< Job 33 >

1 “Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmí bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi!
Audi igitur Iob eloquia mea, et omnes sermones meos ausculta.
2 Kíyèsi i nísinsin yìí, èmí ya ẹnu mi, ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi.
Ecce aperui os meum, loquatur lingua mea in faucibus meis.
3 Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jásí ìdúró ṣinṣin ọkàn mi, ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú.
Simplici corde meo sermones mei, et sententiam puram labia mea loquentur.
4 Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó tí dá mi, àti ìmísí Olódùmarè ni ó ti fún mi ní ìyè.
Spiritus Dei fecit me, et spiraculum Omnipotentis vivificavit me.
5 Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn, tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ níwájú mi;
Si potes, responde mihi, et adversus faciem meam consiste.
6 kíyèsi i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà; láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú.
Ecce, et me sicut et te fecit Deus, et de eodem luto ego quoque formatus sum.
7 Kíyèsi i, ẹ̀rù ńlá mi kì yóò bà ọ; bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.
Verumtamen miraculum meum non te terreat, et eloquentia mea non sit tibi gravis.
8 “Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi, èmí sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,
Dixisti ergo in auribus meis, et vocem verborum tuorum audivi:
9 ‘Èmi mọ́, láìní ìrékọjá, aláìṣẹ̀ ní èmi; bẹ́ẹ̀ àìṣedéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.
Mundus sum ego, et absque delicto: immaculatus, et non est iniquitas in me.
10 Kíyèsi i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi; ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.
Quia querelas in me reperit, ideo arbitratus est me inimicum sibi.
11 Ó kan ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà; o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo.’
Posuit in nervo pedes meos, custodivit omnes semitas meas.
12 “Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà! Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!
Hoc est ergo, in quo non es iustificatus: respondebo tibi, quia maior sit Deus homine.
13 Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé, òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?
Adversus eum contendis quod non ad omnia verba responderit tibi?
14 Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.
Semel loquitur Deus, et secundo idipsum non repetit.
15 Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn,
Per somnium in visione nocturna, quando irruit sopor super homines, et dormiunt in lectulo:
16 nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,
Tunc aperit aures virorum, et erudiens eos instruit disciplina,
17 kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀; kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;
Ut avertat hominem ab his, quae facit, et liberet eum de superbia:
18 Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.
Eruens animam eius a corruptione: et vitam illius, ut non transeat in gladium.
19 “A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀; pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án,
Increpat quoque per dolorem in lectulo, et omnia ossa eius marcescere facit.
20 bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.
Abominabilis ei fit in vita sua panis, et animae illius cibus ante desiderabilis.
21 Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́ egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde.
Tabescet caro eius, et ossa, quae tecta fuerant, nudabuntur.
22 Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú, ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.
Appropinquavit corruptioni anima eius, et vita illius mortiferis.
23 Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tí ń ṣe alágbàwí, ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
Si fuerit pro eo Angelus loquens, unus de millibus, ut annunciet hominis aequitatem:
24 nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé, gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú; èmi ti rà á padà.
Miserebitur eius, et dicet: Libera eum, ut non descendat in corruptionem: inveni in quo ei propitier.
25 Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
Consumpta est caro eius a suppliciis, revertatur ad dies adolescentiae suae.
26 Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.
Deprecabitur Deum, et placabilis ei erit: et videbit faciem eius in iubilo, et reddet homini iustitiam suam.
27 Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé, ‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;
Respiciet homines, et dicet: Peccavi, et vere deliqui, et, ut eram dignus, non recepi.
28 Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’
Liberavit animam suam ne pergeret in interitum, sed vivens lucem videret.
29 “Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta,
Ecce, haec omnia operatur Deus tribus vicibus per singulos.
30 láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i.
Ut revocet animas eorum a corruptione, et illuminet luce viventium.
31 “Jobu, kíyèsi i gidigidi, kí o sì fetí sí mi; pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́.
Attende Iob, et audi me: et tace, dum ego loquor.
32 Bí ìwọ bá sì ní ohun wí, dá mi lóhùn; máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.
Si autem habes quod loquaris, responde mihi, loquere: volo enim, te apparere iustum.
33 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi; pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”
Quod si non habes, audi me: tace, et docebo te sapientiam.

< Job 33 >