< Job 21 >

1 Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé,
ויען איוב ויאמר
2 “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi.
שמעו שמוע מלתי ותהי-זאת תנחומתיכם
3 Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.
שאוני ואנכי אדבר ואחר דברי תלעיג
4 “Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí? Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?
האנכי לאדם שיחי ואם-מדוע לא-תקצר רוחי
5 Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín, kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.
פנו-אלי והשמו ושימו יד על-פה
6 Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí, ìwárìrì sì mú mi lára.
ואם-זכרתי ונבהלתי ואחז בשרי פלצות
7 Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?
מדוע רשעים יחיו עתקו גם-גברו חיל
8 Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.
זרעם נכון לפניהם עמם וצאצאיהם לעיניהם
9 Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.
בתיהם שלום מפחד ולא שבט אלוה עליהם
10 Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun.
שורו עבר ולא יגעל תפלט פרתו ולא תשכל
11 Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.
ישלחו כצאן עויליהם וילדיהם ירקדון
12 Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
ישאו כתף וכנור וישמחו לקול עוגב
13 Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà. (Sheol h7585)
יבלו (יכלו) בטוב ימיהם וברגע שאול יחתו (Sheol h7585)
14 Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.
ויאמרו לאל סור ממנו ודעת דרכיך לא חפצנו
15 Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?
מה-שדי כי-נעבדנו ומה-נועיל כי נפגע-בו
16 Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.
הן לא בידם טובם עצת רשעים רחקה מני
17 “Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?
כמה נר-רשעים ידעך-- ויבא עלימו אידם חבלים יחלק באפו
18 Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.
יהיו כתבן לפני-רוח וכמץ גנבתו סופה
19 Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.
אלוה יצפן-לבניו אונו ישלם אליו וידע
20 Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.
יראו עינו כידו ומחמת שדי ישתה
21 Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?
כי מה-חפצו בביתו אחריו ומספר חדשיו חצצו
22 “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀? Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.
הלאל ילמד-דעת והוא רמים ישפוט
23 Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.
זה--ימות בעצם תמו כלו שלאנן ושליו
24 Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.
עטיניו מלאו חלב ומח עצמותיו ישקה
25 Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun.
וזה--ימות בנפש מרה ולא-אכל בטובה
26 Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.
יחד על-עפר ישכבו ורמה תכסה עליהם
27 “Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.
הן ידעתי מחשבותיכם ומזמות עלי תחמסו
28 Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé, àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’
כי תאמרו איה בית-נדיב ואיה אהל משכנות רשעים
29 Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà? Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn,
הלא שאלתם עוברי דרך ואתתם לא תנכרו
30 pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun. A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.
כי ליום איד יחשך רע ליום עברות יובלו
31 Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?
מי-יגיד על-פניו דרכו והוא-עשה מי ישלם-לו
32 Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.
והוא לקברות יובל ועל-גדיש ישקוד
33 Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn. Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.
מתקו-לו רגבי-נחל ואחריו כל-אדם ימשוך ולפניו אין מספר
34 “Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán, bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”
ואיך תנחמוני הבל ותשובתיכם נשאר-מעל

< Job 21 >