< Job 8 >

1 Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé,
וַ֭יַּעַן בִּלְדַּ֥ד הַשּׁוּחִ֗י וַיֹאמַֽר׃
2 “Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó? Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
עַד־אָ֥ן תְּמַלֶּל־אֵ֑לֶּה וְר֥וּחַ כַּ֝בִּיר אִמְרֵי־פִֽיךָ׃
3 Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí? Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
הַ֭אֵל יְעַוֵּ֣ת מִשְׁפָּ֑ט וְאִם־שַׁ֝דַּ֗י יְעַוֵּֽת־צֶֽדֶק׃
4 Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
אִם־בָּנֶ֥יךָ חָֽטְאוּ־ל֑וֹ וַֽ֝יְשַׁלְּחֵ֗ם בְּיַד־פִּשְׁעָֽם׃
5 Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
אִם־אַ֭תָּה תְּשַׁחֵ֣ר אֶל־אֵ֑ל וְאֶל־שַׁ֝דַּ֗י תִּתְחַנָּֽן׃
6 Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
אִם־זַ֥ךְ וְיָשָׁ֗ר אָ֥תָּה כִּי־עַ֭תָּה יָעִ֣יר עָלֶ֑יךָ וְ֝שִׁלַּ֗ם נְוַ֣ת צִדְקֶֽךָ׃
7 Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.
וְהָיָ֣ה רֵאשִׁיתְךָ֣ מִצְעָ֑ר וְ֝אַחֲרִיתְךָ֗ יִשְׂגֶּ֥ה מְאֹֽד׃
8 “Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.
כִּֽי־שְׁאַל־נָ֭א לְדֹ֣ר רִישׁ֑וֹן וְ֝כוֹנֵ֗ן לְחֵ֣קֶר אֲבוֹתָֽם׃
9 Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
כִּֽי־תְמ֣וֹל אֲ֭נַחְנוּ וְלֹ֣א נֵדָ֑ע כִּ֤י צֵ֖ל יָמֵ֣ינוּ עֲלֵי־אָֽרֶץ׃
10 Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
הֲלֹא־הֵ֣ם י֭וֹרוּךָ יֹ֣אמְרוּ לָ֑ךְ וּ֝מִלִּבָּ֗ם יוֹצִ֥אוּ מִלִּֽים׃
11 Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?
הֲיִֽגְאֶה־גֹּ֭מֶא בְּלֹ֣א בִצָּ֑ה יִשְׂגֶּה־אָ֥חוּ בְלִי־מָֽיִם׃
12 Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.
עֹדֶ֣נּוּ בְ֭אִבּוֹ לֹ֣א יִקָּטֵ֑ף וְלִפְנֵ֖י כָל־חָצִ֣יר יִיבָֽשׁ׃
13 Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
כֵּ֗ן אָ֭רְחוֹת כָּל־שֹׁ֣כְחֵי אֵ֑ל וְתִקְוַ֖ת חָנֵ֣ף תֹּאבֵֽד׃
14 Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
אֲשֶׁר־יָק֥וֹט כִּסְל֑וֹ וּבֵ֥ית עַ֝כָּבִ֗ישׁ מִבְטַחֽוֹ׃
15 Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
יִשָּׁעֵ֣ן עַל־בֵּ֭יתוֹ וְלֹ֣א יַעֲמֹ֑ד יַחֲזִ֥יק בּ֝֗וֹ וְלֹ֣א יָקֽוּם׃
16 Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
רָטֹ֣ב ה֭וּא לִפְנֵי־שָׁ֑מֶשׁ וְעַ֥ל גַּ֝נָּת֗וֹ יֹֽנַקְתּ֥וֹ תֵצֵֽא׃
17 Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
עַל־גַּ֭ל שָֽׁרָשָׁ֣יו יְסֻבָּ֑כוּ בֵּ֖ית אֲבָנִ֣ים יֶחֱזֶֽה׃
18 Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
אִם־יְבַלְּעֶ֥נּוּ מִמְּקוֹמ֑וֹ וְכִ֥חֶשׁ בּ֝֗וֹ לֹ֣א רְאִיתִֽיךָ׃
19 Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.
הֶן־ה֭וּא מְשׂ֣וֹשׂ דַּרְכּ֑וֹ וּ֝מֵעָפָ֗ר אַחֵ֥ר יִצְמָֽחוּ׃
20 “Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́
הֶן־אֵ֭ל לֹ֣א יִמְאַס־תָּ֑ם וְלֹֽא־יַ֝חֲזִ֗יק בְּיַד־מְרֵעִֽים׃
21 títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
עַד־יְמַלֵּ֣ה שְׂח֣וֹק פִּ֑יךָ וּשְׂפָתֶ֥יךָ תְרוּעָֽה׃
22 ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”
שֹׂנְאֶ֥יךָ יִלְבְּשׁוּ־בֹ֑שֶׁת וְאֹ֖הֶל רְשָׁעִ֣ים אֵינֶֽנּוּ׃ פ

< Job 8 >