< John 14 >

1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú.
Let not your heart be troubled: ye believe in God, believe also in me.
2 Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà, ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín.
Many mansions are in the house of my Father; but if it were not so, I would have told you; because I go to prepare a place for you.
3 Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
And if I may go and prepare a place for you, I come again, and will receive you unto myself; in order that you may also be where I am.
4 Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.”
And whither I go, you know the way.
5 Tomasi wí fún un pé, “Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà?”
And Thomas says to Him, Lord, we know not whither thou goest: and how do we know the way?
6 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.
Jesus says to him, I am the way, and the truth, and the life: no one cometh to the Father, but through me.
7 Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú, láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”
If you have known me, you shall also know my Father: and henceforth you know Him and have seen Him.
8 Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”
Philip says to Him, Lord, show us the Father, and it sufficeth us.
9 Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba. Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’
Jesus says to Him, Am I so long time with you, and hast thou not known me, Philip? The one having seen me hath seen the Father: how do you say, Show us the Father?
10 Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.
Dost thou not believe, that I am in the Father, and the Father is in me? The words which I speak unto you I speak not of myself: but the Father who abideth in me doeth His own works.
11 Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá!
Believe me that I am in the Father, and the Father in me; or if not, believe for the sake of the works themselves.
12 Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.
Truly, truly, I say unto you, He that believeth on me, shall also do the works which I am doing; and shall do greater works than these: because I go to the Father:
13 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ.
and whatsoever you may ask in my name, I will do it, in order that the rather may be glorified in the Son.
14 Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.
If you may ask anything of me in my name, I will do it.
15 “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́.
If you love me, keep my commandments.
16 Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé. (aiōn g165)
And I will ask the Father, and He will give you another Comforter, that He may be with you always, (aiōn g165)
17 Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀.
the Spirit of truth: which the world is not able to receive, because it does not see Him, nor know Him: you know Him: because He abideth with you, and shall be in you.
18 Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀.
I will not leave you orphans: I am coming to you.
19 Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi, nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú.
Vet a little while, and the world sees me no more; but you see me: because I live, you shall live also.
20 Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín.
In that day you shall know that I am in the Father, you in me, and I in you.
21 Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi, ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”
The one having my commandments, and keeping them, he is the one loving me with divine love: the one loving me with divine love, shall be loved by my Father, and I will love him and will manifest myself unto him.
22 Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?”
Judas. (not Iscariot), says to Him, Lord, and how is it that you are about to manifest yourself to us, and not to the world?
23 Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀.
Jesus responded and said to him; If any one may love me with divine love, he will keep my word: and my Father will love him, and we will come to him, and will make our mansion with him.
24 Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.
The one not loving me with divine love does not keep my words: and the word which you hear is not mine, but that of the Father who sent me.
25 “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé.
I have spoken these things to you, abiding with you:
26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.
but the Comforter, the Holy Spirit, whom the Father will send in my name, He will teach you all things, and remind you of all things, which I spoke to you.
27 Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.
My peace I leave with you; my peace I give unto you: not as the world gives, give I unto you. Let not your heart be troubled, nor afraid.
28 “Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ.
You heard that I said to you, I go away, and I come to you. If you love me with divine love, you would rejoice, because I go to my Father: because the Father is greater than I.
29 Èmi sì ti sọ fún yín nísinsin yìí kí ó tó ṣẹ, pé nígbà tí ó bá ṣẹ, kí ẹ lè gbàgbọ́.
And I have now told you before it takes place, in order that, when it may come to pass, you may believe.
30 Èmi kì yóò bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀, nítorí ọmọ-aládé ayé yí wá, kò sì ní nǹkan kan lòdì sí mi.
I shall no longer speak many things with you, because the prince of the world comes: and he has nothing in me;
31 Ṣùgbọ́n nítorí kí ayé lè mọ̀ pé èmi fẹ́ràn Baba; gẹ́gẹ́ bí Baba sì ti fi àṣẹ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi ń ṣe. “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ kúrò níhìn-ín yìí.
but in order that the world may know that I love the Father, and as He commanded, so I am doing. Arise, let us go hence.

< John 14 >