< Job 28 >

1 Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.
Surely there is a vein for the silver, and a place for gold which they refine;
2 Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
Iron is taken out of the dust, and copper is molten out of the stone.
3 Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí ìṣúra láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
[Man] putteth an end to the darkness, and exploreth to the utmost limit, the stones of darkness and of the shadow of death.
4 Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
He openeth a shaft far from the inhabitants [of the earth]: forgotten of the foot, they hang suspended; away below men they hover.
5 Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná;
As for the earth, out of it cometh bread, and underneath it is turned up as by fire;
6 òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta safire, o sì ní erùpẹ̀ wúrà.
The stones of it are the place of sapphires, and it hath dust of gold.
7 Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí.
It is a path no bird of prey knoweth, and the vulture's eye hath not seen it;
8 Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.
The proud beasts have not trodden it, nor the fierce lion passed over it.
9 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.
[Man] putteth forth his hand upon the flinty rock, he overturneth the mountains by the root.
10 Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.
He cutteth out channels in the rocks, and his eye seeth every precious thing.
11 Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.
He bindeth the streams that they drip not, and what is hidden he bringeth forth to light.
12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?
But wisdom, where shall it be found? and where is the place of understanding?
13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
Man knoweth not the value thereof; and it is not found in the land of the living.
14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”
The deep saith, It is not in me; and the sea saith, It is not with me.
15 A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
Choice gold cannot be given for it, nor silver be weighed for its price.
16 A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta safire díye lé e.
It is not set in the balance with gold of Ophir, with the precious onyx, and the sapphire.
17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
Gold and glass cannot be compared to it, nor vessels of fine gold be its exchange.
18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
Corals and crystal are no more remembered; yea, the acquisition of wisdom is above rubies.
19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
The topaz of Ethiopia shall not be compared to it, neither shall it be set in the balance with pure gold.
20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé?
Whence then cometh wisdom? and where is the place of understanding?
21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
For it is hidden from the eyes of all living, and concealed from the fowl of the heavens.
22 Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
Destruction and death say, We have heard its report with our ears.
23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.
God understandeth the way thereof, and he knoweth its place:
24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
For he looketh to the ends of the earth, he seeth under the whole heaven.
25 láti dà òsùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òsùwọ̀n wọ́n omi.
In making a weight for the wind, and meting out the waters by measure,
26 Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
In appointing a statute for the rain, and a way for the thunder's flash:
27 nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.
Then did he see it, and declare it; he established it, yea, and searched it out;
28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”
And unto man he said, Lo, the fear of the Lord, that is wisdom; and to depart from evil is understanding.

< Job 28 >