< Job 35 >

1 Elihu sì wí pe:
וַיַּ֥עַן אֱלִיה֗וּ וַיֹּאמַֽר׃
2 “Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé, òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?
הֲ֭זֹאת חָשַׁ֣בְתָּ לְמִשְׁפָּ֑ט אָ֝מַ֗רְתָּ צִדְקִ֥י מֵאֵֽל׃
3 Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.
כִּֽי־תֹ֭אמַר מַה־יִּסְכָּן־לָ֑ךְ מָֽה־אֹ֝עִ֗יל מֵֽחַטָּאתִֽי׃
4 “Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.
אֲ֭נִי אֲשִֽׁיבְךָ֣ מִלִּ֑ין וְֽאֶת־רֵעֶ֥יךָ עִמָּֽךְ׃
5 Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.
הַבֵּ֣ט שָׁמַ֣יִם וּרְאֵ֑ה וְשׁ֥וּר שְׁ֝חָקִ֗ים גָּבְה֥וּ מִמֶּֽךָּ׃
6 Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?
אִם־חָ֭טָאתָ מַה־תִּפְעָל־בֹּ֑ו וְרַבּ֥וּ פְ֝שָׁעֶ֗יךָ מַה־תַּעֲשֶׂה־לֹּֽו׃
7 Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?
אִם־צָ֭דַקְתָּ מַה־תִּתֶּן־לֹ֑ו אֹ֥ו מַה־מִיָּדְךָ֥ יִקָּֽח׃
8 Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.
לְאִישׁ־כָּמֹ֥וךָ רִשְׁעֶ֑ךָ וּלְבֶן־אָ֝דָ֗ם צִדְקָתֶֽךָ׃
9 “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe; wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.
מֵ֭רֹב עֲשׁוּקִ֣ים יַזְעִ֑יקוּ יְשַׁוְּע֖וּ מִזְּרֹ֣ועַ רַבִּֽים׃
10 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;
וְֽלֹא־אָמַ֗ר אַ֭יֵּה אֱלֹ֣והַּ עֹשָׂ֑י נֹתֵ֖ן זְמִרֹ֣ות בַּלָּֽיְלָה׃
11 tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’
מַ֭לְּפֵנוּ מִבַּהֲמֹ֣ות אָ֑רֶץ וּמֵעֹ֖וף הַשָּׁמַ֣יִם יְחַכְּמֵֽנוּ׃
12 Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.
שָׁ֣ם יִ֭צְעֲקוּ וְלֹ֣א יַעֲנֶ֑ה מִ֝פְּנֵ֗י גְּאֹ֣ון רָעִֽים׃
13 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán; bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.
אַךְ־שָׁ֭וְא לֹא־יִשְׁמַ֥ע ׀ אֵ֑ל וְ֝שַׁדַּ֗י לֹ֣א יְשׁוּרֶֽנָּה׃
14 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ, ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.
אַ֣ף כִּֽי־תֹ֖אמַר לֹ֣א תְשׁוּרֶ֑נּוּ דִּ֥ין לְ֝פָנָ֗יו וּתְחֹ֥ולֵֽל לֹֽו׃
15 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí fìyà jẹ ni, òun kò ni ka ìwà búburú si?
וְעַתָּ֗ה כִּי־אַ֭יִן פָּקַ֣ד אַפֹּ֑ו וְלֹֽא־יָדַ֖ע בַּפַּ֣שׁ מְאֹֽד׃
16 Nítorí náà ní Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀ lásán ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”
וְ֭אִיֹּוב הֶ֣בֶל יִפְצֶה־פִּ֑יהוּ בִּבְלִי־דַ֝֗עַת מִלִּ֥ין יַכְבִּֽר׃ פ

< Job 35 >