< Job 5 >

1 “Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn? Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí?
קרא נא היש עונך ואל מי מקדשים תפנה׃
2 Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye, ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.
כי לאויל יהרג כעש ופתה תמית קנאה׃
3 Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.
אני ראיתי אויל משריש ואקוב נוהו פתאם׃
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.
ירחקו בניו מישע וידכאו בשער ואין מציל׃
5 Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó, àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì.
אשר קצירו רעב יאכל ואל מצנים יקחהו ושאף צמים חילם׃
6 Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni, tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.
כי לא יצא מעפר און ומאדמה לא יצמח עמל׃
7 Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà, gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.
כי אדם לעמל יולד ובני רשף יגביהו עוף׃
8 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀, ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.
אולם אני אדרש אל אל ואל אלהים אשים דברתי׃
9 Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí, ohun ìyanu láìní iye.
עשה גדלות ואין חקר נפלאות עד אין מספר׃
10 Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.
הנתן מטר על פני ארץ ושלח מים על פני חוצות׃
11 Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.
לשום שפלים למרום וקדרים שגבו ישע׃
12 Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.
מפר מחשבות ערומים ולא תעשינה ידיהם תושיה׃
13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.
לכד חכמים בערמם ועצת נפתלים נמהרה׃
14 Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán; wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.
יומם יפגשו חשך וכלילה ימששו בצהרים׃
15 Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.
וישע מחרב מפיהם ומיד חזק אביון׃
16 Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà, àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
ותהי לדל תקוה ועלתה קפצה פיה׃
17 “Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.
הנה אשרי אנוש יוכחנו אלוה ומוסר שדי אל תמאס׃
18 Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura, ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná.
כי הוא יכאיב ויחבש ימחץ וידו תרפינה׃
19 Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ.
בשש צרות יצילך ובשבע לא יגע בך רע׃
20 Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
ברעב פדך ממות ובמלחמה מידי חרב׃
21 A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n, bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.
בשוט לשון תחבא ולא תירא משד כי יבוא׃
22 Ìwọ yóò rẹ́rìn-ín nínú ìparun àti ìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.
לשד ולכפן תשחק ומחית הארץ אל תירא׃
23 Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀, àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.
כי עם אבני השדה בריתך וחית השדה השלמה לך׃
24 Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà, ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà.
וידעת כי שלום אהלך ופקדת נוך ולא תחטא׃
25 Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó.
וידעת כי רב זרעך וצאצאיך כעשב הארץ׃
26 Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́, bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.
תבוא בכלח אלי קבר כעלות גדיש בעתו׃
27 “Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí! Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”
הנה זאת חקרנוה כן היא שמענה ואתה דע לך׃

< Job 5 >