< Joel 1 >
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.
The Lord’s message that came to Joel, son of Pethuel.
2 Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà; ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà. Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?
Hear this, elders, pay attention, all inhabitants of the land. Has anything like this happened in your days, or in the days of your ancestors?
3 Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín, ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn, ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.
Recount it to your children; let your children tell it to their children, and their children to the generation that follows.
4 Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù ní ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá ti jẹ, èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá jẹ kù ní eṣú kéékèèké jẹ, èyí tí eṣú kéékèèké jẹ kù ni eṣú apanirun mìíràn jẹ.
That which the cutting locust has left, the swarming locust has eaten, that which the swarming locust has left, the hopping locust has eaten, and that which the hopping locust has left, the destroying locust has eaten.
5 Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì; ẹ hu nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.
Awake, drunkards, and weep, and wail, all drinkers of wine; the new wine is cut off from your mouth.
6 Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.
For a nation has come up on my land, powerful, and numberless; its teeth are the teeth of a lion, and its jaw-teeth are like those of a lioness.
7 Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.
It has laid waste my vines, and barked my fig tree; it has peeled and cast it away, bleached are the branches.
8 Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.
Wail as a bride, clad in sack-cloth, for the husband of her youth.
9 A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò ní ilé Olúwa. Àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa.
Cut off are the cereal and drink-offerings from the house of the Lord; in mourning are the priests, who minister at the Lord’s altar.
10 Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.
The fields are blasted, the land is in mourning, for ruined is the grain, the new wine fails and the oil is dried up.
11 Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí alikama àti nítorí ọkà barle; nítorí ìkórè oko ṣègbé.
Be dismayed, farmers; wail, vine-dressers. For the wheat and the barley; for the harvest is lost from the fields.
12 Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ. Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
The vine fails to bear fruit, and the fig tree is drooping; the pomegranate, palm, and apple, all the trees of the field are dried up. The people’s joy withers.
13 Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi, nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.
Put on sackcloth, and beat your breasts, priests; wail, ministers of the altar; come, lie all night in sack-cloth, ministers of God; for cereal-offering and drink-offering are cut off from the house of your God.
14 Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbàgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sí ké pe Olúwa.
Sanctify a fast, summon an assembly, gather the elders and all the inhabitants of the land into the house of the Lord your God, cry to the Lord:
15 A! Fún ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè.
Alas for the day! Near at hand is the day of the Lord, and as destruction from the Almighty it comes.
16 A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú ojú wá yìí, ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé Ọlọ́run wá?
Is not food cut off from before us, gladness and joy from the house of our God?
17 Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn, a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀; nítorí tí a mú ọkà rọ.
The grains shrivel under their hoes, the storehouses are desolate, the barns broken down, for the grain is withered.
18 Àwọn ẹranko tí ń kérora tó! Àwọn agbo ẹran dààmú, nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko; nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.
How the herds of cattle bellow in distress, for they have no pasture! The flocks of sheep are forlorn.
19 Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè, nítorí iná tí run pápá oko tútù aginjù, ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.
To you, the Lord, I cry. For fire has devoured the pastures of the wilderness, and flame has scorched all the trees of the field.
20 Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú, nítorí tí àwọn ìṣàn omi gbẹ, iná sí ti jó àwọn pápá oko aginjù run.
The wild animals also look up to you longingly, for the water-courses are dried up, and fire has devoured the pastures of the wilderness.