< Joshua 10 >

1 Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn.
When Adonisedec king of Jerusalem had heard these things, to wit, that Josue had taken Hai, and had destroyed it, (for as he had done to Jericho and the king thereof, so did he to Hai, and its king, ) and that the Gabaonites were gone over to Israel, and were their confederates,
2 Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gibeoni jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Ai lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun.
He was exceedingly afraid. For Gabaon was a great city, and one of the royal cities, and greater than the town of Hai, and all its fighting men were most valiant.
3 Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe,
Therefore Adonisedec king of Jerusalem sent to Oham king of Hebron, and to Pharam king of Jerimoth, and to Japhia king of Lachis, and to Dabir king of Eglon, saying:
4 “Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.”
Come up to me, and bring help, that we may take Gabaon, because it hath gone over to Josue, and to the children of Israel.
5 Àwọn ọba Amori márààrún, ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni, kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojúkọ Gibeoni, wọ́n sì kọlù ú.
So the five kings of the Amorrhites being assembled together went up: the king of Jerusalem, the king of Hebron, the king of Jerimoth, the king of Lachis, the king of Eglon, they and their armies, and camped about Gabaon, laying siege to it.
6 Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé, “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”
But the inhabitants of the city of Gabaon which was besieged, sent to Josue, who then abode in the camp at Galgal, and said to him: Withdraw not thy hands from helping thy servants: come up quickly and save us, and bring us succour: for all the kings of the Amorrhites, who dwell in the mountains, are gathered together against us.
7 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gòkè lọ láti Gilgali pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
And Josue went up from Galgal, and all the army of the warriors with him, most valiant men.
8 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”
And the Lord said to Josue: Fear them not: for I have delivered them into thy hands: none of them shall be able to stand against thee.
9 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì.
So Josue going up from Galgal all the night, came upon them suddenly.
10 Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda.
And the Lord troubled them at the sight of Israel: and he slew them with a great slaughter in Gabaon, and pursued them by the way of the ascent to Beth-horon, and cut them off all the way to Azeca and Maceda.
11 Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Israẹli ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Beti-Horoni títí dé Aseka, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ará Israẹli fi idà pa lọ.
And when they were fleeing from the children of Israel, and were in the descent of Beth-horon, the Lord cast down upon them great stones from heaven as far as Azeca: and many more were killed with the hailstones than were slain by the swords of the children of Israel.
12 Ní ọjọ́ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Israẹli, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Aijaloni.”
Then Josue spoke to the Lord, in the day that he delivered the Amorrhite in the sight of the children of Israel, and he said before them: Move not, O sun, toward Gabaon, nor thou, O moon, toward the valley of Ajalon.
13 Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró, títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari. Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan.
And the sun and the moon stood still, till the people revenged themselves of their enemies. Is not this written in the book of the just? So the sun stood still in the midst of heaven, and hasted not to go down the space of one day.
14 Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣáájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí Olúwa gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú Olúwa jà fún Israẹli!
There was not before nor after so long a day, the Lord obeying the voice of a man, and fighting for Israel.
15 Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli padà sí ibùdó ní Gilgali.
And Josue returned with all Israel into the camp of Galgal.
16 Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda,
For the five kings were fled, and had hidden themselves in a cave of the city of Maceda.
17 nígbà tí wọ́n sọ fún Joṣua pé, a ti rí àwọn ọba márààrún, ti ó fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Makkeda,
And it was told Josue that the five kings were found hidden in a cave of the city of Maceda.
18 ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ.
And he commanded them that were with him, saying: Roll great stones to the mouth of the cave, and set careful men, to keep them shut up:
19 Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀tá yín, ẹ kọlù wọ́n láti ẹ̀yìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”
And stay you not, but pursue after the enemies, and kill all the hindermost of them as they flee, and do not suffer them whom the Lord God hath delivered into your hands to shelter themselves in their cities.
20 Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.
So the enemies being slain with a great slaughter, and almost utterly consumed, they that were able to escape from Israel, entered into fenced cities.
21 Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli.
And all the army returned to Josue in Maceda, where the camp then was, in good health and without the loss of any one: and no man durst move his tongue against the children of Israel.
22 Joṣua sì wí pe, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrún jáde wá fún mi.”
And Josue gave orders, saying: Open the mouth of the cave, and bring forth to me the five kings that lie hid therein.
23 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni.
And the ministers did as they were commanded: and they brought out to him the five kings out of the cave: the king of Jerusalem, the king of Hebron, the king of Jerimoth, the king of Lachis, the king of Eglon.
24 Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Joṣua wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn.
And when they were Drought out to him, he called all the men of Israel, and said to the chiefs of the army that were with him: Go, and set your feet on the necks of these kings. And when they had gone, and put their feet upon the necks of them lying under them,
25 Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”
He said again to them: Fear not, neither be ye dismayed, take courage and be strong: for so will the Lord do to all your enemies, against whom you fight.
26 Nígbà náà ni Joṣua kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba márààrún náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́.
And Josue struck, and slew them, and hanged them upon five gibbets, and they hung until the evening.
27 Nígbà tí oòrùn wọ̀, Joṣua pàṣẹ, wọ́n sì sọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúrò ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí.
And when the sun was down, he commanded the soldiers to take them down from the gibbets. And after they were taken down, they cast them into the cave where they had lain hid, and put great stones at the mouth thereof, which remain until this day.
28 Ní ọjọ́ náà Joṣua gba Makkeda. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátápátá, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Makkeda gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jeriko.
The same day Josue took Maceda and destroyed it, with the edge of the sword, and killed the king and all the inhabitants thereof: he left not in it the least remains. And he did to the king of Maceda, as he had done to the king of Jericho.
29 Nígbà náà ní Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Makkeda lọ sí Libina wọ́n sì kọlù ú.
And he passed from Maceda with all Israel to Lebna, and fought against it:
30 Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Joṣua fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jeriko.
And the Lord delivered it with the king thereof into the hands of Israel: and they destroyed the city with the edge of the sword, and all the inhabitants thereof. They left not in it any remains. And they did to the king of Lebna, as they had done to the king of Jericho.
31 Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo ará Israẹli, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Libina lọ sí Lakiṣi; ó sì dó tì í, ó sì kọlù ú.
From Lebna he passed unto Lachis, with all Israel: and investing it with his army, besieged it.
32 Olúwa sì fi Lakiṣi lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sì gbà á ní ọjọ́ kejì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pa gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Libina.
And the Lord delivered Lachis into the hands of Israel, and he took it the following day, and put it to the sword, and every soul that was in it, as he had done to Lebna.
33 Ní àkókò yìí, Horamu ọba Geseri gòkè láti ran Lakiṣi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Joṣua ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀.
At that time Horam king of Gazer, came up to succour Lachis: and Josue slew him with all his people, so as to leave none alive.
34 Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lakiṣi lọ sí Egloni; wọ́n sì dó tì í, wọ́n sì kọlù ú.
And he passed from Lachis to Eglon, and surrounded it,
35 Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lakiṣi.
And took it the same day: and put to the sword all the souls that were in it, according to all that he had done to Lachis.
36 Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli ṣí láti Egloni lọ sí Hebroni, wọ́n sì kọlù ú.
He went up also with all Israel from Eglon to Hebron, and fought against it:
37 Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sì ti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí ti Egloni, wọ́n run un pátápátá àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀.
Took it, and destroyed it with the edge of the sword: the king also thereof, and all the towns of that country, and all the souls that dwelt in it: he left not therein any remains: as he had done to Eglon, so did he also to Hebron, putting to the sword all that he found in it.
38 Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Debiri.
Returning from thence to Dabir,
39 Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni.
He took it and destroyed it: the king also thereof and all the towns round about he destroyed with the edge of the sword: he left not in it any remains: as he had done to Hebron and Lebna and to their kings, so did he to Dabir and to the king thereof.
40 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣẹ́gun gbogbo agbègbè náà, ìlú òkè, gúúsù, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti pàṣẹ.
So Josue conquered all the country of the hills and of the south and of the plain, and of Asedoth, with their kings: he left not any remains therein, but slew all that breathed, as the Lord the God of Israel had commanded him,
41 Joṣua sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-Barnea sí Gasa àti láti gbogbo agbègbè Goṣeni lọ sí Gibeoni.
From Cadesbarne even to Gaza. All the land of Gosen even to Gabaon,
42 Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Joṣua ṣẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ̀ẹ̀kan, nítorí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, jà fún Israẹli.
And all their kings, and their lands he took and wasted at one onset: for the Lord the God of Israel fought for him.
43 Nígbà náà ni Joṣua padà sí ibùdó ní Gilgali pẹ̀lú gbogbo Israẹli.
And he returned with all Israel to the place of the camp in Galgal.

< Joshua 10 >