< Job 37 >
1 “Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú, ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
Disto também o meu coração treme, e salta de seu lugar.
2 Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
Ouvi atentamente o estrondo de sua voz, e o som que sai de sua boca,
3 Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo, mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ao qual envia por debaixo de todos os céus; e sua luz até os confins da terra.
4 Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù; ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá. Òhun kì yóò sì dá àrá dúró, nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
Depois disso brama com estrondo; troveja com sua majestosa voz; e ele não retém [seus relâmpagos] quando sua voz é ouvida.
5 Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu; ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
Deus troveja maravilhosamente com sua voz; ele faz coisas tão grandes que nós não compreendemos.
6 Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’ àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
Pois ele diz à neve: Cai sobre à terra; Como também à chuva: Sê chuva forte.
7 Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀, ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
Ele sela as mãos de todo ser humano, para que todas as pessoas conheçam sua obra.
8 Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn.
E os animais selvagens entram nos esconderijos, e ficam em suas tocas.
9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
Da recâmara vem o redemoinho, e dos [ventos] que espalham [vem] o frio.
10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni, ibú omi á sì súnkì.
Pelo sopro de Deus se dá o gelo, e as largas águas se congelam.
11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
Ele também carrega de umidade as espessas nuvens, [e] por entre as nuvens ele espalha seu relâmpago.
12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀, kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
Então elas se movem ao redor segundo sua condução, para que façam quanto ele lhes manda sobre a superfície do mundo, na terra;
13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
Seja que ou por vara de castigo, ou para sua terra, ou por bondade as faça vir.
14 “Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí; dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
Escuta isto, Jó; fica parado, e considera as maravilhas de Deus.
15 Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
Por acaso sabes tu quando Deus dá ordem a elas, e faz brilhar o relâmpago de sua nuvem?
16 Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
Conheces tu os equilíbrios das nuvens, as maravilhas daquele que é perfeito no conhecimento?
17 Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
Tu, cujas vestes se aquecem quando a terra se aquieta por causa do [vento] sul,
18 Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin, tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?
acaso podes estender com ele os céus, que estão firmes como um espelho fundido?
19 “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un; nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
Ensina-nos o que devemos dizer a ele; [pois discurso] nenhum podemos propor, por causa das [nossas] trevas.
20 A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
Seria contado a ele o que eu haveria de falar? Por acaso alguém falaria para ser devorado?
21 Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀, ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.
E agora não se pode olhar para o sol, quando brilha nos céus, quando o vento passa e os limpa.
22 Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá; lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.
Do norte vem o esplendor dourado; em Deus há majestade temível.
23 Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá; nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
Não podemos alcançar ao Todo-Poderoso; ele é grande em poder; porém ele a ninguém oprime [em] juízo e grandeza de justiça.
24 Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀, òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”
Por isso as pessoas o temem; ele não dá atenção aos que [se acham] sábios de coração.