< Job 32 >
1 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jobu lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀.
2 Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre.
3 Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi.
4 Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí.
5 Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.
6 Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé, “Ọmọdé ni èmi, àgbà sì ní ẹ̀yin; ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró, mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.
7 Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
8 Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
9 Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.
10 “Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
11 Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín; èmi fetísí àròyé yín, nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;
12 àní, mo fiyèsí yín tinútinú. Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́; tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!
13 Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí; Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’
14 Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.
15 “Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́, wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.
16 Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.
17 Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.
18 Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.
19 Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.
20 Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí, èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.
21 Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.
22 Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.