< Joel 3 >

1 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.
“到那日,我使犹大和耶路撒冷被掳之人归回的时候,
2 Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jehoṣafati. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Israẹli ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.
我要聚集万民,带他们下到约沙法谷,在那里施行审判;因为他们将我的百姓,就是我的产业以色列,分散在列国中,又分取我的地土,
3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.
且为我的百姓拈阄,将童子换妓女,卖童女买酒喝。
4 “Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín.
“泰尔、西顿,和非利士四境的人哪,你们与我何干?你们要报复我吗?若报复我,我必使报应速速归到你们的头上。
5 Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín.
你们既然夺取我的金银,又将我可爱的宝物带入你们宫殿,
6 Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.
并将犹大人和耶路撒冷人卖给希腊人,使他们远离自己的境界。
7 “Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín.
我必激动他们离开你们所卖到之地,又必使报应归到你们的头上。
8 Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.
我必将你们的儿女卖在犹大人的手中,他们必卖给远方示巴国的人。这是耶和华说的。”
9 Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí; ẹ dira ogun, ẹ jí àwọn alágbára. Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun.
当在万民中宣告说: 要预备打仗; 激动勇士, 使一切战士上前来。
10 Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.”
要将犁头打成刀剑, 将镰刀打成戈矛; 软弱的要说:我有勇力。
11 Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.
四围的列国啊, 你们要速速地来, 一同聚集。 耶和华啊, 求你使你的大能者降临。
12 “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.
万民都当兴起, 上到约沙法谷; 因为我必坐在那里, 审判四围的列国。
13 Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀, nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀, nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”
开镰吧!因为庄稼熟了; 践踏吧!因为酒榨满了。 酒池盈溢; 他们的罪恶甚大。
14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àfonífojì ìpinnu! Nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ ní àfonífojì ìdájọ́.
许多许多的人在断定谷, 因为耶和华的日子临近断定谷。
15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.
日月昏暗, 星宿无光。
16 Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.
耶和华必从锡安吼叫, 从耶路撒冷发声, 天地就震动。 耶和华却要作他百姓的避难所, 作以色列人的保障。
17 “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.
你们就知道我是耶和华—你们的 神, 且又住在锡安—我的圣山。 那时,耶路撒冷必成为圣; 外邦人不再从其中经过。
18 “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀, àwọn òkè kéékèèké yóò máa sàn fún wàrà; gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi. Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá, yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.
到那日,大山要滴甜酒; 小山要流奶子; 犹大溪河都有水流。 必有泉源从耶和华的殿中流出来, 滋润什亭谷。
19 Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro, Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro, nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda, ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
埃及必然荒凉, 以东变为凄凉的旷野, 都因向犹大人所行的强暴, 又因在本地流无辜人的血。
20 Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé, àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.
但犹大必存到永远; 耶路撒冷必存到万代。
21 Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.
我未曾报复流血的罪, 现在我要报复, 因为耶和华住在锡安。

< Joel 3 >