< Joshua 23 >

1 Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, nígbà tí Olúwa sì ti fún Israẹli ní ìsinmi kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká, nígbà náà Joṣua sì ti di arúgbó.
Después de muchos días, cuando Yavé dio reposo a Israel de todos sus enemigos alrededor, y Josué era anciano y bien entrado en años,
2 Ó sì pe gbogbo Israẹli jọ: àgbàgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó.
aconteció que Josué convocó a todo Israel, sus ancianos y sus jefes, sus jueces y sus oficiales, y les dijo: Yo envejecí y estoy entrado en años.
3 Ẹ̀yin tìkára yín sì ti rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí nítorí yín, Olúwa Ọlọ́run yín ni ó jà fún yín.
Ustedes vieron todo lo que Yavé su ʼElohim, hizo a todas estas naciones por causa de ustedes, pues Yavé su ʼElohim guerreó por ustedes.
4 Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó kù; àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti ṣẹ́gun ní àárín Jordani àti Òkun Ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.
Ciertamente les repartí por suertes esas naciones que aún quedan, en herencia para sus tribus, desde el Jordán, y todos los pueblos que destruí hasta el mar Grande, donde se oculta el sol.
5 Olúwa Ọlọ́run yín fúnra rẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀ ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín.
Yavé su ʼElohim, las echará de delante de ustedes, y las desposeerá delante de su presencia. Ustedes poseerán sus tierras, como les habló Yavé su ʼElohim.
6 “Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì ṣọ́ra láti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun tí a kọ sí inú ìwé òfin Mose, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.
Por tanto, esfuércense mucho en guardar y hacer todo lo que está escrito en el Rollo de la Ley de Moisés para que no se aparten de él ni a la derecha ni a la izquierda.
7 Ẹ má ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ́kù láàrín yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn.
No se mezclen con estas naciones que quedaron con ustedes. No mencionen el nombre de sus ʼelohim, ni juren por ellos, ni les sirvan, ni se postren ante ellos.
8 Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.
Se aferrarán a Yavé su ʼElohim, como hicieron hasta hoy,
9 “Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojúkọ yín.
porque Yavé echó de delante de ustedes a naciones grandes y fuertes, y nadie les pudo hacer frente hasta hoy.
10 Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀tá, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.
Un varón de ustedes persigue a 1.000, porque Yavé su ʼElohim, pelea por ustedes, como Él dijo.
11 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín.
Por tanto, cuídense con diligencia de amar a Yavé su ʼElohim.
12 “Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù láàrín yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀.
Porque si de cualquier manera se apartan y se apegan al resto de estas naciones que quedó entre ustedes, y si contraen con ellas matrimonio, y se mezclan con ellas, y ellas con ustedes,
13 Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín.
sepan con certeza que Yavé su ʼElohim no volverá más a desposeer a estas naciones de delante de ustedes. Les serán como lazo y trampa, como azotes en sus costados y espinas en sus ojos, hasta que perezcan en esta buena tierra que Yavé su ʼElohim les dio.
14 “Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà.
Mira, hoy yo voy por el camino de toda la tierra. Reconozcan, pues, con todo su corazón y toda su alma, que no cayó ni una palabra de todas las buenas cosas que Yavé su ʼElohim habló acerca de ustedes. Todas ellas les fueron cumplidas sin caer una de ellas.
15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.
Pero sucederá que tal como se cumplió en ustedes toda palabra buena que Yavé su ʼElohim les habló, así también Yavé traerá sobre ustedes toda palabra mala, hasta que los destruya de sobre esta buena tierra que Yavé su ʼElohim les dio.
16 Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.”
Si traspasan el Pacto que Yavé su ʼElohim les ordenó, sirven a otros ʼelohim y se postran ante ellos, entonces la ira de Yavé arderá contra ustedes, y pronto perecerán de sobre esta buena tierra que les dio.

< Joshua 23 >