< Joshua 19 >

1 Kèké kejì jáde fún ẹ̀yà Simeoni, ní agbo ilé, ní agbo ilé. Ìní wọn sì wà ní àárín ilẹ̀ Juda.
次にシメオンのため即ちシメオン子孫の支派のためにその宗族にしたがひて籤を掣りその產業ばユダの子孫の產業の中にあり
2 Lára ìpín wọn ní: Beerṣeba (tàbí Ṣeba), Molada,
その有る產業はベエルシバ即ちシバ、モラダ
3 Hasari-Ṣuali, Bala, Esemu,
ハザルシユアル、バラ、エゼム
4 Eltoladi, Betuli, Horma,
エルトラデ、ベトル、ホルマ
5 Siklagi, Beti-Markaboti, Hasari Susa,
チクラグ、ベテマルカボテ、ハザルスサ
6 Beti-Lebaoti àti Ṣarueli, ìlú wọn jẹ́ mẹ́tàlá àti ìletò wọn.
ベテレバオテ、シヤルヘンの十三邑並びに之につける村々
7 Aini, Rimoni, Eteri àti Aṣani, ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn,
およびアイン、リンモン、エテル、アシヤンの四邑ならびに之につける村々
8 àti gbogbo àwọn agbègbè ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Beeri (Rama ní gúúsù). Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Simeoni, agbo ilé, ní agbo ilé.
および此邑々の周圍にありてバアラテベエルすなはち南のラマまでに至るところの一切の村々等なりシメオンの子孫の支派がその宗族にしたがひて獲たる產業は是のごとし
9 A mú ogún ìní àwọn ọmọ Simeoni láti ìpín Juda, nítorí ìpín Juda pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Báyìí ni àwọn ọmọ Simeoni gba ìní wọn ní àárín ilẹ̀ Juda.
シメオンの子孫の產業はユダの子孫の分の中より出づ是ユダの子孫の分自分のためには多かりしに因てシメオンの子孫のおのれの產業を彼らの產業の中に獲たるなり
10 Kèké kẹta jáde fún Sebuluni, ní agbo ilé ní agbo ilé ààlà ìní wọn sì lọ títí dé Saridi.
第三にゼブルンの子孫のために其宗族にしたがひて籤を掣り其產業の境界はサリデに及び
11 Ó sì lọ sí ìwọ̀-oòrùn ní Marala, ó sì dé Dabbeṣeti, ó sì lọ títí dé odo ní ẹ̀bá Jokneamu.
また西に上りてマララに至りダバセテに達しヨグネアムの前なる河に達し
12 Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Saridi sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tabori, ó sì lọ sí Daberati, ó sì gòkè lọ sí Jafia.
サリデよりして東の方日のいづる方にまがりてキスロテタボルの境界にいたりタベラに出でヤピアに上り
13 Nígbà náà ní o lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Gati-Heferi àti Eti-Kaṣini, ó sì jáde ní Rimoni, ó sì yí sí ìhà Nea.
彼處より東の方ガテヘペルにわたりてイツタカジンにいたりネアまで廣がるところのリンモンに至りて盡き
14 Ní ibẹ̀, ààlà sì yíká ní ìhà àríwá lọ sí Hnatoni ó sì pín ní àfonífojì Ifita-Eli.
また北にまはりてハンナトンにいたりイフタエルの谷にいたりて盡く
15 Lára wọn ni Katati, Nahalali, Ṣimroni, Idala àti Bẹtilẹhẹmu. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlá àti ìletò wọn.
カツタテ、ナハラル、シムロン、イダラ、ベテレヘムなどの十二邑ならびに之につける村々あり
16 Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní Sebuluni, ní agbo ilé agbo ilé.
ゼブルンの子孫がその宗族にしたがひて獲たる產業およびその邑と村とは是のごとし
17 Kèké kẹrin jáde fún Isakari, agbo ilé ní agbo ilé.
第四にイツサカルすなはちイツサカルの子孫のためにその宗族にしたがひて籤を掣り
18 Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Jesreeli, Kesuloti, Ṣunemu,
その境界の包括る處はヱズレル、ケスロテ、シユネム
19 Hafraimu, Ṣihoni, Anaharati,
ハパライム、シオン、アナハラテ
20 Rabiti, Kiṣioni, Ebesi,
ラビテ、キシン、エベツ
21 Remeti, Eni-Gannimu, Eni-Hada àti Beti-Pasesi.
レメテ、エンガンニム、エンハダ、ベテパツゼズなどなり
22 Ààlà náà sì dé Tabori, Ṣahasuma, àti Beti-Ṣemeṣi, ó sì pin ní Jordani. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún àti ìletò wọn.
その境界タボル、シヤハヂマおよびベテシメシに達しその境界ヨルダンにいたりて盡く其邑あはせて十六また之につける村々あり
23 Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Isakari, ní agbo ilé agbo ilé.
イツサカルの子孫の支派が其宗族にしたがひて獲たる產業および其邑々村々は是の如し
24 Kèké karùn-ún jáde fún ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé.
第五にアセルの子孫の支派のために其宗族にしたがひて籤を掣り
25 Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Helikati, Hali, Beteni, Akṣafu,
其境界の内はヘルカテ、ハリ、ベテン、アクサフ
26 Allameleki, Amadi, àti Miṣali. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Karmeli àti Ṣihori-Libinati.
アランメレク、アマデ、ミシヤルなり其境界西の方カルメルに達しまたシホルリブナテに達し
27 Nígbà náà ni o yí sí ìhà ìlà-oòrùn Beti-Dagoni, dé Sebuluni àti àfonífojì Ifita-Eli, ó sì lọ sí àríwá sí Beti-Emeki àti Neieli, ó sì kọjá lọ sí Kabulu ní apá òsì.
日の出る方に折てベテダゴンにいたりゼブルンに達し北の方イフタヱルの谷のベテエメク及びネイエルに達し左してカブルに出で
28 Ó sì lọ sí Abdoni, Rehobu, Hammoni àti Kana títí dé Sidoni ńlá.
エプロン、レホブ、ハンモン、カナにわたりて大シドンにまでいたり
29 Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rama, ó sì lọ sí ìlú olódi Tire, ó sì yà sí Hosa, ó sì jáde ní Òkun Ńlá ní ilẹ̀ Aksibu,
ラマに旋りツロの城に及びまたホサに旋りアクジブの邊にて海にいたりて盡く
30 Uma, Afeki àti Rehobu. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn.
またウンマ、アベクおよびレホブありその邑あはせて二十二また之につける村々あり
31 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Aṣeri, ní agbo ilé agbo ilé.
アセルの子孫の支派がその宗族にしたがひて獲たる產業およびその邑々村々は是のごとし
32 Ìpín kẹfà jáde fún Naftali, agbo ilé ní agbo ilé,
第六にナフタリの子孫のためにナフタリの子孫の宗族にしたがひて籤を掣り
33 ààlà wọn lọ láti Helefi àti igi ńlá ní Saananimu nímù; kọjá lọ sí Adami Nekebu àti Jabneeli dé Lakkumu, ó sì pín ní Jordani.
その境界はヘレフより即ちザアナイムの樫の樹より起りアダミネケブおよびヤブニエルを經てラクムにいたりヨルダンにいたりて盡く
34 Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Asnoti-Tabori ó sì jáde ní Hukoki. Ó sì dé Sebuluni, ní ìhà gúúsù Aṣeri ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Juda ní Jordani ní ìhà ìlà-oòrùn.
而して其境界西に旋りてアズノテタボルにいたり彼處よりホツコクに出で南はゼブルンに達し西はアセルに達し日の出る方はヨルダンの邊にてユダに達す
35 Àwọn ìlú olódi sì Siddimu, Seri, Hamati, Rakàti, Kinnereti,
その堅固たる邑々はヂデム、ゼル、ハンマテ、ラツカテ、キンネレテ
36 Adama, Rama Hasori,
アダマ、ラマ、ハゾル
37 Kedeṣi, Edrei, Eni-Aṣọri,
ケデシ、エデレイ、エンハゾル
38 Ironi, Migdali-Eli, Horemu, Beti-Anati àti Beti-Ṣemeṣi. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún àti ìletò wọn.
イロン、ミグダルエル、ホレム、ベテアナテ、ベテシメシなど合せて十九邑亦これにつける村々あり
39 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Naftali, ní agbo ilé sí agbo ilé.
ナフタリの子孫の支派がその宗族にしたがひて獲たる產業およびその邑々村々は是のごとし
40 Ìbò kéje jáde fún ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé ní agbo ilé.
第七にダンの子孫の支派のためにその宗族にしたがひて籤を掣り
41 Ilẹ̀ ìní wọn nìwọ̀nyí: Sora, Eṣtaoli, Iri-Ṣemesi,
その產業の境界の内はゾラ、エシタオル、イルシメシ
42 Ṣaalabini, Aijaloni, Itila,
シヤラビム、アヤロン、イテラ
43 Eloni, Timna, Ekroni,
エロン、テムナ、エクロン
44 Elteke, Gibetoni, Baalati,
エルテケ、ギベトン、バアラテ
45 Jehudu, Bene-Beraki, Gati-Rimoni,
ヱホデ、ベネベラク、ガテリンモン
46 Me Jakoni àti Rakkoni, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Joppa.
メヤルコン、ラツコン、ヨツパと相對ふ地などなり
47 (Ṣùgbọ́n àwọn ará Dani ní ìṣòro láti gba ilẹ̀ ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Leṣemu, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Leṣemu, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dani orúkọ baba ńlá wọn).
但しダンの子孫の境界は初よりは廣くなれり其はダンの子孫上りゆきてライシを攻取り刃をもちてこれを撃ほろぼし之を獲て其處に住たればなり而してその先祖ダンの名にしたがびてライシをダンと名けたり
48 Àwọn ìlú wọ́n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé agbo ilé.
ダンの子孫の支派がその宗族にしたがひて獲たる產業およびその邑々村々は是のごとし
49 Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Israẹli fún Joṣua ọmọ Nuni ní ìní ní àárín wọn,
かく境界を畫りて產業の地を與ふることを終ぬ而してイスラエルの子孫おのれの中にてヌンの子ヨシユアに產業を與へたり
50 bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n fún un ni ìlú tí ó béèrè fún, Timnati Serah ní ìlú òkè Efraimu. Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀.
すなはちヱホバの命にしたがひて彼にその求むる邑を與ふエフライムの山地なるテムナテセラ是なり彼その邑を建なほして其處に住む
51 Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Israẹli fi ìbò pín ní Ṣilo ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.
祭司エレアザル、ヌンの子ヨシユアおよびイスラエルの子孫の支派の族長等がシロにおいて集會の幕屋の門にてヱホバの前に籤をもて分與へし產業は是のごとし斯地を分つことを終たり

< Joshua 19 >