< John 11 >
1 Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀.
At this time a man named Lazarus was sick. He lived in Bethany, the village of Mary and her sister Martha.
2 Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá.
(Mary, whose brother Lazarus was sick, was to anoint the Lord with perfume and wipe His feet with her hair.)
3 Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”
So the sisters sent word to Jesus, “Lord, the one You love is sick.”
4 Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”
When Jesus heard this, He said, “This sickness will not end in death. No, it is for the glory of God, so that the Son of God may be glorified through it.”
5 Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru.
Now Jesus loved Martha and her sister and Lazarus.
6 Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà.
So on hearing that Lazarus was sick, He stayed where He was for two days,
7 Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”
and then He said to the disciples, “Let us go back to Judea.”
8 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”
“Rabbi,” they replied, “the Jews just tried to stone You, and You are going back there?”
9 Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.
Jesus answered, “Are there not twelve hours of daylight? If anyone walks in the daytime, he will not stumble, because he sees by the light of this world.
10 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”
But if anyone walks at night, he will stumble, because he has no light.”
11 Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ, lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”
After He had said this, He told them, “Our friend Lazarus has fallen asleep, but I am going there to wake him up.”
12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.”
His disciples replied, “Lord, if he is sleeping, he will get better.”
13 Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.
They thought that Jesus was talking about actual sleep, but He was speaking about the death of Lazarus.
14 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú.
So Jesus told them plainly, “Lazarus is dead,
15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”
and for your sake I am glad I was not there, so that you may believe. But let us go to him.”
16 Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”
Then Thomas called Didymus said to his fellow disciples, “Let us also go, so that we may die with Him.”
17 Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná,
When Jesus arrived, He found that Lazarus had already spent four days in the tomb.
18 ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.
Now Bethany was near Jerusalem, a little less than two miles away,
19 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.
and many of the Jews had come to Martha and Mary to console them in the loss of their brother.
20 Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.
So when Martha heard that Jesus was coming, she went out to meet Him; but Mary stayed at home.
21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.
Martha said to Jesus, “Lord, if You had been here, my brother would not have died.
22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”
But even now I know that God will give You whatever You ask of Him.”
23 Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”
“Your brother will rise again,” Jesus told her.
24 Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”
Martha replied, “I know that he will rise again in the resurrection at the last day.”
25 Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.
Jesus said to her, “I am the resurrection and the life. Whoever believes in Me will live, even though he dies.
26 Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?” (aiōn )
And everyone who lives and believes in Me will never die. Do you believe this?” (aiōn )
27 Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”
“Yes, Lord,” she answered, “I believe that You are the Christ, the Son of God, who was to come into the world.”
28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.”
After Martha had said this, she went back and called her sister Mary aside to tell her, “The Teacher is here and is asking for you.”
29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
And when Mary heard this, she got up quickly and went to Him.
30 Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀.
Now Jesus had not yet entered the village, but was still at the place where Martha had met Him.
31 Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Maria tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣe bí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.
When the Jews who were in the house consoling Mary saw how quickly she got up and went out, they followed her, supposing she was going to the tomb to mourn there.
32 Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”
When Mary came to Jesus and saw Him, she fell at His feet and said, “Lord, if You had been here, my brother would not have died.”
33 Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́.
When Jesus saw her weeping, and the Jews who had come with her also weeping, He was deeply moved in spirit and troubled.
34 Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.”
“Where have you put him?” He asked. “Come and see, Lord,” they answered.
36 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”
Then the Jews said, “See how He loved him!”
37 Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú bí?”
But some of them asked, “Could not this man who opened the eyes of the blind also have kept Lazarus from dying?”
38 Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.
Jesus, once again deeply moved, came to the tomb. It was a cave with a stone laid across the entrance.
39 Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí, nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”
“Take away the stone,” Jesus said. “Lord, by now he stinks,” said Martha, the sister of the dead man. “It has already been four days.”
40 Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”
Jesus replied, “Did I not tell you that if you believed, you would see the glory of God?”
41 Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.
So they took away the stone. Then Jesus lifted His eyes upward and said, “Father, I thank You that You have heard Me.
42 Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”
I knew that You always hear Me, but I say this for the benefit of the people standing here, so they may believe that You sent Me.”
43 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.”
After Jesus had said this, He called out in a loud voice, “Lazarus, come out!”
44 Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”
The man who had been dead came out with his hands and feet bound in strips of linen, and his face wrapped in a cloth. “Unwrap him and let him go,” Jesus told them.
45 Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Maria, tí wọ́n rí ohun tí Jesu ṣe, ṣe gbà á gbọ́.
Therefore many of the Jews who had come to Mary, and had seen what Jesus did, believed in Him.
46 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisi lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jesu ṣe.
But some of them went to the Pharisees and told them what Jesus had done.
47 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ. Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.
Then the chief priests and Pharisees convened the Sanhedrin and said, “What are we to do? This man is performing many signs.
48 Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.”
If we let Him go on like this, everyone will believe in Him, and then the Romans will come and take away both our place and our nation.”
49 Ṣùgbọ́n Kaiafa, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá!
But one of them, named Caiaphas, who was high priest that year, said to them, “You know nothing at all!
50 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó ṣàǹfààní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má ba à ṣègbé.”
You do not realize that it is better for you that one man die for the people than that the whole nation perish.”
51 Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà,
Caiaphas did not say this on his own. Instead, as high priest that year, he was prophesying that Jesus would die for the nation,
52 kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan.
and not only for the nation, but also for the scattered children of God, to gather them together into one.
53 Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.
So from that day on they plotted to kill Him.
54 Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
As a result, Jesus no longer went about publicly among the Jews, but He withdrew to a town called Ephraim in an area near the wilderness. And He stayed there with the disciples.
55 Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́.
Now the Jewish Passover was near, and many people went up from the country to Jerusalem to purify themselves before the Passover.
56 Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jesu, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹmpili, wí pé, “Kín ni ẹyin ti rò ó sí pé kì yóò wá sí àjọ?”
They kept looking for Jesus and asking one another as they stood in the temple courts, “What do you think? Will He come to the feast at all?”
57 Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.
But the chief priests and Pharisees had given orders that anyone who knew where He was must report it, so that they could arrest Him.