< John 7 >

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili, nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa.
After this, Jesus traveled throughout Galilee. He did not want to travel in Judea, because the Jews there were trying to kill Him.
2 Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan.
However, the Jewish Feast of Tabernacles was near.
3 Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhìn-ín yìí, kí o sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fi iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé.
So Jesus’ brothers said to Him, “Leave here and go to Judea, so that Your disciples there may see the works You are doing.
4 Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.”
For no one who wants to be known publicly acts in secret. Since You are doing these things, show Yourself to the world.”
5 Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́.
For even His own brothers did not believe in Him.
6 Nítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín.
Therefore Jesus told them, “Although your time is always at hand, My time has not yet come.
7 Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú.
The world cannot hate you, but it hates Me, because I testify that its works are evil.
8 Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí, èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.”
Go up to the feast on your own. I am not going up to this feast, because My time has not yet come.”
9 Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Galili síbẹ̀.
Having said this, Jesus remained in Galilee.
10 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀.
But after His brothers had gone up to the feast, He also went—not publicly, but in secret.
11 Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”
So the Jews were looking for Him at the feast and asking, “Where is He?”
12 Ìkùnsínú púpọ̀ sì wà láàrín àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀, nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere ní í ṣe.” Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.”
Many in the crowds were whispering about Him. Some said, “He is a good man.” But others replied, “No, He deceives the people.”
13 Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.
Yet no one would speak publicly about Him for fear of the Jews.
14 Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni.
About halfway through the feast, Jesus went up to the temple courts and began to teach.
15 Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”
The Jews were amazed and asked, “How did this man attain such learning without having studied?”
16 Jesu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi.
“My teaching is not My own,” Jesus replied. “It comes from Him who sent Me.
17 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi.
If anyone desires to do His will, he will know whether My teaching is from God or whether I speak on My own.
18 Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀.
He who speaks on his own authority seeks his own glory, but He who seeks the glory of the One who sent Him is a man of truth; in Him there is no falsehood.
19 Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”
Has not Moses given you the law? Yet not one of you keeps it. Why are you trying to kill Me?”
20 Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù, ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”
“You have a demon,” the crowd replied. “Who is trying to kill You?”
21 Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ àmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín.
Jesus answered them, “I did one miracle, and you are all amazed.
22 Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi.
But because Moses gave you circumcision, you circumcise a boy on the Sabbath (not that it is from Moses, but from the patriarchs.)
23 Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi?
If a boy can be circumcised on the Sabbath so that the law of Moses will not be broken, why are you angry with Me for making the whole man well on the Sabbath?
24 Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.”
Stop judging by outward appearances, and start judging justly.”
25 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí?
Then some of the people of Jerusalem began to say, “Isn’t this the man they are trying to kill?
26 Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà?
Yet here He is, speaking publicly, and they are not saying anything to Him. Have the rulers truly recognized that this is the Christ?
27 Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá, ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”
But we know where this man is from. When the Christ comes, no one will know where He is from.”
28 Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá, èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀.
Then Jesus, still teaching in the temple courts, cried out, “You know Me, and you know where I am from. I have not come of My own accord, but He who sent Me is true. You do not know Him,
29 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”
but I know Him, because I am from Him and He sent Me.”
30 Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.
So they tried to seize Him, but no one laid a hand on Him, because His hour had not yet come.
31 Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ àmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”
Many in the crowd, however, believed in Him and said, “When the Christ comes, will He perform more signs than this man?”
32 Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.
When the Pharisees heard the crowd whispering these things about Jesus, they and the chief priests sent officers to arrest Him.
33 Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi.
So Jesus said, “I am with you only a little while longer, and then I am going to the One who sent Me.
34 Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”
You will look for Me, but you will not find Me; and where I am, you cannot come.”
35 Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí.
At this, the Jews said to one another, “Where does He intend to go that we will not find Him? Will He go where the Jews are dispersed among the Greeks, and teach the Greeks?
36 Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ‘Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi,’ àti ‘Ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà’?”
What does He mean by saying, ‘You will look for Me, but you will not find Me,’ and, ‘Where I am, you cannot come’?”
37 Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.
On the last and greatest day of the feast, Jesus stood up and called out in a loud voice, “If anyone is thirsty, let him come to Me and drink.
38 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”
Whoever believes in Me, as the Scripture has said: ‘Streams of living water will flow from within him.’”
39 Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà, nítorí a kò tí ì fi Èmí Mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.
He was speaking about the Spirit, whom those who believed in Him were later to receive. For the Spirit had not yet been given, because Jesus had not yet been glorified.
40 Nítorí náà, nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”
On hearing these words, some of the people said, “This is truly the Prophet.”
41 Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.” Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí?
Others declared, “This is the Christ.” But still others asked, “How can the Christ come from Galilee?
42 Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?”
Doesn’t the Scripture say that the Christ will come from the line of David and from Bethlehem, the village where David lived?”
43 Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀.
So there was division in the crowd because of Jesus.
44 Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.
Some of them wanted to seize Him, but no one laid a hand on Him.
45 Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”
Then the officers returned to the chief priests and Pharisees, who asked them, “Why didn’t you bring Him in?”
46 Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”
“Never has anyone spoken like this man!” the officers answered.
47 Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí?
“Have you also been deceived?” replied the Pharisees.
48 Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí?
“Have any of the rulers or Pharisees believed in Him?
49 Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”
But this crowd that does not know the law, they are under a curse.”
50 Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé,
Nicodemus, who had gone to Jesus earlier and who himself was one of them, asked,
51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”
“Does our law convict a man without first hearing from him to determine what he has done?”
52 Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”
“Aren’t you also from Galilee?” they replied. “Look into it, and you will see that no prophet comes out of Galilee.”
53 Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
Then each went to his own home.

< John 7 >