< Joshua 15 >

1 Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.
Now the allotment for the clans of the tribe of Judah extended to the border of Edom, to the Wilderness of Zin at the extreme southern boundary:
2 Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀,
Their southern border started at the bay on the southern tip of the Salt Sea,
3 ó sì gba gúúsù Akrabbimu lọ, títí dé Sini àti sí iwájú ìhà gúúsù Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hesroni lọ sí Adari, ó sì tún yípo yíká lọ sí Karka.
proceeded south of the Ascent of Akrabbim, continued on to Zin, went over to the south of Kadesh-barnea, ran past Hezron up to Addar, and curved toward Karka.
4 Ó tún kọjá lọ sí Asmoni, ó sì papọ̀ mọ́ Wadi ti Ejibiti, ó parí sí Òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúúsù.
It proceeded to Azmon, joined the Brook of Egypt, and ended at the Sea. This was their southern border.
5 Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jordani. Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jordani,
The eastern border was the Salt Sea as far as the mouth of the Jordan. The northern border started from the bay of the sea at the mouth of the Jordan,
6 ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni.
went up to Beth-hoglah, proceeded north of Beth-arabah, and went up to the Stone of Bohan son of Reuben.
7 Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli.
Then the border went up to Debir from the Valley of Achor, turning north to Gilgal, which faces the Ascent of Adummim south of the ravine. It continued along the waters of En-shemesh and came out at En-rogel.
8 Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá.
From there the border went up the Valley of Hinnom along the southern slope of the Jebusites (that is, Jerusalem) and ascended to the top of the hill that faces the Valley of Hinnom on the west, at the northern end of the Valley of Rephaim.
9 Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu).
From the hilltop the border curved to the spring of the Waters of Nephtoah, proceeded to the cities of Mount Ephron, and then bent around toward Baalah (that is, Kiriath-jearim).
10 Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna.
The border curled westward from Baalah to Mount Seir, ran along the northern slope of Mount Jearim (that is, Chesalon), went down to Beth-shemesh, and crossed to Timnah.
11 Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ekroni, ó sì yípadà lọ sí Ṣikkeroni, ó sì yípadà lọ sí òkè Baalahi, ó sì dé Jabneeli, ààlà náà sì parí sí Òkun.
Then it went out to the northern slope of Ekron, curved toward Shikkeron, proceeded to Mount Baalah, went on to Jabneel, and ended at the Sea.
12 Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun Ńlá. Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn.
And the western border was the coastline of the Great Sea. These are the boundaries around the clans of the descendants of Judah.
13 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.)
According to the LORD’s command to him, Joshua gave Caleb son of Jephunneh a portion among the sons of Judah—Kiriath-arba, that is, Hebron. (Arba was the forefather of Anak.)
14 Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta jáde láti Hebroni; Ṣeṣai, Ahimani, àti Talmai, ìran Anaki.
And Caleb drove out from there the three sons of Anak—the descendants of Sheshai, Ahiman, and Talmai, the children of Anak.
15 Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).
From there he marched against the inhabitants of Debir (formerly known as Kiriath-sepher).
16 Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.”
And Caleb said, “To the man who strikes down Kiriath-sepher and captures it, I will give my daughter Acsah in marriage.”
17 Otnieli ọmọ Kenasi, arákùnrin Kalebu, sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.
So Othniel son of Caleb’s brother Kenaz captured the city, and Caleb gave his daughter Acsah to him in marriage.
18 Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”
One day Acsah came to Othniel and urged him to ask her father for a field. When she got off her donkey, Caleb asked her, “What do you desire?”
19 Ó sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.
“Give me a blessing,” she answered. “Since you have given me land in the Negev, give me springs of water as well.” So Caleb gave her both the upper and lower springs.
20 Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn.
This is the inheritance of the clans of the tribe of Judah.
21 Ìlú ìpẹ̀kun gúúsù ti ẹ̀yà Juda ní gúúsù ní ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabṣeeli, Ederi, Jaguri,
These were the southernmost cities of the tribe of Judah in the Negev toward the border of Edom: Kabzeel, Eder, Jagur,
22 Kina, Dimona, Adada,
Kinah, Dimonah, Adadah,
23 Kedeṣi, Hasori, Itina,
Kedesh, Hazor, Ithnan,
24 Sifi, Telemu, Bealoti,
Ziph, Telem, Bealoth,
25 Hasori Hadatta, Kerioti Hesroni (tí í ṣe Hasori),
Hazor-hadattah, Kerioth-hezron (that is, Hazor),
26 Amamu, Ṣema, Molada,
Amam, Shema, Moladah,
27 Hasari Gada, Heṣmoni, Beti-Peleti,
Hazar-gaddah, Heshmon, Beth-pelet,
28 Hasari-Ṣuali, Beerṣeba, Bisiotia,
Hazar-shual, Beersheba, Biziothiah,
29 Baalahi, Limu, Esemu,
Baalah, Iim, Ezem,
30 Eltoladi, Kesili, Horma,
Eltolad, Chesil, Hormah,
31 Siklagi, Madmana, Sansanna,
Ziklag, Madmannah, Sansannah,
32 Leboati, Ṣilhimu, Aini àti Rimoni, àpapọ̀ ìlú mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti àwọn ìletò wọn.
Lebaoth, Shilhim, Ain, and Rimmon—twenty-nine cities in all, along with their villages.
33 Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹsẹ̀ òkè: Eṣtaoli, Sora, Aṣna,
These were in the foothills: Eshtaol, Zorah, Ashnah,
34 Sanoa, Eni-Gannimu, Tapua, Enamu,
Zanoah, En-gannim, Tappuah, Enam,
35 Jarmatu, Adullamu, Soko, Aseka,
Jarmuth, Adullam, Socoh, Azekah,
36 Ṣaaraimu, Adittaimu àti Gedera (tàbí Gederotaimu). Ìlú mẹ́rìnlá àti àwọn ìletò wọn.
Shaaraim, Adithaim, and Gederah (or Gederothaim)—fourteen cities, along with their villages.
37 Senani, Hadaṣa, Migdali Gadi,
Zenan, Hadashah, Migdal-gad,
38 Dileani, Mispa, Jokteeli,
Dilan, Mizpeh, Joktheel,
39 Lakiṣi, Boskati, Egloni,
Lachish, Bozkath, Eglon,
40 Kabboni, Lamasi, Kitlisi,
Cabbon, Lahmas, Chitlish,
41 Gederoti, Beti-Dagoni, Naama àti Makkeda, ìlú mẹ́rìndínlógún àti ìletò wọn.
Gederoth, Beth-dagon, Naamah, and Makkedah—sixteen cities, along with their villages.
42 Libina, Eteri, Aṣani,
Libnah, Ether, Ashan,
43 Hifita, Aṣna, Nesibu,
Iphtah, Ashnah, Nezib,
44 Keila, Aksibu àti Meraṣa: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò wọn.
Keilah, Achzib, and Mareshah—nine cities, along with their villages.
45 Ekroni, pẹ̀lú ibùgbé àti àwọn ìletò rẹ̀ tó yí i ká,
Ekron, with its towns and villages;
46 ìwọ̀-oòrùn Ekroni, gbogbo èyí tí ń bẹ nítòsí Aṣdodu, pẹ̀lú àwọn ìletò wọn,
from Ekron to the sea, all the cities near Ashdod, along with their villages;
47 Aṣdodu, agbègbè ìlú rẹ̀ àti ìletò; àti Gasa, ìlú rẹ̀ àti ìletò, títí ó fi dé odò Ejibiti àti agbègbè Òkun Ńlá.
Ashdod, with its towns and villages; Gaza, with its towns and villages, as far as the Brook of Egypt and the coastline of the Great Sea.
48 Ní ilẹ̀ òkè náà: Ṣamiri, Jattiri, Soko,
These were in the hill country: Shamir, Jattir, Socoh,
49 Dannah, Kiriati-Sannnah (tí í ṣe Debiri),
Dannah, Kiriath-sannah (that is, Debir),
50 Anabu, Eṣitemo, Animu,
Anab, Eshtemoh, Anim,
51 Goṣeni, Holoni àti Giloni, ìlú mọ́kànlá àti ìletò wọn.
Goshen, Holon, and Giloh—eleven cities, along with their villages.
52 Arabu, Duma, Eṣani,
Arab, Dumah, Eshan,
53 Janimu, Beti-Tapua, Afeka,
Janim, Beth-tappuah, Aphekah,
54 Hamuta, Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) àti Ṣiori: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò rẹ̀
Humtah, Kiriath-arba (that is, Hebron), and Zior—nine cities, along with their villages.
55 Maoni, Karmeli, Sifi, Jutta,
Maon, Carmel, Ziph, Juttah,
56 Jesreeli, Jokdeamu, Sanoa,
Jezreel, Jokdeam, Zanoah,
57 Kaini, Gibeah àti Timna: ìlú mẹ́wàá àti àwọn ìletò wọn.
Kain, Gibeah, and Timnah—ten cities, along with their villages.
58 Halhuli, Beti-Suri, Gedori,
Halhul, Beth-zur, Gedor,
59 Maarati, Beti-Anoti àti Eltekoni: ìlú mẹ́fà àti àwọn ìletò wọn.
Maarath, Beth-anoth, and Eltekon—six cities, along with their villages.
60 Kiriati-Baali (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu) àti Rabba ìlú méjì àti ìletò wọn.
Kiriath-baal (that is, Kiriath-jearim), and Rabbah—two cities, along with their villages.
61 Ní aginjù: Beti-Araba, Middini, Sekaka,
These were in the wilderness: Beth-arabah, Middin, Secacah,
62 Nibṣani, Ìlú Iyọ̀ àti En-Gedi: ìlú mẹ́fà àti ìletò wọn.
Nibshan, the City of Salt, and En-gedi—six cities, along with their villages.
63 Juda kò lè lé àwọn ọmọ Jebusi jáde, tí wọ́n ń gbé ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi sì ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn Juda títí dí òní.
But the descendants of Judah could not drive out the Jebusites living in Jerusalem. So to this day the Jebusites live there among the descendants of Judah.

< Joshua 15 >