< Job 40 >
1 Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,
And YHWH answers Job and says:
2 “Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́? Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”
“Is the striver with the Mighty instructed? The reprover of God, let him answer it.”
3 Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,
And Job answers YHWH and says:
4 “Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.
“Behold, I have been vile, What do I return to You? I have placed my hand on my mouth.
5 Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”
I have spoken once, and I do not answer, And twice, and I do not add.”
6 Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,
And YHWH answers Job out of the whirlwind and says:
7 “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
“Now gird your loins as a man, I ask you, and you cause Me to know.
8 “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.
Do you also make My judgment void? Do you condemn Me, That you may be righteous?
9 Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
And do you have an arm like God? And do you thunder with a voice like His?
10 Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
Now put on excellence and loftiness, Indeed, put on splendor and beauty.
11 Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde; kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
Scatter abroad the wrath of your anger, And see every proud one, and make him low.
12 Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀ kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
See every proud one—humble him, And tread down the wicked in their place.
13 Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.
Hide them in the dust together, Bind their faces in secret.
14 Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé, ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
And even I praise you, For your right hand gives salvation to you.
15 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti, tí mo dá pẹ̀lú rẹ, òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
Now behold, behemoth, That I made with you: He eats grass as an ox.
16 Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
Now behold, his power [is] in his loins, And his strength in the muscles of his belly.
17 Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
He bends his tail as a cedar, The sinews of his thighs are wrapped together,
18 Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ, Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
His bones [are] tubes of bronze, His bones [are] as a bar of iron.
19 Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
He [is] a beginning of the ways of God, His Maker [alone] brings His sword near;
20 Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
For mountains bear food for him, And all the beasts of the field play there.
21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì, lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
He lies down under shades, In a secret place of reed and marsh.
22 Igi lótusì síji wọn bò o; igi arọrọ odò yí i káàkiri.
Shades cover him, [with] their shadow, Willows of the brook cover him.
23 Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
Behold, a flood oppresses—he does not hurry, He is confident though Jordan Comes forth to his mouth.
24 Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀, tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?
Does [one] take him by his eyes? Does [one] pierce the nose with snares?”