Joshua set up the twelve stones they had taken from the Jordan.
21 Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’
Then Joshua said to the Israelites, “In the future, when your children ask their fathers, ‘What is the meaning of these stones?’
22 Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Israẹli rékọjá odò Jordani ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’
you are to tell them, ‘Israel crossed the Jordan on dry ground.’
23 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá.
For the LORD your God dried up the waters of the Jordan before you until you had crossed over, just as He did to the Red Sea, which He dried up before us until we had crossed over.
24 Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”
He did this so that all the peoples of the earth may know that the hand of the LORD is mighty, and so that you may always fear the LORD your God.”

< Joshua 4 >