< Joshua 24 >
1 Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.
Then Joshua assembled all the tribes of Israel at Shechem. He summoned the elders, leaders, judges, and officers of Israel, and they presented themselves before God.
2 Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí, ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà.
And Joshua said to all the people, “This is what the LORD, the God of Israel, says: ‘Long ago your fathers, including Terah the father of Abraham and Nahor, lived beyond the Euphrates and worshiped other gods.
3 Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki,
But I took your father Abraham from beyond the Euphrates and led him through all the land of Canaan, and I multiplied his descendants. I gave him Isaac,
4 àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.
and to Isaac I gave Jacob and Esau. I gave Esau Mount Seir to possess, but Jacob and his sons went down to Egypt.
5 “‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.
Then I sent Moses and Aaron, and I afflicted the Egyptians by what I did there, and afterward I brought you out.
6 Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa.
When I brought your fathers out of Egypt and you reached the Red Sea, the Egyptians pursued them with chariots and horsemen as far as the Red Sea.
7 Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárín yín àti àwọn ará Ejibiti, ó sì mú òkun wá sí orí wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ejibiti. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní aginjù fún ọjọ́ pípẹ́.
So your fathers cried out to the LORD, and He put darkness between you and the Egyptians, over whom He brought the sea and engulfed them. Your very eyes saw what I did to the Egyptians. Then you lived in the wilderness for a long time.
8 “‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jordani. Wọ́n bá yín jà, ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò níwájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn.
Later, I brought you to the land of the Amorites who lived beyond the Jordan. They fought against you, but I delivered them into your hand, that you should possess their land when I destroyed them before you.
9 Nígbà tí Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, múra láti bá Israẹli jà, ó ránṣẹ́ sí Balaamu ọmọ Beori láti fi yín bú.
Then Balak son of Zippor, the king of Moab, set out to fight against Israel. He sent for Balaam son of Beor to curse you,
10 Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Balaamu, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín síwájú àti síwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
but I would not listen to Balaam. So he blessed you again and again, and I delivered you from his hand.
11 “‘Lẹ́yìn náà ni ẹ rékọjá Jordani, tí ẹ sì wá sí Jeriko. Àwọn ará ìlú Jeriko sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Amori, Peresi, Kenaani, Hiti, Girgaṣi, Hifi àti Jebusi. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.
After this, you crossed the Jordan and came to Jericho. The people of Jericho fought against you, as did the Amorites, Perizzites, Canaanites, Hittites, Girgashites, Hivites, and Jebusites, and I delivered them into your hand.
12 Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọba Amori méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín.
I sent the hornet ahead of you, and it drove out the two Amorite kings before you, but not by your own sword or bow.
13 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà olifi tí ẹ kò gbìn.’
So I gave you a land on which you did not toil and cities that you did not build, and now you live in them and eat from vineyards and olive groves that you did not plant.’
14 “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa.
Now, therefore, fear the LORD and serve Him in sincerity and truth; cast aside the gods your fathers served beyond the Euphrates and in Egypt, and serve the LORD.
15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa, nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate, tàbí òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”
But if it is unpleasing in your sight to serve the LORD, then choose for yourselves this day whom you will serve, whether the gods your fathers served beyond the Euphrates, or the gods of the Amorites in whose land you are living. As for me and my house, we will serve the LORD!”
16 Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà!
The people replied, “Far be it from us to forsake the LORD to serve other gods!
17 Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Ejibiti, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí a là kọjá.
For the LORD our God brought us and our fathers out of the land of Egypt, out of the house of slavery, and performed these great signs before our eyes. He also protected us throughout our journey and among all the nations through which we traveled.
18 Olúwa sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Amori, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Àwa náà yóò máa sin Olúwa, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”
And the LORD drove out before us all the nations, including the Amorites who lived in the land. We too will serve the LORD, because He is our God!”
19 Joṣua sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.
But Joshua said to the people, “You are not able to serve the LORD, for He is a holy God; He is a jealous God; He will not forgive your rebellion or your sins.
20 Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”
If you forsake the LORD and serve foreign gods, He will turn and bring disaster on you and consume you, even after He has been good to you.”
21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Joṣua pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”
“No!” replied the people. “We will serve the LORD!”
22 Lẹ́yìn náà ni Joṣua wí pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa.” Wọ́n dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí.”
Then Joshua told them, “You are witnesses against yourselves that you have chosen to serve the LORD.” “We are witnesses!” they said.
23 Nígbà náà ni Joṣua dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárín yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.”
“Now, therefore,” he said, “get rid of the foreign gods among you and incline your hearts to the LORD, the God of Israel.”
24 Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Joṣua pé, “Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí.”
So the people said to Joshua, “We will serve the LORD our God and obey His voice.”
25 Ní ọjọ́ náà Joṣua dá májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Ṣekemu.
On that day Joshua made a covenant for the people, and there at Shechem he established for them a statute and ordinance.
26 Joṣua sì kọ gbogbo ìdáhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi óákù ní ẹ̀bá ibi mímọ́ Olúwa.
Joshua recorded these things in the Book of the Law of God. Then he took a large stone and set it up there under the oak that was near the sanctuary of the LORD.
27 “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run yín.”
And Joshua said to all the people, “You see this stone. It will be a witness against us, for it has heard all the words the LORD has spoken to us, and it will be a witness against you if you ever deny your God.”
28 Lẹ́yìn náà ni Joṣua jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
Then Joshua sent the people away, each to his own inheritance.
29 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Joṣua ọmọ Nuni ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún.
Some time later, Joshua son of Nun, the servant of the LORD, died at the age of 110.
30 Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi.
And they buried him in the land of his inheritance, at Timnath-serah in the hill country of Ephraim, north of Mount Gaash.
31 Israẹli sì sin Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli.
Israel had served the LORD throughout the days of Joshua and of the elders who outlived him and who had experienced all the works that the LORD had done for Israel.
32 Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́rùn-ún fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu.
And the bones of Joseph, which the Israelites had brought up out of Egypt, were buried at Shechem in the plot of land that Jacob had purchased from the sons of Hamor, Shechem’s father, for a hundred pieces of silver. So it became an inheritance for Joseph’s descendants.
33 Eleasari ọmọ Aaroni sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gibeah, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Finehasi ní òkè ilẹ̀ Efraimu.
Eleazar son of Aaron also died, and they buried him at Gibeah, which had been given to his son Phinehas in the hill country of Ephraim.