< Jonah 3 >

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona wá nígbà kejì wí pé:
This message from the Lord came to Jonah the second time,
2 “Dìde lọ sí Ninefe, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.”
“Arise, go to that great city, Nineveh, and proclaim to it the message that I tell you.”
3 Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.
So Jonah started for Nineveh, as the Lord commanded. Now Nineveh was so large a city that it took three days’ journey to cross it.
4 Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.”
Jonah began by going a day’s journey into the city, and he proclaimed, “Forty days more and Nineveh will be overthrown.”
5 Àwọn ènìyàn Ninefe sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.
And the people of Nineveh believed God; and they ordered a fast and put on sackcloth, from the greatest to the least of them.
6 Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Ninefe, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú.
And when word came to the king of Nineveh, he rose from his throne, took off his robe, dressed in sackcloth, and sat in ashes.
7 Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Ninefe pé, “Kí a la Ninefe já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbàgbà rẹ̀ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, tọ́ ohunkóhun wò, má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi.
And he made this proclamation and published it in Nineveh: “By the decree of the king and his nobles: People, beast, herd, and flock must not taste anything; let them not eat nor drink water.
8 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn.
Let both people and animals put on sackcloth and let them cry earnestly to God; let them each turn from their evil ways and from the deeds of violence which they are doing.
9 Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”
Who knows? God may relent and avert his fierce anger, so that we may not die.”
10 Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn, Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.
When God saw that they turned from their evil course, he relented the evil which he said he would do to them, and did not do it.

< Jonah 3 >