< John 16 >

1 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má ba à mú yín yapa kúrò.
These things have I spoken to you, that you may not be ensnared.
2 Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run.
They will put you out of the synagogues; indeed, the time is coming, when he that kills you, will think that he is offering service to God.
3 Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.
And these things they will do, because they know neither the Father nor me.
4 Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín.
But these things I have told you, that, when the time has come, you may remember that I told you of them. But these things I did not tell you at the beginning, because I was with you.
5 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’
And now I go to him that sent me, and no one of you asks me, Whither goest thou?
6 Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín.
But because I have spoken these things to you, sorrow has filled your heart.
7 Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ, nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.
But yet I tell you the truth: it is profitable for you that I go away. For if I go not away, the Paraclete will not come to you. But if I go away, I will send him to you.
8 Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́,
And when he has come, he will convince the world of sin, and of righteousness, and of judgment.
9 ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́;
Of sin, because they believe not on me;
10 ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí.
of righteousness, because I go to my Father, and you see me no more;
11 Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ ọmọ-aládé ayé yìí.
of judgment, because the prince of this world is judged.
12 “Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsin yìí.
I have yet many things to say to you; but you can not bear them now.
13 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo, nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ, yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín.
But when he, the Spirit of the truth, has come, he will guide you into all the truth; for he will not speak of himself; but what he hears, that will he speak, and he will show you things to come.
14 Òun ó máa yìn mí lógo, nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín.
He will glorify me; for he will take of mine, and show it to you.
15 Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni, nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín.
All things that the Father has are mine; for this reason I said, that he will take of mine, and show it to you.
16 “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi, àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”
A little while, and you will not see me; and again, a little while, and you will see me, because I go to the Father.
17 Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, ‘Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi, àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi, àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba’?”
Then some of his disciples said one to another: What is this that he says to us, A little while, and you will not see me; and again, a little while, and you will see me? and, Be cause I go to the Father?
18 Nítorí náà wọ́n wí pé, kín ni, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí.
Therefore they said: What is this that he says, The little while? We know not what he says.
19 Jesu sá à ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi, àti nígbà díẹ̀ si, ẹ̀yin ó sì rí mi?
Then Jesus knew that they wished to ask him; and he said to them: Are you inquiring of one another about this, because I said, A little while and you will not see me; and again, a little while, and you will see me?
20 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin yóò máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀: ṣùgbọ́n, ìbànújẹ́ yín yóò di ayọ̀.
Verily, verily I say to you, you shall weep and lament, but the world will rejoice. You shall be sorrowful, but your sorrow shall be turned into joy.
21 Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti bí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé.
A woman, when she is in labor, has sorrow, be cause her hour has come; but when the child is born, she no longer remembers the pain, for joy that a man is born into the world.
22 Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsin yìí, ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín.
You, therefore, have sorrow now; but I shall see you again, and your heart will rejoice, and your joy no one takes from you.
23 Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín.
And in that day you shall ask nothing of me; verily, verily I say to you, whatever you ask of the Father in my name, he will give you.
24 Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.
Till this time you have asked for nothing in my name; ask, and you shall receive, that your joy may be full.
25 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba.
These things I have spoken to you in parables; the time is coming when I will no longer speak to you in parables, but will teach you plainly concerning the Father.
26 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi, èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín.
In that day you shall ask in my name; and I say not to you, that I will ask the Father in your behalf;
27 Nítorí tí Baba tìkára rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá.
for the Father himself loves you, because you have loved me, and have believed that I came forth from God.
28 Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé, àti nísinsin yìí mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”
I came forth from the Father, and have come into the world: again I leave the world, and go to the Father.
29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe.
His disciples said to him: Lo, now thou speakest plainly, and speakest no parable.
30 Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.”
Now we know that thou knowest all things, and hast no need that any one should ask thee. By this we believe that thou hast come forth from God.
31 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí?
Jesus answered them: Do you now believe?
32 Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.
Behold, the hour is coming, and has now come, in which you shall be scattered, each one to his own home, and shall leave me alone: and yet I am not alone, for the Father is with me.
33 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”
These things I have spoken to you, that in me you may have peace. In the world you shall have affliction, but be of good courage; I have overcome the world.

< John 16 >