< Job 34 >
1 Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé,
2 “Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.
3 Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.
4 Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa; ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.
5 “Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi; Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.
6 Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’
7 Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?
8 Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.
9 Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’
10 “Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye: Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!
11 Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe, yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.
12 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà; bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.
13 Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́, tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lé e lọ́wọ́?
14 Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀ tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
15 gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀, ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.
16 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi.
17 Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí? Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?
18 O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’ tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’
19 mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?
20 Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú, àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ; a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.
21 “Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.
22 Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.
23 Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.
24 Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,
25 nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
26 Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,
27 nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i, wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,
28 kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.
29 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi? Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i? Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;
30 kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọba kí wọn kí ó má di ìdẹwò fún ènìyàn.
31 “Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé, èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?
32 Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
33 Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà? Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́, ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi. Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́!
34 “Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,
35 ‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’
36 Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin, nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú.
37 Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa, ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”