< Job 38 >

1 Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé,
ויען-יהוה את-איוב מנהסערה (מן הסערה) ויאמר
2 “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi?
מי זה מחשיך עצה במלין-- בלי-דעת
3 Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn.
אזר-נא כגבר חלציך ואשאלך והודיעני
4 “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.
איפה היית ביסדי-ארץ הגד אם-ידעת בינה
5 Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
מי-שם ממדיה כי תדע או מי-נטה עליה קו
6 Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
על-מה אדניה הטבעו או מי-ירה אבן פנתה
7 nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
ברן-יחד כוכבי בקר ויריעו כל-בני אלהים
8 “Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá.
ויסך בדלתים ים בגיחו מרחם יצא
9 Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀.
בשומי ענן לבשו וערפל חתלתו
10 Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un, tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn.
ואשבר עליו חקי ואשים בריח ודלתים
11 Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
ואמר--עד-פה תבוא ולא תסיף ופא-ישית בגאון גליך
12 “Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá, ìwọ sì mú ìlà-oòrùn mọ ipò rẹ̀,
המימיך צוית בקר ידעתה שחר (ידעת השחר) מקמו
13 í ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?
לאחז בכנפות הארץ וינערו רשעים ממנה
14 Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.
תתהפך כחמר חותם ויתיצבו כמו לבוש
15 A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga ni a sì ṣẹ́.
וימנע מרשעים אורם וזרוע רמה תשבר
16 “Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
הבאת עד-נבכי-ים ובחקר תהום התהלכת
17 A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú?
הנגלו לך שערי-מות ושערי צלמות תראה
18 Ìwọ mòye ìbú ayé bí? Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.
התבננת עד-רחבי-ארץ הגד אם-ידעת כלה
19 “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,
אי-זה הדרך ישכן-אור וחשך אי-זה מקמו
20 tí ìwọ í fi mú un lọ sí ibi àlá rẹ̀, tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?
כי תקחנו אל-גבולו וכי-תבין נתיבות ביתו
21 Ìwọ mọ èyí, nítorí nígbà náà ni a bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.
ידעת כי-אז תולד ומספר ימיך רבים
22 “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí, ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,
הבאת אל-אצרות שלג ואוצרות ברד תראה
23 tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
אשר-חשכתי לעת-צר ליום קרב ומלחמה
24 Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
אי-זה הדרך יחלק אור יפץ קדים עלי-ארץ
25 Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
מי-פלג לשטף תעלה ודרך לחזיז קלות
26 láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;
להמטיר על-ארץ לא-איש-- מדבר לא-אדם בו
27 láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?
להשביע שאה ומשאה ולהצמיח מצא דשא
28 Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?
היש-למטר אב או מי-הוליד אגלי-טל
29 Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá? Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?
מבטן מי יצא הקרח וכפר שמים מי ילדו
30 Nígbà tí omi di líle bí òkúta, nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀.
כאבן מים יתחבאו ופני תהום יתלכדו
31 “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára? Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni?
התקשר מעדנות כימה או-משכות כסיל תפתח
32 Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
התציא מזרות בעתו ועיש על-בניה תנחם
33 Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run? Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
הידעת חקות שמים אם-תשים משטרו בארץ
34 “Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
התרים לעב קולך ושפעת-מים תכסך
35 Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Àwa nìyí’?
התשלח ברקים וילכו ויאמרו לך הננו
36 Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn tàbí tí ó fi òye sínú àyà?
מי-שת בטחות חכמה או מי-נתן לשכוי בינה
37 Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,
מי-יספר שחקים בחכמה ונבלי שמים מי ישכיב
38 nígbà tí erùpẹ̀ di líle, àti ògúlùtu dìpọ̀?
בצקת עפר למוצק ורגבים ידבקו
39 “Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,
התצוד ללביא טרף וחית כפירים תמלא
40 nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?
כי-ישחו במעונות ישבו בסכה למו-ארב
41 Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?
מי יכין לערב צידו כי-ילדו אל-אל ישועו יתעו לבלי-אכל

< Job 38 >