< Joshua 12 >
1 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:
2 Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín àfonífojì náà dé odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.
3 Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.
4 Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.
5 Ó ṣe àkóso ní orí òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni.
6 Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.
7 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni sí òkè Halaki, èyí tí o lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:
8 ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi).
9 Ọba Jeriko, ọ̀kan ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli), ọ̀kan
10 ọba Jerusalẹmu, ọ̀kan ọba Hebroni, ọ̀kan
11 ọba Jarmatu, ọ̀kan ọba Lakiṣi, ọ̀kan
12 ọba Egloni, ọ̀kan ọba Geseri, ọ̀kan
13 ọba Debiri, ọ̀kan ọba Gederi, ọ̀kan
14 ọba Horma, ọ̀kan ọba Aradi, ọ̀kan
15 ọba Libina, ọ̀kan ọba Adullamu, ọ̀kan
16 ọba Makkeda, ọ̀kan ọba Beteli, ọ̀kan
17 ọba Tapua, ọ̀kan ọba Heferi, ọ̀kan
18 ọba Afeki, ọ̀kan ọba Laṣaroni, ọ̀kan
19 ọba Madoni, ọ̀kan ọba Hasori, ọ̀kan
20 ọba Ṣimroni-Meroni, ọ̀kan ọba Akṣafu, ọ̀kan
21 ọba Taanaki, ọ̀kan ọba Megido, ọ̀kan
22 ọba Kedeṣi, ọ̀kan ọba Jokneamu ni Karmeli, ọ̀kan
23 ọba Dori (ní Nafoti Dori), ọ̀kan ọba Goyimu ní Gilgali, ọ̀kan
24 ọba Tirsa, ọ̀kan. Gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.