< Job 3 >

1 Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré
post haec aperuit Iob os suum et maledixit diei suo
2 Jobu sọ, ó sì wí pé,
et locutus est
3 “Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé, àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’
pereat dies in qua natus sum et nox in qua dictum est conceptus est homo
4 Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá; bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.
dies ille vertatur in tenebras non requirat eum Deus desuper et non inlustret lumine
5 Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn; kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e; kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.
obscurent eum tenebrae et umbra mortis occupet eum caligo et involvatur amaritudine
6 Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà: kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.
noctem illam tenebrosus turbo possideat non conputetur in diebus anni nec numeretur in mensibus
7 Kí òru náà kí ó yàgàn; kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.
sit nox illa solitaria nec laude digna
8 Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún, tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.
maledicant ei qui maledicunt diei qui parati sunt suscitare Leviathan
9 Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn; kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́
obtenebrentur stellae caligine eius expectet lucem et non videat nec ortum surgentis aurorae
10 nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi, láti pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.
quia non conclusit ostia ventris qui portavit me nec abstulit mala ab oculis meis
11 “Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá, tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?
quare non in vulva mortuus sum egressus ex utero non statim perii
12 Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi, tàbí ọmú tí èmi yóò mu?
quare exceptus genibus cur lactatus uberibus
13 Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́; èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi
nunc enim dormiens silerem et somno meo requiescerem
14 pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro.
cum regibus et consulibus terrae qui aedificant sibi solitudines
15 Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn.
aut cum principibus qui possident aurum et replent domos suas argento
16 Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí: bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?
aut sicut abortivum absconditum non subsisterem vel qui concepti non viderunt lucem
17 Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu, níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.
ibi impii cessaverunt a tumultu et ibi requieverunt fessi robore
18 Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀, wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.
et quondam vincti pariter sine molestia non audierunt vocem exactoris
19 Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.
parvus et magnus ibi sunt et servus liber a domino suo
20 “Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì, àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò,
quare data est misero lux et vita his qui in amaritudine animae sunt
21 tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá, tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.
qui expectant mortem et non venit quasi effodientes thesaurum
22 Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi, tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?
gaudentque vehementer cum invenerint sepulchrum
23 Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún, tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?
viro cuius abscondita est via et circumdedit eum Deus tenebris
24 Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi; ìkérora mi sì tú jáde bí omi.
antequam comedam suspiro et quasi inundantes aquae sic rugitus meus
25 Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí, àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.
quia timor quem timebam evenit mihi et quod verebar accidit
26 Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”
nonne dissimulavi nonne silui nonne quievi et venit super me indignatio

< Job 3 >