< Job 39 >
1 “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ? Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?
¿Sabes tú el tiempo en que paren las cabras monteses? ¿ó miraste tú las ciervas cuando están pariendo?
2 Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé, ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ.
¿Contaste tú los meses de su preñez, y sabes el tiempo cuando han de parir?
3 Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ, wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde.
Encórvanse, hacen salir sus hijos, pasan sus dolores.
4 Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn; wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.
Sus hijos están sanos, crecen con el pasto: salen y no vuelven á ellas.
5 “Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́? Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,
¿Quién echó libre al asno montés, y quién soltó sus ataduras?
6 èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún, àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀.
Al cual yo puse casa en la soledad, y sus moradas en lugares estériles.
7 Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran.
Búrlase de la multitud de la ciudad: no oye las voces del arriero.
8 Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀, òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí.
Lo oculto de los montes es su pasto, y anda buscando todo lo que está verde.
9 “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
¿Querrá el unicornio servirte á ti, ni quedar á tu pesebre?
10 Ìwọ le fi òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
¿Atarás tú al unicornio con su coyunda para el surco? ¿labrará los valles en pos de ti?
11 Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀? Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?
¿Confiarás tú en él, por ser grande su fortaleza, y le fiarás tu labor?
12 Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ?
¿Fiarás de él que te tornará tu simiente, y que [la] allegará en tu era?
13 “Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí, tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?
¿[Diste tú] hermosas alas al pavo real, ó alas y plumas al avestruz?
14 Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;
El cual desampara en la tierra sus huevos, y sobre el polvo los calienta,
15 tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
Y olvídase de que los pisará el pie, y que los quebrará bestia del campo.
16 Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;
Endurécese para con sus hijos, como si no fuesen suyos, no temiendo que su trabajo haya sido en vano:
17 nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.
Porque le privó Dios de sabiduría, y no le dió inteligencia.
18 Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.
Luego que se levanta en alto, búrlase del caballo y de su jinete.
19 “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí, tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?
¿Diste tú al caballo la fortaleza? ¿vestiste tú su cerviz de relincho?
20 Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà? Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.
¿Le intimidarás tú como á alguna langosta? El resoplido de su nariz es formidable:
21 Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
Escarba la tierra, alégrase en su fuerza, sale al encuentro de las armas:
22 Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.
Hace burla del espanto, y no teme, ni vuelve el rostro delante de la espada.
23 Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
Contra él suena la aljaba, el hierro de la lanza y de la pica:
24 Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.
Y él con ímpetu y furor escarba la tierra, sin importarle el sonido de la bocina;
25 Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré, igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.
[Antes como] que dice entre los clarines: ¡Ea!, y desde lejos huele la batalla, el grito de los capitanes, y la vocería.
26 “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè, tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?
¿Vuela el gavilán por tu industria, y extiende hacia el mediodía sus alas?
27 Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè, kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?
¿Se remonta el águila por tu mandamiento, y pone en alto su nido?
28 Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta, lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.
Ella habita y está en la piedra, en la cumbre del peñasco y de la roca.
29 Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.
Desde allí acecha la comida: sus ojos observan de muy lejos.
30 Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀, níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”
Sus pollos chupan la sangre: y donde hubiere cadáveres, allí está.