< Job 31 >

1 “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú, èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?
Hice pacto con mis ojos; ¿cómo, pues, había yo de mirar a una virgen?
2 Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá? Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.
Porque ¿qué galardón me daría de arriba Dios, y qué heredad el Omnipotente de las alturas?
3 Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
¿Por ventura no hay quebrantamiento para el impío, y extrañamiento para los que obran iniquidad?
4 Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?
¿Por ventura no ve él mis caminos, y cuenta todos mis pasos?
5 “Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn,
Si anduve con mentira, y si mi pie se apresuró a engaño,
6 (jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
péseme Dios en balanzas de justicia, y conocerá mi perfección.
7 Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,
Si mis pasos se apartaron del camino, y si mi corazón se fue tras mis ojos, y si algo se apegó a mis manos,
8 ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.
siembre yo, y otro coma, y mis verduras sean arrancadas.
9 “Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
Si fue mi corazón engañado acerca de mujer, y si estuve acechando a la puerta de mi prójimo,
10 kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
muela para otro mi mujer, y sobre ella otros se encorven.
11 Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀.
Porque es maldad e iniquidad, comprobada.
12 Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.
Porque es fuego que devoraría hasta el sepulcro, y desarraigaría toda mi hacienda.
13 “Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí, nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;
Si hubiera tenido en poco el derecho de mi siervo y de mi sierva, cuando ellos pleitearan conmigo,
14 kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?
¿qué haría yo cuando Dios se levantase? Y cuando él visitara, ¿qué le respondería yo?
15 Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a? Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?
¿Por ventura el que en el vientre me hizo a mí, no lo hizo a él? ¿Y no nos dispuso un mismo autor en la matriz?
16 “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,
Si estorbé el contento de los pobres, e hice desfallecer los ojos de la viuda;
17 tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ, tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
y si comí mi bocado solo, y no comió de él el huérfano;
18 nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba, èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:
(porque desde mi juventud creció conmigo el huérfano como con padre, y desde el vientre de mi madre fui guía de la viuda);
19 bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ, tàbí tálákà kan láìní ìbora;
si he visto que pereciera alguno sin vestido, y al menesteroso sin cobertura;
20 bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;
si no me bendijeron sus lomos, y del vellón de mis ovejas se calentaron;
21 bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
si alcé contra el huérfano mi mano, aunque viese que me ayudarían en la puerta;
22 ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
mi espalda se caiga de mi hombro, y mi brazo sea quebrado de mi canilla.
23 Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi, àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
Porque temí el castigo de Dios, contra cuya alteza yo no tendría poder.
24 “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’
Si puse en el oro mi esperanza, y dije al oro: Mi confianza eres tú;
25 bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀, àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọ́pọ̀,
si me alegré de que mi hacienda se multiplicase, y de que mi mano hallase mucho;
26 bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,
si he mirado al sol cuando resplandecía, y a la luna cuando iba hermosa,
27 bí a bá tàn ọkàn mi jẹ láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi,
y mi corazón se engañó en secreto, y mi boca besó mi mano,
28 èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò, nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
esto también fuera maldad comprobada; porque habría negado al Dios soberano.
29 “Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi. Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.
Si me alegré en el quebrantamiento del que me aborrecía, y me regocijé cuando le halló el mal;
30 Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀ nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.
que ni aun entregué al pecado mi paladar, pidiendo maldición para su alma;
31 Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé, ‘Ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?’
cuando mis domésticos decían: ¡Quién nos diese de su carne! Nunca nos hartaríamos.
32 Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí; èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.
El extranjero no tenía fuera la noche; mis puertas abría al caminante.
33 Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá, ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi.
Si encubrí, como los hombres mis prevaricaciones, escondiendo en mi seno mi iniquidad;
34 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí? Tàbí ẹ̀gàn àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù? Tí mo fi pa ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi sọ̀rọ̀ jáde?
si temí a la gran multitud, y el menosprecio de las familias me atemorizó, y callé, y no salí de mi puerta,
35 (“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí! Kíyèsi i, àmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn, kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ.
¡quién me diera quien me oyese! He aquí mi señal es que el Omnipotente testificará por mí, aunque mi adversario me hiciera el proceso.
36 Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi, èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.
Ciertamente yo lo llevaría sobre mi hombro, y me lo ataría en lugar de coronas.
37 Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un, bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)
Yo le contaría el número de mis pasos, y como príncipe me llegaría a él.
38 “Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.
Si mi tierra clamara contra mí, y llorarán todos sus surcos;
39 Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owó tàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,
si comí su sustancia sin dinero, o afligí el alma de sus dueños;
40 kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama, àti èpò búburú dípò ọkà barle.” Ọ̀rọ̀ Jobu parí.
en lugar de trigo me nazcan espinos, y abrojos en lugar de cebada. Se acaban las palabras de Job.

< Job 31 >