< Job 41 >

1 “Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?
“Do you draw leviathan with a hook? And do you let down his tongue with a rope?
2 Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú, tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?
Do you put a reed in his nose? And pierce his jaw with a thorn?
3 Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?
Does he multiply supplications to you? Does he speak tender things to you?
4 Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?
Does he make a covenant with you? Do you take him for a perpetual servant?
5 Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?
Do you play with him as a bird? And do you bind him for your girls?
6 Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí? Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?
(Companions feast on him, They divide him among the merchants!)
7 Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀, tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.
Do you fill his skin with barbed irons? And his head with fish-spears?
8 Fi ọwọ́ rẹ lé e lára, ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Place your hand on him, Remember the battle—do not add!
9 Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán; ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
Behold, the hope of him is found a liar, Also, is one not cast down at his appearance?
10 Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè. Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.
None so fierce that he awakes him, And who [is] he [who] stations himself before Me?
11 Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
Who has brought before Me and I repay? Under the whole heavens it [is] Mine.
12 “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani, tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.
I do not keep silent concerning his parts, And the matter of might, And the grace of his arrangement.
13 Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀? Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?
Who has uncovered the face of his clothing? Who enters within his double bridle?
14 Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀? Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.
Who has opened the doors of his face? Around his teeth [are] terrible.
15 Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.
A pride—strong ones of shields, Shut up—a close seal.
16 Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.
They draw near to one another, And air does not enter between them.
17 Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.
They adhere to one another, They stick together and are not separated.
18 Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́, ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.
His sneezings cause light to shine, And his eyes [are] as the eyelids of the dawn.
19 Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.
Flames go out of his mouth, sparks of fire escape.
20 Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá, bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.
Smoke goes forth out of his nostrils, As a blown pot and reeds.
21 Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná, ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.
His breath sets coals on fire, And a flame goes forth from his mouth.
22 Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí, àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.
Strength lodges in his neck, And grief exults before him.
23 Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.
The flakes of his flesh have adhered—Firm on him—it is not moved.
24 Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta, àní, ó le bi ìyá ọlọ.
His heart [is] firm as a stone, Indeed, firm as the lower piece.
25 Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù; nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.
The mighty are afraid at his rising, From his breakings they keep themselves free.
26 Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà, ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.
The sword of his overtaker does not stand, Spear, dart, and breastplate.
27 Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ àti idẹ si bi igi híhù.
He reckons iron as straw, bronze as rotten wood.
28 Ọfà kò lè mú un sá; òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.
The son of the bow does not cause him to flee, Stones of the sling are turned into stubble by him.
29 Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko; ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.
Darts have been reckoned as stubble, And he laughs at the shaking of a javelin.
30 Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.
Sharp points of clay [are] under him, He spreads gold on the mire.
31 Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.
He causes the deep to boil as a pot, He makes the sea as a pot of ointment.
32 Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.
He causes a path to shine after him, One thinks the deep to be hoary.
33 Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀, tí a dá láìní ìbẹ̀rù.
There is not on the earth his like, That is made without terror.
34 Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”
He sees every high thing, He [is] king over all sons of pride.”

< Job 41 >